Ìwé Ékísódù 37:1-29 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Bésálélì se àpótí igi kasíá ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni gíga rẹ̀.

2Ó fi kìkì wúrà bò ó nínú àti lóde, ó sì fi wúrà gbà á léti yíká.

3Ó sì dá òrùka wúrà mẹ́rin fún un, ó so wọ́n mọ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, pẹ̀lú òrùka méjì ní ìhà kìn-ín-ní àti òrùka méjì ni ìhà kejì.

4Ó sì tún ṣe òpó igi kaṣíà, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú wúrà.

5Ó sì kó àwọn òpó náà sínú òrùka ní ìhà àpótí náà láti máa fi gbé e.

6Ó se ìbòrí àánú kìkì wúrà ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀.

7Ó sì se kérúbù méjì láti inú òlù wúrà ní òpin ìbòrí náà.

8Ó se kérúbù kan ni òpin èkínní, ó sì tún ṣe kérúbù kejì sí èkejì; ní òpin méjèèjì ó ṣe ìtẹ́ àánú ìbòrí wọn.

9Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè sí i, ó fi ìji bo ìbòrí wọn. Àwọn kérúbù kọjú sí ara wọn, wọ́n ń wo ìbòrí náà.

10ⓑ Ó se tábìlì igi kaṣíá ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní gíga.

11Ó sì fi kìkì wúrà bòó, ó sì se ìgbátí yí i ká.

12Ó sì tún ṣe etí ìbù ọwọ́ fífẹ̀ yìí ká, ó sì fi ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká.

13Ó sì dá òrùka wúrà fún tábìlì náà, ó sì so wọ́n mọ́ igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, níbi tí ẹṣẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wà.

14Àwọn òrùka náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ etí rẹ̀ láti gbá àwọn òpó náà mu láti máa fi gbé tábìlì náà.

15Igi kaṣíá ni ó fi se òpó ti a fi ń gbé tábìlì náà, ó sì fi wúrà bò ó.

16Ó sì ṣe àwọn ohun èlò tí ó wà lórí tábìlì náà ní kìkì wúrà, abọ́ rẹ̀, àwo rẹ, àwokòtò rẹ̀ àti ìgò rẹ̀ fún dída ọrẹ mímu jáde.

17ⓒ Ó sì se ọ̀pá fìtílà náà ní kìkì wúrà ó sì lù ú jáde, ọ̀pá rẹ̀, ìtànná ìfẹ́ rẹ̀, irudi rẹ àti ago rẹ̀, wọ́n jẹ́ òkan náà.

18Ẹ̀ka mẹ́fà ní ó jáde láti ìhà ọ̀pá fìtílà náà mẹ́ta ní ìhà àkọ́kọ́ àti mẹ́ta ní ìhà èkejì.

19Kọ́ọ̀bù mẹ́ta ni a se bí ìtànná alímóndì pẹ̀lú ìrùdí àti ìtànná wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta sì tún wà ní ẹ̀ka mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni ní ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà jáde lára ọ̀pá fìtílà.

20Lára ọ̀pá fìtílà náà ni a se kọ́ọ̀bù mẹ́rin bí ìtànná alímóndì, ìrùdí rẹ̀ àti ìtànná rẹ̀:

21Ìrùdí kan níṣàlẹ̀ ẹ̀ka méjì jáde lará ọ̀pá fìtílà náà, ìrùdí kejì níṣàlẹ̀ èkejì, àti ìrùdí kẹ́ta níṣàlẹ̀ ìrùdí ìkẹta-ẹ̀ka mẹ́fà lò wà lára gbogbo rẹ̀.

22Ìrùdí náà àti ẹ̀ka wọn jẹ́ bákan náà, ó lù ú jáde ní kìkì wúrà.

23Ó se fìtílà méje rẹ̀, pẹ̀lú àlùmágàjí àti àwo rẹ̀ kìkì wúrà ni.

24Ó sì se ọ̀pá fìtílà náà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ láti ara talẹ́ńtì kan tí ó jẹ́ kìkì wúrà.

25ⓓ Igi kaṣíá ní ó fi ṣe pẹpẹ tùràrí náà. Igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ jẹ́ déédé, gígùn rẹ̀ jẹ ìdajì mítà, fífẹ̀ rẹ̀ náà jẹ́ ìdajì mítà àti gíga rẹ̀ sì jẹ́ mítà kan-ìwo rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà.

26Kìkì wúrà ni ó fi bo orí rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀, ó sì fi ìgbátí wúrà yìí ká.

27Ó se òrùka wúrà méjì sí ìṣàlẹ̀ ìgbátí náà méjì ní ọ̀kánkán ara wọn láti gbá òpó náà mú láti máa fi gbé e.

28Ó ṣe òpó igi kaṣíá, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú u wúrà.

29Ó sì tún ṣe òróró mímọ́ ìtasórí àti kìkì òórùn dídùn tùràrí-iṣẹ́ àwọn tí ń ṣe nǹkan olóòórùn.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>