1Àwọn àpósítélì àti àwọn arákùnrin ti ó wà ni Jùdíà sì gbọ́ pé àwọn aláìkọlà pẹ̀lú ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
2Nígbà tí Pétérù sì gòkè wá sí Jerúsálémù, àwọn ti ìkọlá ń bá a wíjọ́
3wí pé, “Ìwọ wọlé tọ àwọn ènìyàn aláìkọlà lọ, ó sì bá wọn jẹun.”
4
5“Èmi wà ni ìlú Jópà, mo ń gbàdúrà, mo rí ìran kan lójúran. Ohun èlò kan sọ̀kalẹ̀ bí ewé tákàdá ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá; ó sì wá títí de ọ̀dọ̀ mi.
6Mo tẹjúmọ́ ọn, mo sì fiyèsí i, mo sí rí ẹran ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin, àti ẹranko ìgbẹ́, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run.
7Mo sì gbọ́ ohùn kan ti ó fọ̀ sí mi pé, ‘Dìde, Pétérù: máa pa, kí ó sì máa jẹ.’
8“Ṣùgbọ́n mo dáhùn wí pé, ‘Àgbẹdọ̀, Olúwa! nítorí ohun èèwọ̀ tàbí ohun aláìmọ́ kan kò wọ ẹnu mi rí láí.’
9“Ṣùgbọ́n ohùn kan dáhùn nígbà ẹ̀ẹ̀kéjì láti ọ̀run wá pé, ‘Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, kí ìwọ má ṣe pè é ní àìmọ́.’
10Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà mẹ́ta; a sì tún fa gbogbo rẹ̀ sókè ọ̀run.
11“Sì wò ó, lójúkan náà ọkùnrin mẹ́ta dúró níwájú ilé ti a gbé wà, ti a rán láti Kesaríà sí mi.
12Ẹ̀mí sì wí fún mi pé, kí èmi bá wọn lọ, ki èmi má ṣe kọminú ohunkóhun. Àwọn arákùnrin mẹ́fà wọ̀nyí sì bá mi lọ, a sì wọ ilé ọkùnrin náà:
13Ó sì sọ fún wa bí òun ti rí ańgẹ́lì kan tí ó dúró ní ilé rẹ̀, tí ó sì wí pé, ‘Ránṣẹ́ lọ sí Jópà, kí ó sì pe Símónì tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ Pétérù;
14Ẹni tí yóò sọ ọ̀rọ̀ fún ọ, nípa èyí tí a ó fi gba ìwọ àti gbogbo ilé rẹ là.’
15“Bí mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sì sọ, Ẹ̀mi Mímọ́ sì bà lé wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti bà lé wa ni àtètèkọ́ṣe.
16
17Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run sì ti fi irú ẹ̀bùn kan náà fún wọn bí ó ti fi fún àwa pẹ̀lú nígbà tí a gba Jésù Kírísítì Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí n ó fi rò pé mo le è de Ọlọ́run ní ọ̀nà?”
18Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́, wọ́n sì yin Ọlọ́run ógo wí pé, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run fi ìrònúpíwàdà sí ìyè fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú!”
19
20Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bẹ nínú wọn tí ó jẹ́ ará Sáípúrọ́sì àti Kírénè; nígbà tí wọ́n dé Áńtíókù, wọ́n sọ̀rọ̀ fún àwọn Hélénì pẹ̀lú, wọ́n ń wàásù Jésù Olúwa.
21Ọwọ́ Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn: ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì gbàgbọ́, wọ́n sì yípadà sí Olúwa.
22Ìròyìn nípa wọn sì dé etí ìjọ ti ó wà ni Jerúsálémù; wọ́n sì rán Bánábà lọ títí dé Áńtíókù;
23Nígbà ti ó dé ti ó sì rí ẹ̀rí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì gba gbogbo wọn níyànjú pé, pẹ̀lú ìpinu ọkàn ni kí wọn fi ara mọ́ Olúwa.
24Nítorí òun jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ìgbàgbọ́; ènìyàn púpọ̀ ni a sì kà kún Olúwa.
25Bánábà sì jáde lọ sí Tásọ́sì láti wá Ṣọ́ọ̀lù,
26nígbà tí ó sì rí i, ó mú un wá sí Áńtíókù. Fún ọdún kan gbáko ni wọ́n fi ń bá ìjọ péjọ pọ̀, tí wọ́n sì kọ́ ènìyàn púpọ̀. Ní Áńtíókù ni a sì kọ́kọ́ ti pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni “Kírísítìánì.”
27Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn wòlíì sì ti Jerúsálémù sọ̀kalẹ̀ wá sí Áńtíókù.
28Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn, ti a ń pè ni Ágábù sí dìde, ó ti ipa Ẹ̀mí sọ pé, ìyàn ńlá yóò mú yíká gbogbo ilẹ̀ Róòmù. (Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìsèjọba Kíláúdíù.)
29Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pinnu, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti tó, láti rán ìrànlọ́wọ́ sí àwọn arakùnrin tí ó wà ní Jùdíà.
30Wọn sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn sì fi i ránṣẹ́ sí àwọn àgbà láti ọwọ́ Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù.