Ìwé Ékísódù 5:1-23 BYB2014 - Bible AI

1Lẹ́yìn náà ni Mósè àti Árónì tọ Fáráò lọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ: ‘Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè ṣe àjọ mi ní ijù.’ ”

2Fáráò dáhùn wí pé, “Ta ni OLÚWA, tí èmi yóò fi gbọ́ràn sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Ísírẹ́lì ó lọ? Èmi kò mọ OLÚWA, èmi kò sì ní jẹ́ kí Ísírẹ́lì ó lọ.”

3Lẹ́yìn náà ni wọ́n wí pé, “Ọlọ́run àwọn Hébérù tí pàdé wa. Ní ìsinsìnyìí, jẹ́ kí a lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ihà láti rú ẹbọ sí OLÚWA Ọlọ́run wa, kí ó má ba á fi àjàkálẹ̀-àrùn tàbí idà bá wa jà.”

4Ṣùgbọ́n ọba Éjíbítì sọ wí pé, “Mósè àti Árónì, èése ti ẹ̀yin fi mú àwọn ènìyàn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́ yín.”

5Nígbà náà ni Fáráò sọ pé, “Ẹ wò ó àwọn ènìyàn náà ti pọ̀ sí ì nílẹ̀ yìí ní ìsinsìnyìí, ẹ̀yin sì ń dá wọn dúró láti máa bá iṣẹ́ lọ.”

6Ní ọjọ́ yìí kan náà ni Fáráò pàṣẹ fún àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn ti ń ṣe alábojútó iṣẹ́ lórí àwọn ènìyàn.

7“Ẹ̀yin kò ní láti pèsè koríko gbígbẹ fún bíríkì síṣun mọ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí; ẹ jẹ́ kí wọn máa wá koríko gbígbẹ fún ara wọn.

8Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn ó ṣe iye bíríkì kan náà bí ì ti àtẹ̀yìnwá, kí ẹ má ṣe dín iye rẹ̀ kú. Ọ̀lẹ ni wọ́n, ìwà ọ̀lẹ yìí náà ló mú wọn pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rúbọ sí Ọlọ́run wa.’

9Ẹ mú iṣẹ́ náà le fún wọn, kí wọn bá a le è tẹramọ́ iṣẹ́ wọn, ẹ má fi ààyè gba irọ́ wọn.”

10Ní ìgbà náà ni àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ jáde tọ̀ wọ́n lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Èyí ni ohun tí Fáráò sọ, ‘Èmi kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ mọ́.

11Ẹ lọ wá koríko gbígbẹ ni ibi tí ẹ bá ti lè rí i, ṣùgbọ́n iṣẹ́ yín kí yóò dínkù.’ ”

12Gbogbo wọn sí fọ́n káàkiri ni ilẹ̀ Éjíbítì láti sa ìdì koríko tí wọn yóò lò bí ì koríko gbígbẹ fún sísun bíríkì.

13Àwọn akóniṣiṣẹ́ sì ń ni wọ́n lára, wọ́n wí pé, “Ẹ parí iṣẹ́ tí ẹ ni láti se fún ọjọ́ kan bí ìgbà ti a ń fún un yin ní koríko gbígbẹ.”

14Àwọn alábojútó iṣẹ́ tí àwọn akóniṣiṣẹ́ yàn lára ọmọ Ísírẹ́lì ni wọn ń lù, tí wọn sì ń béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò ṣe iye bíríkì ti ẹ̀yin ń ṣe ní àná ní òní bí i tí àtẹ̀yìnwá?”

15Nígbà náà ni àwọn alábojútó iṣẹ́ tí a yàn lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tọ Fáráò lọ láti lọ bẹ̀bẹ̀ pé, “Èéṣe tí ìwọ ti fi ọwọ́ líle mú àwa ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ báyìí?

16Wọn kò fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni koríko gbígbẹ, ṣíbẹ̀ wọn sọ fún wa pé, ‘Ẹ ṣe bíríkì!’ Wọ́n na àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀bi náà wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”

17Fáráò sí dáhùn wí pé, “Ọ̀lẹ niyín, ọ̀lẹ! Èyí ni ó mú kí ẹ̀yin máa sọ ni ìgbà gbogbo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rúbọ sí OLÚWA.’

18Nísínsìnyìí ẹ padà lọ sí ẹnu iṣẹ́ yín, a kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ, ṣíbẹ̀ ẹ gbọdọ̀ ṣe iye bíríkì tí ó yẹ kí ẹ ṣe.”

19Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ mọ̀ dájú wí pé àwọn ti wà nínú wàhálà ńlá ní ìgbà tí a sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ní láti dín iye bíríkì tí ẹ ń ṣe ni ojoojúmọ́ kù.”

20Ní ìgbà tí wọ́n kúró ni ọ̀dọ̀ Fáráò wọ́n rí Mósè àti Árónì tí ó dúró láti pàdé wọn.

21Wọn sì wí pé, “Kí OLÚWA kí ó wò yín, kí ó sì ṣe ìdájọ́! Ẹ̀yin ti mú wa dàbí òórùn búburú fún Fáráò àti àwọn òsìṣẹ̀ rẹ̀, ẹ sì ti fún wọn ni ìdà láti fi pa wá.”

22Mósè padà tọ OLÚWA lọ, ó sì wí pé, “OLÚWA, èéṣe tí ìwọ fi mú ìyọnu wá sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Ṣe torí èyí ni ìwọ fi rán mi?

23Láti ìgbà ti mo ti tọ Fáráò lọ láti bá a sọ̀rọ̀ ni orúkọ rẹ ni ó ti mú ìyọnu wá sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì gba àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀ rárá.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>