Ìwé Ìṣe àwọn Àpósítélì 27:1-44 BYB2014 - Bible AI

1Bí a sì ti pinnu rẹ̀ pé kí a wọ ọkọ̀ lọ sí Ítalì, wọn fi Pọ́ọ̀lù àti àwọn òǹdè mìíràn lé balógun ọ̀rún kan lọ́wọ́, ti a ń pè ní Júlíọ́sì, ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun Ọ̀gọ́sítúsì.

2Nígbà tí a sì wọ ọkọ̀-okun Ádírámítíù kan, tí a fẹ́ lọ sí àwọn ìlú ti ó wà létí òkun Éṣíà, a ṣíkọ̀: Árísítakù, ará Makedóníà láti Tẹsalóníkà wà pẹ̀lú wa.

3Ní ijọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí Sídónì. Júlíọ́sì sì ṣe inú rere sì Pọ́ọ̀lù, ó sì fún un láàyè kí ó máa tọ àwọn ọrẹ̀ rẹ̀ lọ kí wọn le se ìtọ́jú rẹ̀.

4Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ níbẹ̀, a lọ lẹ́bá Kípírúsì, nítorí tí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì.

5Nígbà tí a ré òkun Kílíkíà àti Paḿfílíà kọjá, a gúnlẹ̀ sí Mírà ti Líkíà.

6Níbẹ̀ ni balogun ọ̀rún sì rí ọkọ̀-okun Alekisáńdírà kan, ti ń lọ sí Ítalì; ó sì fi wa sínú rẹ̀.

7Nígbà tí a ń lọ jẹ́jẹ́ ní ọjọ́ púpọ̀, ti a fi agbára káká dé ọkánkán Nídúsì, àti nítorí tí afẹ́fẹ́ kò fún wa láàyè, a ba ẹ̀bá Kírétè lọ, lọ́kankán Sálímónì;

8Nígbà tí a sì fi agbára káká kọjá rẹ̀, a dé ibi tí a ń pè ní Èbùté Yíyanjú, tí ó súnmọ́ ìlú Láséà.

9Nígbà ti a sì ti sọ ọjọ́ púpọ̀ nù, àti pé ìrìn-àjò wa sì ti léwu gan-an nítorí nisinsinyìí ààwẹ̀ ti kọjá lọ, Pọ́ọ̀lù dá ìmọ̀ràn.

10Ó sì wí fún wọn pé, “Alàgbà, mo wòye pé ìṣíkọ̀ yìí yóò ní ewu, òfò púpọ̀ yóò sì wá, kì í ṣe kìkì ti ẹrù àti ti ọkọ̀, ṣùgbọ́n ti ọkàn wa pẹ̀lú.”

11Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún gba ti olórí ọkọ́ àti ti ọlọ́kọ̀ gbọ́, ju ohun wọ̀nyí tí Pọ́ọ̀lù wí lọ.

12Àti nítorí pé èbúté náà kò rọrùn láti lo àkókò òtútù níbẹ̀, àwọn púpọ̀ sí dámọ̀ràn pé, kí a lọ kúrò níbẹ̀, bóyá wọn ó lè làkàkà dé Fóníkè, tí i ṣe èbúté Kírétè ti ó kọjú sí òsì ìwọ̀-oorùn, àti ọ̀tún ìwọ̀-oorùn, láti lo àkókò òtútù níbẹ̀.

13Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúsù sì ń fẹ́ jẹ́jẹ́, tí wọn ṣèbí ọwọ́ àwọn tẹ ohun tí wọn ń wá, wọ́n ṣíkọ̀, wọn ń pá ẹ̀bá Kírétè lọ.

14Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà ni ìjì ti a ń pè ni Éúrákúílò fẹ́ lù ú.

15Nígbà ti ó sì ti gbé ọkọ̀-okun náà, ti kò sì lè dojúkọ ìjì yìí, a fi i sílẹ̀, ó ń gbá a lọ.

16Nígbà tí ó sì gbá a lọ lábẹ́ erékùsù kan tí a ń pè Kíláúdà, ó di iṣẹ́ púpọ̀ kí a tó lè súnmọ́ ìgbàjà.

17Nígbà tí wọ́n sì gbé e sókè, wọn sa agbára láti dí ọkọ́-òkun náà nísàlẹ̀, nítorí tí wọ́n ń bẹ̀rù kí á máa ba à gbé wọn sórí iyanrin-dídẹ̀, wọn fi ìgbòkun sílẹ̀, bẹ́ẹ́ ni a sì ń gbá wa kiri.

18Bí a sì ti ń ṣe làálàá gidigidi nínú ìjì náà, ni ijọ́ kejì wọn kó ẹrù-ọkọ̀ dà sí omi láti mú ọkọ̀ fẹ́rẹ̀;

19Ní ijọ́ kẹta, wọ́n fi ọwọ́ ara wọn kó ohun-èlò ọkọ̀ dànù.

20Nígbà tí òòrùn àti ìràwọ̀ kò si hàn lọ́jọ́ púpọ̀, tí ìjì náà kò sì mọ níwọ̀n fún wa, àbá àti là kò sí fún wa mọ́.

21Nígbà tí wọ́n wà ní àìjẹun lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà náà Pọ́ọ̀lù dìde láàrin wọn, ó ní, “Alàgbà, ẹ̀yin bá ti gbọ́ tèmi kí a má ṣe ṣíkọ̀ kúrò ní Kírétè, ewu àti òfò yìí kì ìbá ti bá wa.

