1Ó sì wá sí Dábè àti Lísírà: sí kíyèṣi i, ọmọ-ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀, tí a ń pè ní Tìmótíù, ọmọ obìnrin kan tí í ṣe Júù, tí ó gbàgbọ́; ṣùgbọ́n Gíríkì ní baba rẹ̀.
2Ẹni tí a ròhìn rẹ̀ ní rere lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin tí ó wà ní Lísírà àti Ìkóníónì.
3Òun ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí ó bá òun lọ; ó sì mú un, ó sì kọ ọ́ ní ilà, nítorí àwọn Júù tí ó wà ní agbégbé wọ̀nyí: nítorí gbogbo wọn mọ̀ pé, Gíríkì ni baba rẹ̀.
4Bí wọn sì ti ń la àwọn Ìlú lọ, wọ́n ń fi àwọn àṣẹ, tí a tí pinnu láti ọ̀dọ̀ àwọn àpósítélì àti àwọn alàgbà tí ó wà ní Jerúsálémù, lé wọn lọ́wọ́ láti máa pa wọ́n mọ́.
5Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ sì fẹsẹmúlẹ̀ ní ìgbágbọ́, wọn ṣí ń pọ̀ sí i ní iye lójoojumọ́.
6Wọ́n sì la agbégbé Fírígíà já, àti Gálátíà, nítorí tí Ẹ̀mí Mímọ́ kọ̀ fún wọn láti ṣọ ọ̀rọ̀ náà ni Éṣíà.
7Nígbà tí wọ́n dé ọ̀kánkán Mísíà, wọ́n gbìyànjú láti lọ ṣí Bítíníà, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Jéṣù kò gbà fún wọn.
8Nígbà tí wọ́n sì kọjà lẹ́bá Mísíà, wọ́n ṣọ̀kalẹ̀ lọ ṣi Tíróásì.
9Ìran kan si hàn sì Pọ́ọ̀lù ni òru: Ọkùnrin kan ará Makedóníà dúró, ó sì ńbẹ̀ ẹ̀, wí pé, “Rékọjá wá ṣí Makedóníà, kí o sí ràn wá lọ́wọ́!”
10Nígbà tí ó sì tí rí ìran náà, lọ́gán ó múra láti lọ sí Makedóníà, a gbà á sí pé, Olúwa tí pè wá láti wàásù ìyìn rere fún wọn.
11Nítorí náà nígbà tí àwa ṣíkọ̀ ní Tíróáṣì a ba ọ̀nà tàrà lọ ṣí Sámótírakíà, ni ijọ́ kéjì a sì dé Níápólì;
12Láti ibẹ̀ àwa sì lọ si Fílípì, Ìlú kan tí (àwọn ara Róòmù) tẹ̀dó tí í ṣe olú ìlú yìí fún ọjọ́ mélòókán.
13Lọ́jọ́ ìsinmi, àwa sí jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà, lẹ́bá odò kan, níbi tí a rò pé ibi àdúrà wà; àwa sí jókóò, a sì bá àwọn obìnrin tí o péjọ ṣọ̀rọ̀.
14Àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Lìdíà, tí ó ń ta àwọn aró ẹlẹ́ṣè àlùkò, gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, ọkàn ẹni tí Olúwa ṣí láti fetísì ohun tí a tí ẹnu Pọ́ọ̀lù sọ.
15Nígbà tí a sí bamitíìsì rẹ̀, àti àwọn ara ilé rẹ̀, ó bẹ̀ wá, wí pé, “Bí ẹ̀yin bá kà mí ni olóòtọ́ sí Olúwa, ẹ wá si ilé mi, kí ẹ sí wọ̀ níbẹ̀!” O sí rọ̀ wá.
16Bí àwa tí nlọ ṣí ibi àdúrà náà, ọmọbìnrin kan tí o ní ẹ̀mí ìwosẹ́, pàdé wa, ẹni tí ó fi àfọ̀ṣẹ mú èrè púpọ̀ wá fún àwọn ọ̀gá rẹ̀:
17Òun náà ni ó ń tọ Pọ́ọ̀lù àti àwa lẹ́hìn, ó sì ń kígbe, pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni ìránṣẹ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ń kéde ọ̀nà ìgbàlà fún yin!”
18Ó sì ń ṣe èyí lọ́jọ́ púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí inú Pọ́ọ̀lù bàjẹ́, tí ó sì yípadà, ó wí fún ẹ̀mí náà pé, “Mo pàṣẹ fún ọ ní orúkọ Jéṣù Kíríṣítì kí o jáde kúrò lára rẹ̀!” Ó sí jáde ni wákàtí kan náà.
