1Ní oṣù kẹ́ta tí àwọn Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì, ni ọjọ́ náà gan an ni wọ́n dé ihà Ṣínáì.
2Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n gbéra kúrò ní Réfídímù, wọ́n wọ ijù Ṣínáì, wọ́n sì tẹ̀dó ṣíbẹ̀ ní iwájú òkè Ṣínáì.
3Mósè sì gòkè tọ Ọlọ́run lọ. OLÚWA sì ké pè é láti orí òkè náà wá pé, “Èyí ni ìwọ yóò sọ fún ilé Jákọ́bù àti ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì:
4‘Ẹ̀yin ti rí ohun tí mo ti ṣe sí àwọn ará Éjíbítì, àti bí mo ti gbé e yín ní apá ìyẹ́ idì.
5
6Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ilẹ ọba àwọn àlùfáà fún mi, orílẹ̀ èdè mímọ́.’ Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ti ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”
7Mósè sì tọ àwọn ènìyàn wá, ó sí pe àwọn àgbààgbà láàárin àwọn ènìyàn jọ. Ó sì gbé gbogbo ọ̀rọ̀ ti OLÚWA pàṣẹ fún un láti sọ ni iwájú wọn.
8Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì pa ohùn wọn pọ̀ wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa yóò se ohun gbogbo ti OLÚWA wí.” Mósè sì mú ìdáhùn wọn padà tọ OLÚWA lọ.
9OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Èmi yóò tọ̀ ọ́ wá nínú ìkùùkuu síṣú dudu, kí àwọn ènìyàn lè gbọ́ ohùn mi nígbà ti mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọn kí ó lè máa gbà ọ́ gbọ́.” Nígbà náà ni Mósè sọ ohun tí àwọn ènìyàn wí fún OLÚWA.
10OLÚWA sì wí fún Mósè pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn.
11Kí wọn kí ó sì múra di ọjọ́ kẹ́ta, nítorí ni ọjọ́ náà ni OLÚWA yóò sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Ṣínáì ni ojú gbogbo àwọn ènìyàn.
12
13Ọwọ́kọ́wọ́ kò gbọdọ̀ kàn án, ẹni tí ó fi ọwọ́ kan òkè náà a ó sọ ọ́ ní òkúta tàbí kí a ta a ní ọfà, ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko: Òun kì yóò wà láàyè.’ Nígbà ti ìpè bá dún nìkan ni kí wọn ó gun òkè wá.”
14Mósè sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn.
15Ó sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ múra sílẹ̀ di ọjọ́ kẹta; Ẹ má ṣe bá aya yín lòpọ̀.”
16
17Mósè sì kó àwọn ènìyàn tí ó jáde láti ibùdó wá pàdé Ọlọ́run, wọ́n dúró nítòsí òkè.
18Èéfín sì bo òkè Sínáì nítorí OLÚWA sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ nínú iná. Èéfín náà sì ń ru sókè bí èéfín iná ìléru, gbogbo òkè náà sì mì tìtì.
19Ohùn ìpè sì ń rinlẹ̀ dòdò. Mósè sọ̀rọ̀, Ọlọ́run sì fi àrá dá a lóhùn.
20OLÚWA sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Ṣínáì, o sì pe Mósè wá sí orí òkè náà. Mósè sì gun orí òkè.
21OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Sọ̀kalẹ̀, kí ó sì kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí wọn má ṣe fi tipátipá wá ọ̀nà láti wo OLÚWA, bí wọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn yóò ṣègbé.
22Kódà àwọn àlùfáà tí ó ń wá ṣíwájú OLÚWA gbọdọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́. OLÚWA yóò kọ lù wọ́n.”
23Mósè wí fún OLÚWA pé, “Àwọn ènìyàn kì yóò lè wá sí orí òkè Ṣínáì, nítorí ìwọ fúnrarẹ ti kìlọ̀ fún wa pé, ‘Ṣe ààlà yí òkè ká, kí o sì yà á sí mímọ́.’ ”
24OLÚWA sì wí fún Mósè pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, mú Árónì gòkè wá pẹ̀lú rẹ. Ṣùgbọ́n kí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn má ṣe fi tipátipá gòkè tọ OLÚWA. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò kọlù wọ́n.”
25Mósè ṣọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ènìyàn lọ. Ó sì sọ ohun tí OLÚWA wí fún wọn.