1
2
3Mo fi ara hàn Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù bí Ọlọ́run alágbára (Ẹ́lísàdáì) ṣùgbọ́n nípa orúkọ mi OLÚWA, Èmi kò fi ara mi hàn wọ́n.
4Èmí sì tún fi idi májẹ̀mu mi múlẹ̀ pẹ̀lú wọn láti fún wọn ní ilẹ̀ Kénánì, ilẹ̀ tí wọn gbé gẹ́gẹ́ bí àjòjì.
5Èmi sì ti tún gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àwọn tí àwọn ará Éjíbítì mú gẹ́gẹ́ bí ẹrú, àti pé èmi sì ti rántí májẹ̀mu mi.
6“Sọ fún àwọn ará ilé Ísírẹ́lì: ‘Èmi ni OLÚWA, Èmi yóò sọ yín di òmìnira kúró nínú àjàgà àwọn ará Éjíbítì. Èmi yóò sì gbà yín sílẹ̀ kúró ní oko ẹrú wọn. Èmi yóò dá a yín sílẹ̀ pẹ̀lú apá nínà (àwọn iṣẹ́ ìyanu) àti pẹ̀lú ìdájọ́ ńlá.
7Èmi yóò mú un yín bí ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ̀ Ọlọ́run yín. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde kúró nínú àjàgà àwọn ará Íjíbítí.
8Èmi yóò mú un yín wá ilẹ̀ náà ti èmi ti búra pẹ̀lú ìgbọ́wọ́sókè láti fi fún Ábúráhámù. Ísáákì àti Jákọ́bù. Èmi yóò fi fún un yín bí ohun ìní, èmi ni OLÚWA.’ ”
9Mósè sì sọ èyí fún àwọn ará Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n wọn kò fi etí sílẹ̀ sí Mósè nítorí ọkàn wọn tó rẹ̀wẹ̀sì àti nítorí ìgbékùn búburú bí ohun tí ó ti kọ́ sọ kó wọn sí ní oko ẹrú wọn.
10Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Mósè.
11“Lọ, sọ fún Fáráò ọba Éjíbítì pé kí ó jẹ́ kí àwọn ará Ísírẹ́lì lọ kúró ní orílẹ̀ èdè rẹ̀.”
12Ṣùgbọ́n Mósè sọ fún OLÚWA pé, “Nígbà ti àwọn ará Ísírẹ́lì tó jẹ́ ènìyàn mi kó fetí sí ọ̀rọ̀ mi, báwo ni Fáráò yóò se fetí sí ọ̀rọ̀ mi, nígbà ti mo jẹ́ akólòlò?”
13OLÚWA bá ìran Mósè àti Árònì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Ísírẹ́lì àti Fáráò ọba Íjibítì, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn kó àwọn Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.
14Wọ̀nyí ni olórí ìran wọn:
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26Árónì àti Mósè yìí kan náà ni OLÚWA sọ fún pé, “Ẹ kó àwọn ará Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí.”
27Àwọn ni ó bá Fáráò ọba Éjíbítì sọ̀rọ̀ nípa kíkó àwọn ará Ísírẹ́lì jáde kúrò ni Éjíbítì, àní Mósè àti Árónì yìí kan náà ni.
28Nígbà tí OLÚWA bá Mósè sọ̀rọ̀ ni Éjíbítì,
29Ó ni “Èmi ni OLÚWA. Sọ ohun gbogbo ti mo ti sọ fún ọ fún Fáráò ọba Éjíbítì.”
30Ṣùgbọ́n Mósè sì wí ní iwájú OLÚWA pé, “Níwọ̀n ìgbà ti mo jẹ́ akólòlò, ọ̀nà dà ti Fáráò yóò ṣe fi etí sí mi?”