22Ǹjẹ̀ nísinsìn yìí mó gbà yín níyànjú, kí ẹ tújúká; nítorí kí yóò sí ẹni tí yóò nù, bí kò ṣe ti ọkọ̀.

23Nítorí ańgẹ́lì Ọlọ́run, ẹni tí èmi jẹ́ tirẹ̀, àti ẹni ti èmi ń sìn, ó dúró tì mi ni òru àná.

24Ó wí pé, ‘Má bẹ̀rù, Pọ́ọ̀lù; ìwọ kò lè ṣàìmá dúró níwájú Késárì: Sì wò ó, Ọlọ́run ti fi gbogbo wọn ti ó bá ọ wọ ọkọ̀ pọ̀ fún ọ.’

25Ǹjẹ́ nítorí náà, alàgbà, ẹ dárayá: nítorí mo gba Ọlọ́run gbọ̀ pé, yóò rí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fún mi.

26Ṣùgbọ́n a ó gbá wa jù sí erékùṣù kan.”

27Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru ọjọ́ kẹrìnlá, bí a ti ń gbé wa kọjá lọ láàrin òkun Ádíríà, láàrin ọ̀gànjọ́ àwọn atukọ̀ fura pé, àwọn súnmọ́ etí ilẹ̀ kan:

28Nígbà tí wọ́n sì wọn òkun, wọ́n rí i ó jìn ní ogún ìgbọ̀nwọ́, nígbà tì í wọ́n sún ṣíwájú díẹ̀, wọ́n sì tún wọn òkun, wọn rí i pé ó jìn ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dógùn.

29Nígbà tí wọ́n bẹ̀rù kí wọn má ṣe rọ́ lu orí òkúta, wọ́n sọ ìdákọ̀ro mẹ́rin sílẹ̀ ni ìdí-ọkọ̀, wọ́n ń rétí òjúmọ́.

30Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn atukọ̀ ń wá ọ̀nà láti sá kúrò nínú ọkọ̀, tí wọ́n sì ti sọ ìgbàjá kalẹ̀ sí ojú òkun, bí ẹni pé wọn ń fẹ́ sọ ìdákọ̀ró sílẹ̀ níwájú ọkọ̀.

31Pọ́ọ̀lù wí fún balógun ọ̀rún àti fún àwọn ọmọ-ogun pé, “Bí kò ṣe pé àwọn wọ̀nyí bá dúró nínú ọkọ̀ ẹ̀yin kí yóò lè là!”

32Nígbà náà ni àwọn ọmọ ogun gé okùn ìgbàjá, wọ́n jù ú sílẹ̀ kí ó ṣúbu sọ́hun.

33Nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀, Pọ́ọ̀lù bẹ gbogbo wọn kí wọn jẹun díẹ̀, ó wí pé, “Òní ni ó di ìjẹrìnlá tí ẹ̀yin ti ń rétí, ti ẹ kò dẹkun gbígbaàwẹ̀, tí ẹ kò sì jẹun.

34Nítorí náà mo bẹ̀ yín, kí ẹ jẹun díẹ̀, nítorí èyí ni fún ìgbàlà yín: nítorí irun kan kí yóò rẹ́ kúrò lórí ẹnìkan yín.”

35Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì mú àkàrà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run níwájú gbogbo wọn: nígbà tí ó si bù ú, ó bẹ̀rẹ̀ sí i jẹ.

36Nígbà náà ni gbogbo wọn sì daráyá, àwọn pẹ̀lú sì gba oúnjẹ,

37Gbogbo wa tí ń bẹ nínú ọkọ̀-okun náà sì jẹ́ ọ̀rìnlúgba ènìyàn ó dín mẹ́rin (276).

38Nígbà tí wọn jẹun yó tan, wọn bẹ̀rẹ̀ sí mu ọkọ̀-okun náà fúyẹ́, nípa kíkó àlìkámà dà sí omi.

39Nígbà tí ilẹ̀ sí mọ́, wọn kò mọ́ ilẹ̀ náà; ṣùgbọ́n wọn rí apá odò kan tí ó ní èbúté, níbẹ́ ni wọ́n gbérò, bóyá ó le ṣe é ṣe láti mu ọkọ̀ gúnlẹ̀.

40Nígbà tí wọ́n sì gé ìdákọ̀ró kúrò, wọn jù wọn sínú òkun, lẹ́sẹ̀kan náà wọn tú ìdè-ọkọ̀, wọn sì ta ìgbòkùn iwájú ọkọ̀ sí afẹ́fẹ́, wọn sì wakọ̀ kọjú sí etí-òkun.

41Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí òkun méjì pàde, wọn fi orí-ọkọ̀ sọlẹ̀: iwájú rẹ̀ sì kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin, ó dúró, kò lè yí, ṣùgbọ́n agbára rírú omi bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ìdí ọkọ̀ náà.

42Èrò àwọn ọmọ-ogun ni ki a pá àwọn òǹdè, kí ẹnikẹ́ni wọn má ba à wẹ̀ jáde sá lọ.

43Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún ń fẹ́ gba Pọ́ọ̀lù là, ó kọ èrò wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn tí ó lè wẹ̀ kí wọn bọ́ sí òkun lọ sì ilẹ̀.

44Àti àwọn ìyókú, òmìíràn lórí pátakó, àti omíràn lórí àwọn igi tí ó ya kúrò lára ọkọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe tí gbogbo wọn yọ, ní àlàáfíà dé ilẹ́.

/article>