Ìwé Ìṣe àwọn Àpósítélì 2:1-47 BYB2014 - Bible AI

1Nígbà tí ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sítì sì dé, gbogbo wọn fi ọkàn kan wà ní ibìkan.

2Lójijì ìró sì ti ọ̀run wá, gẹ́gẹ́ bí ìró ẹ̀fúùfù líle, ó sì kún gbogbo ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó.

3Ẹ̀là ahọ́n bí i iná sì yọ sí wọn, ó pín, ó sì bà lé olúkúlùkù wọn.

4Gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn ni ohùn.

5Àwọn Júù olùfọkànsìn láti orílẹ̀-èdè gbogbo lábẹ́ ọ̀run sì ń gbé Jerúsálémù.

6Nígbà tí wọn sì gbọ́ ìró yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ nínú ìdàmú, nítorí tí olúkúlùkù gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní èdè rẹ̀.

7Ẹnu sì yà wọ́n, wọn ń wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ara Gálílì kọ́ ni gbogbo àwọn tí ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́?

8Èé ha sì tí ṣe ti olúkúlùkù wa fi ń gbọ́ bí wọ́n tí ń fi èdè sọ̀rọ̀?

9Àwọn ará Pátíríà, àti Médísì, àti Élámù; àti àwọn tí ń gbé Mesopotamíà, Júdíà, àti Kapadókíà, Pọ́ńtù, àti Ásíà.

10Fírígíà, àti Pàḿfílíà, Íjíbítì, àti agbégbé Líbíà níhà Kírénè; àti àwọn àtìpó Róòmù, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù.

11(àti àwọn Júù àti àwọn tí a tipa ẹ̀sìn sọ di Júù); Àwọn ara Kírétè àti Árábíà; àwa gbọ́ tí wọ́n sọ́rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ńlá Ọlọ́run ni èdè wa.”

12Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n aì wá rìrì. Wọn wí fún ara wọn pé, “Kí ni èyí túmọ̀ sí?”

13Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmìíràn ń sẹ̀fẹ̀, wọn sí wí pé, Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kún fún wáìnì titun.

14Nígbà náà ni Pétérù díde dúró pẹ̀lú àwọn mọ́kànlá yòókù, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin Júù ènìyàn mi àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé Jerúsálémù, ẹ jẹ́ kí èyí kí ó yé yin; kí ẹ sì fétísí ọ̀rọ̀ mi.

15Àwọn wọ̀nyí kò mutí yó, bí ẹ̀yin tí ròó; wákàtí kẹ́ta ọjọ́ sáà ni èyí.

16Bẹ́ẹ̀ kọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ ti a ti sọ láti ẹnu wòlíì Joeli:

17ⓐ “ ‘Ní ìkẹyìn ọjọ́, Ọlọ́run wí pé, Èmi yóò tú Ẹ̀mí mí jáde sára ènìyàn gbogbo, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò sì máa ríran, àwọn arúgbó yín yóò sì máa lá àlá;

18Àti sára àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mi ọkùnrin àti sára àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mi obìnrin, ni Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi jáde ni àwọn ọjọ́ náà: wọn yóò sì máa sọtẹ́lẹ̀;

19Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn lójú ọ̀run, àti àwọn àmì nísàlẹ̀ ilẹ̀; ẹ̀jẹ̀ àti iná àti rírú èéfín;

20A yóò sọ òòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ológo Olúwa tó dé.

21Yóò sì ṣe pé ẹnikẹ́ni tí ó bá pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.’

22“Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Jésù tí Násárẹ́tì, ọkùnrin tí a mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípa iṣẹ́ agbára àti tí ìyanu, àti àmì ti Ọlọ́run ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrin yín, bí ẹ̀yin tíkárayín ti mọ̀ pẹ̀lú.

23Ẹni tí a ti fi lé yín lọ́wọ́ nípa ìpinnu ìmọ̀ àti ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run; àti ẹ̀yin pẹ̀lú, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú kàn mọ́ àgbélébùú, tí a sì pa á.

24Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí díde kúrò nínú òkú, gbà á kúrò nínú ìrora ikú: nítorí tí kò ṣe é ṣe fún ikú láti dì í mú.

