Ìwé Ékísódù 9:1-35 BYB2014 - Bible AI

1Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Lọ sọ fún Fáráò, ‘Èyí ni OLÚWA Ọlọ́run àwọn Hébérù sọ: “Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn mí.”

2Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn ó lọ, tí ó sì dá wọn dúró.

3Ọwọ́ OLÚWA yóò mú àrùn búburú wá sí ara ẹran ọ̀sìn nínú oko, sí ara ẹsin, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, rànkunmí, màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́ yín.

4Ṣùgbọ́n OLÚWA yóò pààlà sí àárin ẹran ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti Ísírẹ́lì àti ti àwọn ara Éjíbítì tí yóò fi jẹ́ pé kò sí ẹran ọ̀sìn ti ó jẹ́ ti ará Ísírẹ́lì tí yóò kú.’ ”

5OLÚWA sì dá àkókò kan wí pé, “Ní ọ̀la ni OLÚWA yóò ṣe èyí ni ilẹ̀ yìí.”

6OLÚWA sí ṣe é ni ọjọ́ kejì. Gbogbo ẹran-ọ̀sìn ará Éjíbítì kú, ṣùgbọ́n ẹyọkan kò kú lára ẹran-ọ̀sìn àwọn Ísírẹ́lì.

7Fáráò rán àwọn ènìyàn rẹ̀ láti lọ ṣe ìwádìí, wọ́n sì rí pé ẹyọkan kò kú lára àwọn ẹran ọ̀sìn ará Ísírẹ́lì. Ṣíbẹ̀ náà, Fáráò kò yí ọkàn rẹ̀ padà àti pé kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ.

8Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Mósè àti Árónì, “Ẹ bu ẹ̀kúnwọ́ eérú gbígbóná láti inú ààrò, kí Mósè kù ú sí inú afẹ́fẹ́ ni iwájú Fáráò.

9Yóò sì di eruku lẹ́búlẹ́bú ni gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, yóò sì di oówo ti ń tú pẹ̀lú ìléròrò sí ara àwọn ènìyàn àti ẹran jákè jádò gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.”

10ⓐ Nígbà náà ni wọ́n bú eérú gbígbóná láti inú ààrò, wọ́n dúró ní iwájú Fáráò. Mósè sì ku eérú náà sínú afẹ́fẹ́, ó sì di oówo tí ń tú pẹ̀lú ìléròrò ni ara àwọn ènìyàn àti lára ẹran.

11Àwọn onídán kò le è dúró níwájú Mósè nítorí oówò ti ó wà lára wọn àti ni ara gbogbo àwọn ara Éjíbítì.

12Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sé ọkàn Fáráò le, kò sì gbọ́ ti Mósè àti Árónì, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti sọ fún Mósè.

13Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Dìde ni òwúrọ̀ kùtùkùtù, kí o sì tọ Fáráò lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run àwọn Hébérù wí: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sin mí,

14Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò rán ìdààmú ti ó ní agbára gidigidi sí ọ, sí àwọn ìjòyè rẹ àti sí àwọn ènìyàn rẹ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, kò sí ẹni bí èmi ni gbogbo ayé.

15Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọ lù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ohun búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀.

16ⓑ Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe dá ọ sí, kí èmi kí ó lè fi agbára mi hàn ọ́, kí a bá à lè gbọ́ òkìkí orúkọ mi ní gbogbo ayé.

17Ṣíbẹ̀ ìwọ tún gbógun ti àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì jẹ́ kí wọn lọ.

18Nítorí náà, ni ìwòyí ọ̀la, èmi yóò rán òjò o yìnyín tí irú rẹ̀ kò tí i rọ̀ rí ni Éjíbítì láti ìpìlẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ títí di àkókò yìí.

19Pàṣẹ nísin yìí láti kó ẹran-ọ̀sìn yin àti ohun gbogbo ti ẹ ni ní pápá wá sí abẹ́ ààbò, nítorí òjò yìnyín yóò rọ̀ sí orí àwọn ènìyàn àti ẹran ti a kò kó wá sí abẹ́ ààbò tí wọ́n sì wà ni orí pápá, wọn yóò sì kú.’ ”

20Àwọn ti ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ OLÚWA lára àwọn ìjòyè Fáráò yára lọ láti kó àwọn ẹrú àti àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn wá sí abẹ́ ààbò.

21Ṣùgbọ́n àwọn ti kò kà ọ̀rọ̀ OLÚWA sí fi àwọn ẹrú wọn àti àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn sílẹ̀ ni pápá.

22OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ọ̀run kí yìnyín bá à lè rọ̀ sí orí gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, sí orí ènìyàn àti ẹranko, àti sí orí gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko.”

23Nígbà tí Mósè gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, OLÚWA rán àrá àti yìnyín, mọ̀nàmọ́ná sì bù sí orí ilẹ̀. OLÚWA rọ òjò yìnyín sí orí ilẹ̀ Éjíbítì;

24ⓒ Yìnyín rọ̀, mọ̀nàmọ́ná sì bẹ̀rẹ̀ sí bù sí orí ilẹ̀ èyí ni ó tí ì buru jù ti ó ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ti Éjíbítì ti di orílẹ̀ èdè.

25Jákè jádò gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì ni yìnyín ti pa gbogbo ohun tí ó wà ni orí pápá; ènìyàn àti ẹranko, ó wò gbogbo ohun ọ̀gbìn lulẹ̀ ó sì fa gbogbo igi ya pẹ̀lú.

26Ilẹ̀ Gósénì ni ibi ti àwọn Ísírẹ́lì wà nikan ni òjò yìnyín náà kò rọ̀ dé.

27Nígbà náà ni Fáráò pe Mósè àti Árónì sì ọ̀dọ́ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ ní àkókò yìí; OLÚWA jẹ́ olódodo ṣùgbọ́n èmi àti àwọn ènìyàn mi ni aláìsòdodo.

28Èyí ti òjò yìnyín àti àrá rọ̀ yìí tó gẹ́ẹ́, gbàdúrà sí OLÚWA kí ó dáwọ́ rẹ̀ dúró. Èmi yóò jẹ́ kí ẹ lọ, n kò tún ni dá a yín dúró mọ́.”

29Mósè dá a lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúró ní àárin ilú, èmi yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí OLÚWA, sísàn àrá yóò dáwọ́ dúró, yìnyín kò sì ni rọ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé OLÚWA ni ó ni ilẹ̀.

30Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ kò bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run.”

31(Òwú àti ọkà báálì sí bàjẹ́ ni ìwọ̀n ìgbà ti wọn so ṣùgbọ́n ti ọkà-báálì kò lajú ti òwú kò sì là.

32Onírúurú ọkà-wíìtì (jéró àti sípélítì) kò bàjẹ́, èṣo wọn padà gbó nítorí wọ́n máa ń pẹ so.)

33Nígbà náà ni Mósè kúrò ni iwájú Fáráò, ó kúrò ni àárin ìgboro kọjá lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí OLÚWA, sísán àrá àti òjò yìnyín ti ń rọ̀ sì dáwọ́ dúró, òjò kò sì rọ̀ sí orí ilẹ̀ mọ́.

34Nígbà tí Fáráò rí i pé òjò àti yìnyín àti àrá ti ń sán ti dáwọ́ dúró, ó tún ṣè ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ọkan Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀ yigbì.

35Ọkàn Fáráò sì yigbì, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó lọ, bí OLÚWA ti sọ láti ẹnu Mósè.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>