Ìwé Ékísódù 30:1-38 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ “Ìwọ yóò sì ṣe pẹpẹ igi kaṣíà kan; máa jó tùràrí lórí rẹ̀.

2Kí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé, kí ó jẹ́ ìdajì mítà ní gígùn, ìdajì mítà ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga rẹ̀—kí ìwo rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.

3Ìwọ yóò sì bo òkè rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀ pẹ̀lú u kìkì wúrà, ìwọ yóò sì se wúrà gbà á yíká.

4Ìwọ yóò sì ṣe òrùka wúrà méjì fún pẹpẹ náà níṣàlẹ̀ ìgbátí méjèèjì ní ọ̀kánkán ìhà rẹ̀—láti gbá àwọn òpó rẹ̀ mú, láti lè máa fí gbé e.

5Ìwọ yóò sì ṣe òpó igi kaṣíà, ìwọ yóò sì bọ́ wọ́n pẹ̀lú wúrà.

6Ìwọ yóò gbé pẹpẹ náà sí iwájú aṣọ títa, èyí tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí níwájú ìtẹ́ àánú èyí tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí níbi ti èmi yóò ti máa bá ọ pàdé.

7“Árónì yóò sì máa jó tùràrí dídùn lórí pẹpẹ náà ní àràárọ̀, nígbà tí ó tún àwọn fítìlá náà ṣe.

8Òun yóò sì tún jó tùràrí nígbà tí ó bá tan fìtílà ní àṣálẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní tùràrí yóò máa jó títí láé níwájú OLÚWA fún àwọn ìran tó ni ń bọ̀.

9Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mú Àjèjì tùràrí wá sórí pẹpẹ yìí tàbí ẹbọ sísun kankan tàbí ọrẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ da ẹbọ ohun mímu sórí rẹ̀.

10Árónì yóò sì máa ṣe ètùtù sórí àwọn ìwo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Óun yóò sì máa ṣe ètùtù ọdọọdún yìí pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ètùtù fún ìran tó ń bọ̀. Mímọ́ jùlọ ni sí OLÚWA.”

11ⓑ Nígbà náà ni OLÚWA wí fún Mósè pé,

12“Nígbà tí ìwọ bá ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti mọ iye wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọdọ̀ mú ìràpadà ọkàn rẹ̀ wá fún OLÚWA ní ìgbà tí o bá ka iye wọn. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-àrùn kì yóò sún mọ́ wọn, nígbà tí o bá ń ka iye wọn.

13Olúkúlùkù ẹrù tí ó bá kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn tí a ti kà yóò san ìdajì sékéli (gíráámù mẹ́fà), gẹ́gẹ́ bí sékélì ibi mímọ́, èyí tí ó wọn ogún gérà. Ìdajì sékélì yìí ní ọrẹ fún OLÚWA.

14Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá sínú àwọn tí a kà láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni yóò fi ọrẹ fún OLÚWA.

15Àwọn olówó kì yóò san ju ìdajì sékélì lọ, àwọn talákà kò sì gbọdọ̀ dín ní ìdajì sékélì nígbà tí ẹ̀yin bá mú ọrẹ wá fún OLÚWA láti se ètùtù fún ọkàn yín.

16Ìwọ yóò sì gba owó ètùtù náà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìwọ yóò sì fi lé lẹ̀ fún ìsìn àgọ́ àjọ. Yóò jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níwájú OLÚWA, láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.”

17Nígbà náà ni OLÚWA wí fún Mósè pé,

18ⓒ “Ìwọ yóò si ṣe agbada idẹ kan, àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ idẹ, fún wíwẹ̀. Ìwọ yóò sì gbé e sí àárin àgọ́ àjọ àti pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì pọn omi sínú rẹ̀.

19Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wẹ ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ wọn pẹ̀lú omi tí ó wà nínú rẹ̀.

20Nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ, wọ́n yóò wẹ̀ pẹ̀lú omi nítorí kí wọ́n má ba à kú. Bákan náà, nígbà tí wọ́n bá sún mọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe ìṣìn, láti mú ẹbọ ti a fi iná sun wá fún OLÚWA,

21wọn yóò sì wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn, nítorí kí wọn máa ba à kú. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún Árónì àti irú àwọn ọmọ rẹ̀ fún ìrandìran wọn.”

22ⓓ  OLÚWA sọ fún Mósè pé,

23Ìwọ yóò mú ààyò tùràrí olóòórùn sí ọ̀dọ̀ rẹ; ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta sékélì (kílógíráámù mẹ́fà) tí òjíá sísàn, ìdajì bí ó bá yẹ àádọ́tàlérúgba (250) sékélì tí kínámónì dídùn, àti kane dídùn àádọ́tàlérúgba (250) sékélì,

24kaṣia ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) sékélì-gbogbo rẹ̀ ní ìlànà sékélì ibi mímọ́ àti hínì òrórò ólífì kan (lítà mẹ́rin).

25Ṣe ìwọ̀nyí ní òróró mímọ́ ìkunra, tí a pò pọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣe-òórùn dídùn tì í ṣe, Yóò jẹ òróró mímọ́ ìtasórí.

26Ìwọ yóò sì lò ó láti ya àgọ́ sí mímọ́ àti àpótí ẹ̀rí náà,

27tábìlì àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà àti ohun èlò rẹ̀, àti pẹpẹ tùràrí,

28pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti agbada pẹ̀lú ẹṣẹ̀ rẹ̀.

29Ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohunkóhun tí ó bá fí ọwọ́ kàn wọn yóò di mímọ́.

30“Ìwọ yóò sì ta òróró sí orí Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè sìn mí bí àlùfáà.

31Ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Èyí ni yóò ṣe òróró mímọ́ ìtasórí mi fún ìrandíran tó ń bọ̀.

32Má se dà á sí ara ènìyàn kí o má sì ṣe ṣe òróró kankan ni irú rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ̀yín sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́.

33Ẹnikẹ́ni tí ó bá po irú rẹ̀, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá fi sára ẹnìkankan yàtọ̀ sí àlùfáà, a ó gé e kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ”

34OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Mú tùràrí olóòórùn dídùn sọ́dọ̀ rẹ, óníkà, àti gálíbánúmù àti kìkì tùràrí dáradára, iye kan ni gbogbo rẹ,

35ṣe tùràrí olóòórùn dídùn tí a pò, iṣẹ́ àwọn olóòórùn, tí ó ní iyọ̀, ó dára, ó sì jẹ́ mímọ́.

36Ìwọ yóò sì lọ díẹ̀ nínú rẹ̀ kúnná, ìwọ yóò sì gbé e ṣíwájú ẹ̀rí ní àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti pàdé yín. Yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ fún yín.

37Ẹ má ṣe se tùràrí kankan ní irú èyí fún'ra yín; ẹ kà á ní mímọ́ sí OLÚWA.

38Ẹnikẹ́ni tí ó bá se irú rẹ̀ láti máa gbádùn òórùn rẹ̀, òun ni a ó gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>