19Nígbà tí àwọn ọ̀gá rẹ̀ sì ríì pé, ìgbẹ́kẹ̀lé èrè wọn pin, wọ́n mú Pọ́ọ̀lù àti Sílà, wọn sì wọ́ wọn lọ sí ọjà tọ àwọn aláṣẹ lọ;
20Nígbà tí wọ́n sì mú wọn tọ àwọn onídájọ́ lọ, wọ́n wí pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí í ṣe Júù, wọ́n ń yọ ìlú wa lẹ́nu jọjọ;
21Wọ́n sí n kọ́ni ní àṣà tí kò yẹ fún wa, àwa ẹni tí í ṣe ara Romu, láti gbà àti láti tẹ̀lé.”
22
23Nígbà tí wọ́n sì lù wọ́n púpọ̀, wọ́n sọ wọ́n sínú túbú, wọ́n kìlọ̀ fún onítúbú kí ó pa wọ́n mọ́ dáradára:
24Nígbà tí ó gbọ́ irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ̀ wọ́n ṣínú túbú tí inú lọ́hùn, ó sí kan àbà mọ wọ́n lẹ́ṣẹ̀.
25Ṣùgbọ̀n láàrin ọ̀gànjọ́ Pọ́ọ̀lù àti Ṣílà ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn si Ọlọ́run: àwọn ara túbú sì ń tẹ́tí sí wọn.
26Lójijì ilẹ̀ mímì ńlá sì mi, tóbẹ́ẹ̀ tí ìpilẹ̀ ile túbú mì tìtì: lọ́gán, gbogbo ilẹ̀kùn sì sí, ìde gbogbo wọn sì tú ṣílẹ̀.
27Nígbà tí onítúbú si tají, tí o sì ri pé, àwọn ìlẹ̀kùn túbú tí sí sílẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣebí àwọn ara túbú ti sá lọ.
28Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù gbé ohun rẹ̀ sókè, wí pé, “Má se pa ara rẹ lára: nítorí gbogbo wa ń bẹ níhìn yìí!”
29Nígbà tí ó sì beere iná, ó bẹ́ wọ inú ilé, ó ń wárìrì, ó wólẹ̀ níwájú Pọ́ọ̀lù àti Sílà.
30Ó sì mú wọn jáde, ó ní, “Alàgbà, kín ni ki èmi ṣe ki n lè là?”
31Wọ́n sì wí fún un pé, “Gbá Jéṣù Kírísítì Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là, ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ pẹ̀lú.”
32Wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un, àti fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀.
33Ó sì mú wọn ní wákàtí náà lóru, ó wẹ ọgbẹ́ wọn; a ṣi bamitíìsì rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ lójúkan náà.
34Ó sì mú wọn wá ṣí ilé rẹ̀, ó sì gbé ounjẹ kalẹ̀ níwájú wọn, ó sì yọ̀ gidigidi pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, nítorí ó gba Ọlọ́run gbọ́.
35Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn onídájọ́ rán àwọn ọlọ́pàá pé, “Tú àwọn ènìyàn náà ṣílẹ̀.”
36Onítúbú sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Pọ́ọ̀lù, wí pé, “Àwọn onídájọ́ ránṣẹ́ pé kí á da yín ṣílẹ̀: ǹjẹ́ nisinsìnyìí ẹ jáde kí ẹ sì máa lọ ní àlàáfíà.”
37Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù wí fún wọn pé, “Wọ́n lù wá ni gbangba, wọ́n sì sọ wá sínú túbú ni àìjẹ̀bí, àwa ẹni tí ì ṣe ara Róòmù: ṣe nísinsìnyìí wọ́n fẹ́ tì wá jáde nikọ̀kọ̀? Àgbẹdọ̀! Ṣùgbọ́n kí àwọn tìkara wọn wá mú wa jáde!”
38Àwọn ọlọ́pàá sì sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn onídàjọ́: ẹ̀rù sì bà wọ́n, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ará Róòmù ni wọ́n.
39Wọ́n sì wá, wọ́n sìpẹ̀ fún wọ́n, wọn sì mú wọn jáde, wọ́n sì bẹ̀ wọ́n pé, ki wọn jáde kúrò ni ìlú náà.
40Wọ́n sì jáde nínú túbú, wọ́n sì wọ ilé Lídíà lọ: nígbà tí wọn sì tí rí àwọn arákùnrin, wọ́n tù wọ́n nínú, wọn sì jáde kúrò.