1Ó sì ṣe, ọkùnrin ará ilé Léfì kan fẹ́ ọmọbìnrin ará Léfì kan ni ìyàwó.
2
3Ṣùgbọ́n nígbà tí kò le è gbé e pamọ́ mọ́, ó fi ewé pápírúsì hun apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọ̀dà ati òjé igi sán apẹ̀rẹ̀ náà. Ó sì tẹ́ ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbe é sí inú esùnsún ni etí odò Náílì.
4Arábìnrin rẹ̀ dúró ni òkèèrè láti wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà.
5
6ó sí i, ó sì rí ọmọ náà. Ọmọ náà ń sunkún, àánú ọmọ náà sì ṣe é. Ó wí pé “Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Hébérù ni èyí.”
7Nígbà náà ni arábìnrin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin Fáráò pé “Ṣé kí èmi lọ wá ọ̀kan lára àwọn obìnrin Hébérù wá fún ọ láti bá ọ tọ́jú ọmọ náà?”
8Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni; lọ.” Arábìnrin náà sì lọ, ó sì pe ìyá ọmọ náà wá,
9Ọmọbìnrin Fáráò sì wí fún un pé, “Gba ọmọ yìí kí o sì tọ́jú rẹ̀ fún mi, èmi yóò san owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ fún ọ” Ọmọbìnrin náà sì gbé ọmọ náà lọ, ó sì tọ́jú rẹ̀.
10Nígbà tí ọmọ náà sì dàgbà, ó mú un tọ ọmọbìnrin Fáráò wá, ó sì di ọmọ rẹ̀. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Mósè, ó wí pé “Nítorí tí mo fà á jáde nínú omi.”
11
12
13Ní ọjọ́ kejì, ó jáde lọ, ó rí àwọn ará Hébérù méjì tí wọ́n ń jà. Ó béèrè lọ́wọ́ èyí tí ó jẹ̀bi pé “Èéṣe tí ìwọ fi ń lu Hébérù arákùnrin rẹ?”
14
15
16Ó sì ṣe, àlùfáà Mídíánì kan ni àwọn ọmọbìnrin méje, wọn sì wá láti pọn omi kún ọpọ́n ìmumi fún ẹran ọ̀sìn baba wọn.
17Àwọn darandaran kán wá, wọ́n sì lé wọn sẹ́yìn, ṣùgbọ́n Mósè dìde láti gbà wọ́n sílẹ̀ àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fún ẹran wọn ní omi.
18Nígbà ti àwọn ọmọbìnrin náà padà dé ọ̀dọ̀ Rúẹ́lì baba wọn, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé “Èéṣe tí ẹ̀yin fi tètè dé ni òní?”
19Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ará Éjíbítì kan ni ó gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn darandaran, ó tilẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti fa omi àti láti fún agbo ẹran ní omi.”
20Ó sọ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, “Níbo ni ó wà? Èéṣe ti ẹ fi fi ọkùnrin náà sílẹ̀? Ẹ pè é wá jẹun.”
21Mósè gbà láti dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ẹni tí o fi Sípórà, ọmọbìnrin rẹ̀ fún Mósè láti fi ṣe aya.
22Ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Gésómù, ó wí pé “Èmi ń ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.”
23Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ọba Éjíbítì kú. Àwọn ará Ísírẹ́lì ń kérora ní oko ẹrú wọn, wọ́n ń ké fún ìrànlọ́wọ́ nítorí oko ẹrú tí wọ́n wà, igbe wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
24
25Nítorí náà, Ọlọ́run bojú wo àwọn ará Ísírẹ́lì, Ó sì wà láti gbà wọ́n sílẹ̀.