Ìwé Ékísódù 40:1-38 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA sì wí fún Mósè pé:

2Ní ọjọ́ kìn-ín-ní. Oṣù kìn-ín-ní ni kí ó gbé Àgọ́ náà, àgọ́ àjọ náà ró.

3Gbé àpótí ẹ̀rí sí inú rẹ̀, kí ó sì bo àpótí náà pẹ̀lú aṣọ títa.

4Gbé tábìlì náà wọ ilé, kí o sì tò àwọn ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ lé e lórí. Nígbà náà gbé ọ̀pá fìtílà wọlé, kí o sì to àwọn fìtílà rẹ̀.

5Gbé pẹpẹ wúrà ti tùràrí sí iwájú àpótí ẹ̀rí, kí o sì fi aṣọ títa ẹnu ọ̀nà sí ara àgọ́ náà.

6“Gbé pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun sí iwájú ẹnu ọ̀nà Àgọ́ náà, Àgọ́ àjọ;

7gbé agbada sí àárin àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, kí o sì fi omi sí inú rẹ̀.

8Gbé àgbàlá ró yìí ka, kí ó sì fi aṣọ títa sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà.

9“Mú òróró ìtasórí, kí ó sì ta á sára Àgọ́ náà àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀: yà pẹpẹ sí mímọ́ àti gbogbo ọ̀sọ́ rẹ̀, yóò sì jẹ́ mímọ́.

10Ta òróró sára pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ya pẹpẹ náà sí mímọ́, yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ.

11Ta òróró sára agbada náà àti ẹsẹ̀ rẹ, kí o sì yà wọ́n sí mímọ́.

12“Mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì wẹ̀ wọ́n pẹ̀lú omi.

13Nígbà náà wọ Árónì ní aṣọ mímọ́, ta òróró sí i ní orí, kí o sì yà á sí mímọ́, nítorí kí ó lè máa sìn mi bí àlùfáà.

14Mú àwọn ọmọ rẹ̀ kí o sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n.

15Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ńi orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.”

16Mósè ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún-un.

17Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé Àgọ́ náà ró ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ìn-ní ní ọdún kejì.

18Nígbà tí Mósè gbé Àgọ́ náà ró ó fi ihò ìtẹ̀bọ̀ sí ààyè rẹ̀, ó to pákó rẹ̀, ó fi ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, ó sì gbé àwọn òpó rẹ̀ ró.

19Ó na aṣọ àgọ́ náà sórí Àgọ́, ó sì fi ìbòrí bo orí Àgọ́ náà, bí OLÚWA ṣe pàṣẹ fún un.

20Ó mu ẹ̀rí, ó sì fi sínú àpótí, ó so àwọn òpó mọ́ àpótí náà, ó sì fi àánú bo orí rẹ.

21Ó sì gbé àpótí náà wá sínú àgọ́; ó sì sọ aṣọ títa, ó sì ta á bo àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún-un.

22Mósè gbé tábìlì sínú àgọ́ àjọ sí ìhà àríwá àgọ́ náà lẹ́yìn aṣọ títa,

23ⓐ ó sì to àkàrà sórí rẹ̀ níwájú OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún-un.

24Ó gbé ọ̀pá fìtílà sínú àgọ́ àjọ ní òkánkán tábìlì ní ìhà gúsù Àgọ́ náà.

25Ó sì tan àwọn fítìlà náà níwájú OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún-un.

26Mósè gbé pẹpẹ wúrà sínú Àgọ́ àjọ níwájú aṣọ títa

27ó sì jó tùràrí dídùn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún-un.

28Ó sì ta aṣọ títa sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ náà.

29Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́, àgọ́ àjọ, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ́ (ọkà), gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún-un.

30ⓑ Ó gbé agbada sí àárin àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, ó sì pọn omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀,

31Mósè, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lò ó láti fi wẹ ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ wọn.

32Wọ́n máa ń wẹ̀ nígbàkugbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ tàbí tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè.

33Mósè sì gbé àgbàlá tí ó yí Àgọ́ náà kà ró àti pẹpẹ, ó sì ta aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà sí àgbàlá náà. Bẹ́ẹ̀ Mósè ṣe parí iṣẹ náà

34ⓒ Nígbà náà ni àwọ̀ọsánmọ̀ bo àgọ́ àjọ, ògo OLÚWA bo Àgọ́ náà.

35Mósè kò sì lè wọ inú Àgọ́ àjọ, nítorí àwọ́ọ́sánmọ̀ wà lórí rẹ, ògo OLÚWA sì ti kún inú Àgọ́ náà.

36Ní gbogbo ìrìnàjò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbàkugbà tí a ba ti fa ikuuku àwọ̀ọsánmọ̀ náà sókè kúrò lórí Àgọ́, wọ́n máa ń jáde lọ;

37ṣùgbọ́n tí àwọ̀ọsánmọ̀ kò bá gòkè wọn kò ní jáde títí di ọjọ́ tí ó bá gòkè.

38Nítorí náà àwọ̀ọsánmọ̀ OLÚWA wà lórí Àgọ́ ní ọ̀sán, iná sì wà nínú àwọ̀ọsánmọ̀ ní òru, ní ojú gbogbo ilé Ísírẹ́lì ní gbogbo ìrìnàjò wọn.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
div>