Ìwé Ìṣe àwọn Àpósítélì 22:1-30 BYB2014 - Bible AI

1“Ẹ̀yin ará àti baba, ẹ gbọ́ tí ẹnu mi nísinsìnyìí.”

2Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ni èdè Árámáíkì, wọ́n túbọ̀ dákẹ́ jẹ́ẹ́.

2Nígbà náà ni ó wí pé:

3“Júù ni èmi í ṣe, a bí mi ni Tásọ́sì ìlú kan ní Kílíkíà, ṣùgbọ́n tí a tọ́ mi dàgbà ni ìlú yìí. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ Gàmálíẹ́lì ni a sì gbé kọ́ mi ní òfin àwọn baba wa, tí mo sì jẹ́ onítara fún Ọlọ́run àní gẹ́gẹ́ bí gbogbo yin tí rí ni òní.

4ⓐ Mo sì ṣe inúnibíni sí àwọn ènìyàn tí ń tọ ọ̀nà yìí dé ojú ikú wọn, mo dè tọkùnrin àtobìnrin wọ́n, mo sì fi wọ́n sínú túbú,

5àní bí olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo àjọ àwọn alàgbà tí lè jẹ́ mi ní ẹ̀rí. Mo tilẹ̀ gba ìwé àṣẹ lọ́wọ́ wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arakùnrin wọn ní Dámásíkù láti mú àwọn tí ó wà níbẹ̀ ní dídè wá sí Jerúsálémù, láti jẹ wọ́n níyà.

6“Bí èmi tí súnmọ́ etí Dámásíkù níwọ̀n ọjọ́kanrí, lójijì ìmọ́lẹ̀ ńlá láti ọ̀run wá mọ́lẹ̀ yí mi ká.

7Mo sì subú lulẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan tí ó wí fún mi pé, ‘Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?’

8“Mo sì béèrè pé, ‘Ta ni ìwọ́, Olúwa?’ “Ó sì dá mi lóhùn pé, ‘Èmi ni Jésù tí Násárétì, ẹni tí ìwọ́ ń ṣe inúnibíni sí.’

9Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi rí ìmọ́lẹ̀ náà nítòótọ́, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ohùn ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀.

10“Mo sí béèrè pé, ‘Kín ni kí èmí kí ó ṣe, Olúwa?’ “Olúwa sì wí fún mi pé, ‘Dìde, kí o sì lọ sí Dámásíkù; níbẹ̀ ni a ó sì ti sọ ohun gbogbo fún ọ tí a yàn fún ọ láti ṣe.’

11Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi fà mí lọ́wọ́ wọ Dámásíkù lọ nítorí tí èmi kò lè ríran nítorí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ náà ti fọ́ mi ní ojú.

12“Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Ananáyà tọ̀ mí wá, ẹni tó jẹ́ olùfọkànṣìn ti òfin, tí ó sì lórúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn Júù tí ó ń gbé ibẹ̀.

13Ó sì dúró tì mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Arákùnrin Ṣọ́ọ̀lù, gba ìríran!’ Ní ẹsẹ̀ kan náà, mo sì sí ojú sí òkè mo sì lè rí i.

14“Nígbà náà ni ó wí pé: ‘Ọlọ́run àwọn baba wa ti yàn ọ́ láti mọ ìfẹ́ rẹ̀, àti láti ri Ẹni Òdodo náà, àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu rẹ̀.

15Ìwọ yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn, nínú ohun tí ìwọ tí rí tí ìwọ sì ti gbọ́.

16Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, kín ni ìwọ ń dúró dè? Dìde, kí a sì bamitíìsì rẹ̀, kí ó sì wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù, kí ó sì máa pé orúkọ rẹ̀.’

17“Nígbà tí mo padà wá sí Jerúsálémù tí mo ǹ gbàdúrà ní tẹ́ḿpílì, mo bọ́ sí ojúran,

18mo sì rí Olúwa, ó ń sọ̀rọ̀ fún mi pé, ‘Kíá! Jáde kúrò ní Jerúsálémù kán-kán, nítorí wọn kì yóò gba ẹ̀rí rẹ nípa mi gbọ́.’

19“Èmi sì wí pé, ‘Olúwa, àwọn ènìyàn wọ̀nyí pàápàá mọ̀ pé èmi ti lọ láti inú sínágọ́gù kan sí èkejì láti máa sọ wọ́n sínú túbú àti láti máa lu àwọn tí ó gbà ọ́ gbọ́.

20Nígbà tí a sì ta ẹ̀jẹ̀ Sítéfánù ẹlẹ́ríì rẹ sílẹ̀, èmi náà pẹ̀lú dúró níbẹ̀, mo sì ní ohùn sí ikú rẹ̀, mo sì ń se ìtọ́jú aṣọ àwọn ẹni tí ó pa á.’

21“Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, ‘Máa lọ: nítorí èmi ó rán ọ sí àwọn aláìkọlà lókèèrè réré.’ ”

22Wọ́n sì fi etí sí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù títí tí ó fi sọ ọ̀rọ̀ yìí. Nígbà yìí ni wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì kígbe wí pé, “Ẹ mu ẹni yìí kúrò láyé! Kò yẹ kí ó wà láàyè!”

23Bí wọ́n sì ti ń kígbe, tí wọ́n sì ń jú aṣọ wọn káàkiri, tí wọ́n ń ku eruku sí ojú ọ̀run,

24olórí ogun pàṣẹ pé kí a mú Pọ́ọ̀lù wá sínú àgọ́ àwọn ológun. Ó sì pàṣẹ kí wọ́n ó lù ú, kí wọn fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò, kí òun baà lè mọ ìdí tí wọ́n fi ń kígbe lé e lórí bẹ́ẹ̀.

25Bí wọ́n sí tí fi okùn-ọṣán dè é, Pọ́ọ̀lù bí balógun ọ̀rún tí ó dúró tì í pé, “Ó ha tọ́ fún yín láti na ẹni tí i ṣe ará Róòmù ni àìdálẹ́bi bí?”

26Nígbà tí balógun ọ̀rún sì gbọ́ èyí, ó lọ wí fún olórí-ogun pé, “Kín ni ó fẹ́ ṣe yìí: nítorí ọkùnrin yìí ará Róòmù ní i ṣe?”

27Olórí-ogun sì dé, ó sì bí Pọ́ọ̀lù pé, “Sọ fún mi, ará Róòmù ni ìwọ jẹ́ bí?” Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”

28Olórí-Ogun sì dáhùn wí pé, “Owó púpọ̀ ni mo fi ra ọlá ìbílẹ̀ yìí.” Pọ́ọ̀lù wí pé, “Ṣùgbọn a bí mi sínú rẹ̀ ni.”

29Nítorí náà àwọn tí ó múra láti fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀: lójúkan náà. Ọlórí-ogun pẹ̀lú sì bẹ̀rù nígbà tí ó mọ̀ pé ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ní Pọ́ọ̀lù i ṣe, àti nítorí ó tí dè é.

30Ní ijọ́ kéjì, nítorí tí olórí-ogun fẹ́ mọ̀ dájúdájú ohun tí àwọn Júù ń fi Pọ́ọ̀lù sùn sí, ó túu sílẹ̀, ó pàṣẹ kí àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ péjọ, nígbà náà ni ó mú Pọ́ọ̀lù sọ̀kalẹ̀, ó sì mú un dúró ní wájú wọn.

/article>