1OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Fi ìhín yìí sílẹ̀, ìwọ àti àwọn ènìyàn tí o mú gòkè láti Éjíbítì wá, kí ẹ sì gòkè lọ sí ilẹ̀ tí èmi ti pinnu ní ìbúra fún Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú ọmọ rẹ.’
2Èmi yóò rán ańgẹ́lì ṣáájú yín, èmi yóò sì lé àwọn Kénánì, àwọn ará Ámórì, àwọn ará Hítì, àwọn ará Pérísì, àwọn ará Hífì àti àwọn ará Jébúsì jáde.
3
4Nígbà tí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ọ̀rọ̀ ìparun wọ̀nyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì ní kùn, ẹnìkankan kò sì le è wọ ohun ọ̀sọ́ rẹ̀.
5Nítorí OLÚWA ti wí fún Mósè pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ènìyàn ọlọ́rùn líle ní ẹ̀yin, bí èmi bá lè wa sí àárin yín ni ìsẹ́jú kan, èmi lè pa yín run. Ní sinsin yìí, bọ́ ohun ọ̀sọ́ rẹ kúrò, èmi yóò sì gbèrò ohun tí èmi yóò se pẹ̀lú rẹ.’ ”
6Bẹ́ẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò lára wọn ní òkè Hórébù.
7Mósè máa ń gbé àgọ́ náà, ó sì pa á sí ìta ibùdó, ó jìnnà díẹ̀ sí ibùdó, ó pè é ni “Àgọ́ àjọ.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bèrè OLÚWA yóò lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà ní ìta ibùdó.
8Nígbàkúgbà tí Mósè bá jáde lọ sí ibi àgọ́, gbogbo ènìyàn á dìde, wọ́n á sì dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn, wọn yóò máa wo Mósè títí yóò fi wọ inú àgọ́ náà.
9Bí Mósè ṣe wọ inú àgọ́ náà, ọ̀wọ̀n àwọ̀ọsánmọ̀ yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì dúró sí ẹnu ọnà, nígbà tí OLÚWA ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Mósè.
10Nígbàkígbà tí àwọn ènìyàn bá rí i ti ọ̀wọ́n àwọ̀ọsánmọ̀ bá dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, gbogbo wọn yóò dìde wọn yóò sì sìn, olúkúlùkù ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀.
11
12Mósè sọ fún OLÚWA pé, “Ìwọ ti ń sọ fún mi, ‘Darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,’ ṣùgbọ́n ìwọ kò jẹ́ kí ń mọ ẹni tí ìwọ yóò rán pẹ̀lú mi. Ìwọ ti wí pé, ‘Èmi mọ̀ ọ́ nípa orúkọ, ìwọ sì ti rí ojú rere mi pẹ̀lú.’
13Bí ìwọ bá ní inú dídùn pẹ̀lú mi, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́, kí n sì le máa wá ojú rere rẹ pẹ̀lú. Rántí wí pé orílẹ̀ èdè yìí ènìyàn rẹ ni.”
14OLÚWA dáhùn wí pé, “Ojú mi yóò máa bá ọ lọ, èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi.”
15Nígbà náà ni, Mósè wí fún-un pé, “Bí ojú rẹ kò bá bá wa lọ, má se rán wa gòkè láti ìhín lọ.
16Báwo ni ẹnìkẹ́ni yóò se mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé?”
17OLÚWA sì sọ fún Mósè pé, “Èmi yóò ṣe ohun gbogbo tí ìwọ ti bèrè, nítorí inú mi dún sí o, èmi sì mọ̀ ọ́ nípa orúkọ rẹ̀.”
18Mósè sì wí pé “Nísinsin yìí fi ògo rẹ hàn mí.”
19
20Ṣùgbọ́n,” ó wí pé, “Ìwọ kò le è rí ojú mi, nítorí kò sí ẹnìkan tó rí mi, tí ó lè yè.”
21OLÚWA sì wí pé, “Ibì kan wà lẹ́gbẹ̀ ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, níbi tí o ti lè dúró lórí àpáta.
22Nígbà tí ògo mi bá kọjá, èmi yóò gbé ọ sínú pàlàpálá àpáta, èmi yóò sì bò ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ mi títí èmi yóò fi rékọjá.
23Nígbà tí èmi yóò mú ọwọ́ mi kúrò, ìwọ yóò sì rí ẹ̀yìn mi; ṣùgbọ́n ojú mi ni o kò ní rí.”