1Mósè pe gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ohun ti OLÚWA ti pa láṣẹ fún-un yín láti ṣe:
2
3Ẹ má se dáná kankan ní ibùgbé yín ní ọjọ́ ìsinmi.”
4
5Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún OLÚWA. Ẹnikẹ́ni tí ọ́ bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún OLÚWA ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ;
6aṣọ aláró, elésèé àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára; àti irun ewúrẹ́;
7awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù; odò igi kaṣíá;
8òróró ólífì fún títan iná; olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn;
9Òkúta óníkìsì àti òkúta tí a tò sí ẹ̀wù èfòdì àti igbáàyà.
10“Gbogbo ẹni tí ó ní ọgbọ́n láàrin yín, kí ó wa, kí ó sì wá se gbogbo ohun tí OLÚWA ti pa láṣẹ:
11Àgọ́ náà pẹ̀lú àgọ́ rẹ àti ìbòrí rẹ̀, kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ọ̀wọ́n rẹ̀ àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;
12Àpótí náà pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀, ibò àánú àti aṣọ títa náà tí ó síji bòó;
13Tábìlì náà pẹ̀lú òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn náà;
14Ọ̀pá fìtílà tí ó wà fún títanná pẹ̀lú ohun èlò rẹ̀, fìtílà àti òróró fún títanná;
15Pẹpẹ tùràrí náà pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, òróró ìtasórí àti tùràrí dídùn; aṣọ títa fún ọ̀nà ìlẹ̀kùn ní ẹnu ọ̀nà sí Àgọ́ náà;
16Pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú ojú àrò idẹ rẹ̀, òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀; agbada idẹ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀;
17aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú, ọ̀wọ́n àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ àti aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà;
18Èèkàn àgọ́ náà fún Àgọ́ náà àti fún àgbàlá àti okùn wọn;
19aṣọ híhun láti sisẹ ní ibi mímọ́ aṣọ mímọ́ fún Árónì àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n sìn bí àlùfáà.”
20Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì kúrò níwájú Mósè,
21Olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ àti ẹni tí ọkàn rẹ̀ gbé sókè wá, wọ́n sì mú ọrẹ fún OLÚWA, fún isẹ́ Àgọ́ àjọ, fún gbogbo ìsìn rẹ̀ àti fún asọ mímọ́ náà.
22Gbogbo àwọn tí ó fẹ́, ọkùnrin àti obìnrin, wọ́n wá wọ́n sì mú onírúurú ìlẹ̀kẹ wúrà: òrùka etí, òrùka àti ọ̀sọ́. Gbogbo wọn mú wúrà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ wá fún OLÚWA.
23Olúkúlùkù ẹni tí ó ni aṣọ aláró elésèé àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára, tàbí irun ewúrẹ́, awọ àgbò tí a rì ní pupa tàbí awọ màlúù odò, kí ó mú wọn wá.
24Àwọn tí ó mú ọrẹ fàdákà tàbí idẹ wá, mú ọrẹ wá fún OLÚWA, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní igi kasíà fún ipa kankan nínú iṣẹ mú un wá.
25Gbogbo àwọn obìnrin tí ó ní ọgbọ́n ríran owú pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀, kí ó mú èyí ti ó ti ran wá ti aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó tàbí ti ọ̀gbọ̀ dáradára.
26Gbogbo àwọn obìnrin tí ó fẹ́, tí ó sì ní ọgbọ́n ń ran òwú irun ewúrẹ́
27Àwọn olórí mú òkúta óníkísì wá láti tò ó lórí ẹ̀wù éfódì àti igbáàyà.
28Wọ́n sì tún mú olóòrùn àti òróró ólífì wá fún títanná àti fún òróró ìtasórí àti fún tùràrí dídùn.
29Gbogbo àwọn ènìyàn Isirẹli ọkùnrin àti obìnrin ẹni tí ó fẹ́ mú ọrẹ àtinúwá fún OLÚWA fún gbogbo iṣẹ́ tí OLÚWA ti pa láṣẹ fún wọn láti se nípaṣẹ̀ Mósè.
30
31Ó sì ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún-un, pẹ̀lú ọgbọ́n, agbára, ìmọ̀ àti gbogbo onírúurú isẹ́ ọnà
32Láti má a se aláràbarà iṣẹ́ ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ,
33láti gbẹ́ òkúta àti láti tò ó, láti fún igi àti láti sísẹ ni gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà.
34Ó sì fún òun àti Óhólíábù ọmọ Áhísámákì ti ẹ̀yà Dánì, ni agbára láti kọ́ àwọn tókù.
35Ó sì fi ọgbọ́n kún wọn láti se gbogbo onírúurú iṣẹ́, ti oníṣọ̀nà, ti ayàwòrán, ti aránsọ, ti alásọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ní ọ̀gbọ̀ dáradára àti ti ahunsọ, gbogbo èyí tí ọ̀gá onísẹ́ ọnà àti ayàwòrán ń ṣe.