25ⓑ Dáfídì tí wí nípa tirẹ̀ pé:

25“ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo niwájú mí, nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi, A kì ó ṣí mi ní ipò.

26Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀: pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí.

27Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà-òkú, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni-Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.

28Ìwọ mú mi mọ ọ̀nà ìyè, ìwọ yóò mú mi kún fún ayọ̀ ni iwájú rẹ.’

29“Ará, èmí lè sọ fún yin pẹ́lú ìgboyà pé ní ti Dáfídì baba ńlá kú, a sì sin ín, ibojì rẹ̀ sì ń bẹ lọ́dọ̀ wa títí di òní yìí.

30ⓒ Ṣùgbọ́n ó jẹ́ wòlíì, àti bí ó mọ́ pé, Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún òun nínú ìbúra pé nínú irú-ọmọ inú rẹ̀, òun yóò mú ọ̀kan jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀.

31ⓓ Ní rírí èyí tẹ́lẹ̀, ó sọ ti àjíǹde Kírísítì, pé a kò fi ọkan rẹ̀ sílẹ̀ ni isà-òkú, bẹ́ẹ̀ ni ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́.

32Jésù náà yìí ni Ọlọ́run ti jí díde sí ìyè, àwa pẹ̀lú sì jẹ́rìí sí èyí.

33A ti gbé ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó tu èyí tí ẹ̀yin rí àti gbọ́ nísinsìyìí sítá.

34ⓔ Nítorí Dáfídì kò gókè lọ sí ọ̀run ṣùgbọ́n òun tìkárarẹ̀ wí pé,

34“ ‘Olúwa wí fún Olúwa mi pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi

35títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀ta rẹ dí àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.” ’

36“Ǹjẹ́ kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì mọ̀ dájúdájú pé: Ọlọ́run ti fi Jésù náà, ti ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, se Olúwa àti Kírísítì.”

37Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ́, wọn sì wí fún Pétérù àti àwọn àpósítélì yòókù pé, “Ará, kín ni àwa yóò ṣe”

38Pétérù sì wí fún wọn pé, “Ẹ ronúpìwàdà, kí a sì bamitíìsì olúkúkùkù yín ní orúkọ Jésù Kírísítì fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ̀yin yóò sì gba ẹbun Ẹ̀mí Mímọ́

39ⓕ Nítorí fún yín ni ìlérí náà, àti fún àwọn ọmọ yín, àti fún gbogbo àwọn tí ó jìnnà réré, àní gbogbo àwọn tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò pè.”

40Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀ mìíràn ni ó fi ń kìlọ̀ tí ó sì ń fi ń rọ̀ wọ́n wí pé, “Ẹ gba ara yín là lọ́wọ́ ìran àrékérekè yìí.”

41Nítorí náà àwọn tí ó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ a bamítíìsì wọn, lọ́jọ́ náà a sì kà ìwọn ẹgbẹ̀rùn mẹ́ta ọkàn kún wọn.

42Wọ́n sì dúró ṣinṣin nínú ẹ̀kọ́ àwọn àpósítélì, àti ní ìdàpọ̀, ní bíbu àkàrà àti nínú àdúrà.

43Ẹ̀rù sí ba gbogbo ọkàn; iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì púpọ̀ ni a ti ọwọ́ àwọn àpósítélì ṣe.

44ⓖ Gbogbo àwọn tí ó sì gbàgbọ́ wà ni ibìkan, wọn ní ohun gbogbo sọ́kàn;

45Wọn si ń ta ohun ìní àti ẹrù wọn, wọn sì ń pín wọn fún olúkúlùkù, gẹ́gẹ́ bí ẹnikẹ́ni tí í ṣe aláìní.

46Wọ́n fi ọkàn kan dúró lójoojúmọ́ nínú tẹ́mpílì. Wọ́n ń bu àkàrà ní ilé wọn, wọn ń fi inú dídùn àti ọkàn òtítọ́ jẹ oúnjẹ wọn.

47Wọ́n yín Ọlọ́run, wọn sì rí ojú rere lọ́dọ̀ ènìyàn gbogbo, Olúwa sí ń yàn kún wọn lójoojúmọ́, àwọn tí à ń gbàlà.

article>