1Nígbà tí wọn sì ti kọjá Áḿfípólì àti Apolóníà, wọ́n wá sí Tẹsalóníkà, níbi tí sínágọ́gù àwọn Júù wà:
2Àti Pọ́ọ̀lù, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó wọlé tọ̀ wọ́n lọ, ni ọjọ́ ìsinmi mẹ́ta ó sì ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú ìwé-mímọ́.
3Ó ń túmọ̀, ó sí n fihàn pé, Kíríṣítì kò lè sàìmá jìyà, kí o sì jínde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jéṣu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kírísítì náà.”
4A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà: bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í se díẹ̀.
5Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn si fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ìta ènìyàn mọ́ra, wọ́n gbá ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jásónì, wọ́n ń fẹ́ láti mú wọn jáde tọ àwọn ènìyàn lọ.
6Nìgbà tí wọn kò sì rí wọn, wọ́n wọ́ Jásónì, àti àwọn arákùnrin kan tọ àwọn olórí ìlú lọ, wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn wọ̀nyí tí o tí dorí ayé kodò wá sí ìhínyìí pẹ̀lú.
7Àwọn ẹni tí Jásónì gbà sí ọ̀dọ̀: gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o sí ń hùwà lòdì sí àṣẹ Kéṣárì, wí pé, ọba mìíràn kan wà, Jéṣù.”
8Àwọn ènìyàn àti àwọn olórí ìlú kò ni ìbàlẹ̀ àyà nígbà tí wọ́n gbọ́ nǹkan wọ̀nyí.
9Nígbà tí wọ́n sì gbà ògo lọ́wọ́ Jásónì àti àwọn ìyókù, wọ́n fi wọ́n ṣílẹ̀ lọ.
10Lọ́gán àwọn arákùnrin sì rán Pọ́ọ̀lù àti Ṣílà lọ ṣí Béróéá lóru: nígbà tí wọ́n sí dé ibẹ̀, wọ́n wọ inú ṣínágógù àwọn Júù lọ.
11Àwọn wọ̀nyí sì ní ìyìn ju àwọn tí Tẹsalóníkà lọ, ní tí pé wọn fi tọkàntọkàn gbà ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n sì ń wá inú ìwé-mímọ̀ lójoojúmọ́ bí ǹkan wọ̀nyí bá rí bẹ́ẹ̀.
12Nítorí náà púpọ̀ nínú wọn gbàgbọ́; àti nínú àwọn obìnrin Gíríkì ọlọ́lá, àti nínú àwọn ọkùnrin, kì í ṣe díẹ̀.
13Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù tí Tẹsalóníkà mọ̀ pé, Pọ́ọ̀lù ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Béreóà, wọ́n wá síbẹ̀ pẹ̀lú, wọ́n rú àwọn ènìyàn sókè.
14Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rán Pọ́ọ̀lù jáde lọ́gán láti lọ títí de òkun: ṣùgbọ́n Sílà àti Tímótíù dúró ṣíbẹ̀.
15Àwọn tí ó sin Pọ́ọ̀lù wá sì mú un lọ títí dé Átẹ́nì; nígbà tí wọ́n sì gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wá fún Sílà àti Tímótíù pé, ki wọn ó yára tọ òun wá, wọ́n lọ.
16Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dúró dè wọ́n ni Aténì, ẹ̀mí rẹ̀ ru nínú rẹ̀, nígbà tí ó rí pé ìlú náà kún fún òrìṣà.
17Nítorí náà ó ń bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú Sínágógù, àti àwọn olùfọkànsìn, àti àwọn tí ó ń bá pàdé lọ́jà lójoojúmọ́.
18Nínú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Épíkúrè àti tí àwọn Sítííkì pàdé rẹ̀. Àwọn kan si ń wí pé, “Kín ni aláhesọ yìí yóò rí wí?” Àwọn mìíràn sì wí pé, “Ó dàbí ń wàásù Jésù, àti àjíǹde fún wọn.”
19Wọ́n sì mú un, wọ́n sì fà á lọ ṣí Áréópágù, wọ́n wí pé, “A ha lè mọ̀ kín ni ẹ̀kọ́ titun tí ìwọ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́?
20Nítorí tí ìwọ mú ohun àjèjì wá si etí wa: àwa sì ń fẹ́ mọ̀ kín ni ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí.”
21Nítorí gbogbo àwọn ará Áténì, àti àwọn àlejò tí ń ṣe àtìpó níbẹ̀ kì í ṣe ohun mìíràn jù kí a máa sọ tàbí ki a máa gbọ́ ohun titun lọ.
22Pọ́ọ̀lù si dìde dúró láàrin Áréópágù, ó ní, “Ẹ̀yin ará Áténì, mo wòye pé ní ohun gbogbo ẹ kún fún onírúurú ìsìn jù.
23Nítorí bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo wo àwọn ohun tí ẹ̀yin ń sìn, mo sì rí pẹpẹ kan tí a kọ àkọlé yìí ṣí, ‘FÚN ỌLỌ́RUN ÀÌMỌ̀.’ Ǹjẹ́ ẹni tí ẹyin ń sìn ni àìmọ̀ òun náà ni èmi ń ṣọ fún yin.
24
25Bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ènìyàn sìn ín, bí ẹni pé ó ń fẹ́ nǹkan, òun ni ó fi ìyè àti èémí àti ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn.
26Ó sì tí tipàṣẹ̀ ẹnìkan dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé, ó sì ti pinnu àkókò tí a yàn tẹ́lẹ̀, àti ààlà ibùgbé wọn;
27kí wọ́n baà lè maa wá Olúwa, bóyá wọn yóò lè sàfẹrí rẹ̀, ki wọn sì rí í. Bí ó tílẹ̀ jẹ pé kò jìnnà sí olúkúlùkù wa:
28Nítorí nínú rẹ̀ ni àwa wà láàyè, tí a ń rìn kiri, tí a sì ní ẹ̀mí wa: bí àwọn kan nínú àwọn akéwì tí ẹ̀yin tìkarayín tí wí pé, ‘Àwa pẹ̀lú sì jẹ́ ọmọ rẹ̀.’
29“Ǹjẹ́ bí àwa bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, kò yẹ fún wa láti rò pé, Ẹni-Ijọ́sìn-sí wa dàbí wúrà, tàbí fàdákà, tàbí òkúta, tí a fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ ènìyàn ya èré àwòrán rẹ̀.
30Pẹ̀lúpẹ̀lù ìgbà àìmọ̀ yìí ni Ọlọ́run tí gbójú fò dá; ṣùgbọ́n nísìnyìí ó pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ronúpìwàdà;
31Níwọ̀n bí ó ti dá ọjọ́ kan, nínú èyí tí yóò ṣe ìdájọ́ ayé lódodo nípaṣẹ̀ ọkùnrin náà tí ó ti yàn, nígbà tí ó ti fi ohun ìdánilójú fún gbogbo ènìyàn, níti pé ó jí dìde kúrò nínú òkú.”
32Nígbà tí wọ́n ti gbọ́ ti àjíǹde òkú, àwọn mìíràn ń ṣẹ̀fẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn mìíràn wí pé, “Àwa o tún nǹkan yìí gbọ́ lẹ́nu rẹ̀.”
33Bẹ́ẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù sì jáde kúrò láàrin wọn.
34Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin kan fi ara mọ́ ọn, wọ́n sì gbàgbọ́: nínú àwọn ẹni tí Díónísíù ara Aréópágù wà, àti obìnrin kan tí a ń pè ni Dámárì, àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn.