1
2Ìwọ yóò sìṣe ìwo orí ìgun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, kí àwọn ìwo náà àti pẹpẹ náà lè ṣe ọ̀kan, ìwọ yóò sì bo pẹpẹ náà pẹ̀lú idẹ.
3Ìwọ yóò sìṣe abọ́ ìtẹ́dí rẹ láti máa gba eérú rẹ̀, àti ọkọ̀ rẹ̀, àwokòtò rẹ̀, àti fọ́ọ̀kì ẹran rẹ̀, àti àwo iná rẹ̀, gbogbo ohun èlò rẹ̀ ni ìwọ yóò fi idẹ ṣe.
4Ìwọ yóò sí ṣe ni wẹ́wẹ́, ìṣẹ́ àwọ̀n idẹ, kí o sì ṣe òrùka idẹ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìṣẹ́ àwọ̀n náà.
5Gbé e sí abẹ́ igun pẹpẹ náà, kí ó lè dé ìdajì pẹpẹ náà.
6Ìwọ yóò sí ṣe òpó igi kaṣíà fún pẹpẹ náà, kí o sì bò ó pẹ̀lú idẹ.
7A ó sì bọ àwọn òpó náà ní òrùka, wọn yóò sì wà ní ìhà méjèèjì pẹpẹ nígbà tí a bá rù ú.
8Ìwọ yóò síṣe pẹpẹ náà ni oníhò nínú. Ìwọ yóò sí ṣe wọ́n bí èyí tí a fi hàn ọ́ ní orí òkè.
9
10pẹ̀lú ogún (20) òpó àti ogún (20) ihò itẹ̀bọ̀ idẹ pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà, kí ó sì di àwọn òpó mú.
11Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mítà mẹ́rìndínláàdọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun (20) òpó àti ogún ihò itẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú.
12“Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́talélógún ní fífẹ̀, kí ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá.
13Ní ìhà ìlà oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́talélógun ní fífẹ̀,
14Aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dógún ní gíga ní yóò wà ní ìhà ẹnu ọ̀nà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta,
15Àti aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dógún ní gíga yóò wá ní ìhà kejì, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta.
16“Àti fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, pèṣè aṣọ títa, mítà mẹ́sàn-án ní gíga, ti aláró, elésèé àlùkò, ti òdòdó, àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe, pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin.
17Gbogbo òpó ti ó wà ní àyíká àgbàlá náà ni a ó fi fàdákà ṣo pọ̀ àti ìkọ́, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ.
18Àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́rìndìnláàdọ́ta (46 mítà) ni gíga àti mítà mẹ́talélógún (23 mítà) ní fífẹ̀, pẹ̀lú aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn mítà méjì ní gíga, àti pẹ̀lú ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ.
19Gbogbo irú iṣẹ́ tí ó wà kí ó ṣe, papọ̀ pẹ̀lú gbogbo èèkàn àgọ́ náà àti fún tí àgbàlá náà, kí ó jẹ́ idẹ.
20
21Ní àgọ́ àjọ, lẹ́yìn òde láìsí aṣọ ìsélé tí ó wá níwájú ẹ̀rí náà, Árónì àti òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, ni yóò tọ́jú rẹ̀ lati alẹ́, títí di òwúrọ̀ níwájú OLÚWA: yóò sì di ìlànà láéláé ni ìrandíran wọn lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Isírẹ́lì.