1
2Títí ó fi di ọjọ́ tí a gbà á lọ sókè ọ̀run, lẹ́yìn tí ó ti sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn àpósítélì tí ó yàn
3Lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀, ó fi ara rẹ̀ hàn fún wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tí ó dájú pé òun wà láàyè. Ó fi ara hàn wọ́n fún ogójì ọjọ́, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run.
4
5Nítorí Jòhánù fi omi bamitíìsì yín, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ díẹ̀ sí i, a o fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitíìsì yín.”
6Nítorí náà, nígbà tí wọ́n sì péjọ pọ̀, wọn bi í léèrè pé, “Olúwa, láti ìgbà yí lọ ìwọ yóò ha mú ìjọba padà fún Ísírẹ́lì bí?”
7Ó sì wí fún wọn pé, “Kì í ṣe ti yín ni láti mọ àkókò tàbí ìgbà tí Baba ti yàn nípa àṣẹ òun tìkárarẹ̀.
8
9
10Bí wọ́n sì ti tẹjúmọ́ ojú ọ̀run bí ó ti ń lọ sókè, lójijì, àwọn ọkùnrin méjì tí ó wọ aṣọ funfun dúró létí ọ̀dọ̀ wọn.
11Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀yin ara Gálílì, è é ṣe tí ẹ̀yin fi dúró tí ẹ̀ ń wo ojú ọ̀run? Jésù yìí, tí a gbà sókè ọ̀run kúrò lọ́wọ́ yín, yóò padà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí tí ó ń lọ sì ọ̀run.”
12Lẹ́yìn náà ni wọ́n padà sí Jerúsálému láti orí òkè ti a ń pè ni Ólífì, tí ó tó ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ ìsinmi kan.
13
14Gbogbo àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn obìnrin àti Màríà ìyá Jésù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ọkàn kan dúró láti máa gbàdúrà.
15Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni Pétérù sí díde dúró láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn (iye àwọn ènìyàn gbogbo nínú ìjọ jẹ́ ọgọ́fà)
16
17nítorí ọ̀kan nínú wa ni òun ń se tẹ́lẹ̀, òun sì ní ìpín nínú iṣẹ́-ìránṣẹ́ yìí.”
18(Júdásì fi èrè àìsòótọ́ rẹ̀ ra ilẹ̀ kan; nígbà tí ó sì subú ni ògèdèǹgbé, ó bẹ́ ní agbede-méjì, gbogbo ifun rẹ̀ sì tú jáde.
19Ó si di mímọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń gbé Jerúsálémù; nítorí náà ni wọ́n fi ń pè ilẹ̀ náà ni Ákélídámà ní èdè wọn, èyí sì ni, Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ́.)
20
21Nítorí náà, ó di dandan láti yan ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin wọn tí wọn ti ń bá wa rìn ni gbogbo àkókò tí Jésù Olúwa ń wọlé, tí ó sì jáde láàrin wa.
22Bẹ́ẹ̀ láti ìgbà bamitíìsì Jòhánù títí ó fi di ọjọ́ náà ti a gbe é lọ sókè kúrò lọ́dọ̀ wa. ó yẹ kí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú wa.”
23Wọn sì yan àwọn méjì, Jósẹ́fù tí a ń pè ní Básábà, (ẹni tí a sọ àpèlé rẹ̀ ni Júsítúsì) àti Màtíà.
24Wọn sì gbàdúrà, wọn sì wí pé, “Olúwa, ìwọ mọ ọkàn gbogbo ènìyàn, fihàn wá nínú àwọn méjì yìí, èwo ni ìwọ yàn
25kí ó lè gba ipò nínú iṣẹ́-ìránṣẹ́ àpósítélì yìí, èyí tí Júdásì kúrò nínú rẹ̀, ki òun kí ó lè lọ sí ipò ti ara rẹ̀.”
26Wọ́n sì dìbò fún wọn; ibò sí mú Mátíà; a sì kà á mọ́ àwọn àpósitélì mọ́kànlá.