1Ní ọjọ́ kan Pétérù àti Jòhánù jùmọ̀ ń gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlì ní wákàtí àdúrà; tí í ṣe wákàtí mẹ́ta ọ̀sán.
2Wọn sì gbé ọkùnrin kan ti ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ lójoojúmọ́ lẹ́nu-ọ̀nà tẹ́ḿpìlì ti a ń pè ni Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ inú tẹ́ḿpìlì lọ,
3Nígbà tí ó rí Pétérù àti Jòhánù bí wọn tí fẹ́ wọ inú tẹ́ḿpìlì, ó sagbe.
4Pétérù sì tẹjúmọ́ ọn, pẹ̀lú Jòhánù, ó ní “Wò wá!”
5Ó sì fiyèsí wọn, ó ń réti láti rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn.
6Pétérù wí pé, “Góòlù àti fàdákà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyí náà ni mo fifún ọ: Ní orúkọ Jésù Kírísítì ti Násárẹ́tì, dìde kí o sì máa rìn.”
7Ó sì fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó sì gbé dìde; lójúkán náà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ̀ rẹ̀ sì mókun.
8Ó sì ń fò sókè, ó dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, ó sì bá wọn wọ inú tẹ́ḿpìlì lọ, ó ń rìn, ó sì ń fò, ó sì yín Ọlọ́run.
9Gbogbo ènìyàn sì rí i, ó ń rìn, ó sì yin Ọlọ́run:
10Wọn sì mọ̀ pé òun ni ó ti jókòó tí ń ṣagbe lẹ́nu ọ̀nà Dáradára ti tẹ́ḿpìlì náà; hà, sì ṣe wọn, ẹnu sì yà wọn gidigidi sí ohun tí ó ṣe lára rẹ̀.
11Bí arọ ti a mú láradá sì ti di Pétérù àti Jòhánù mú, gbogbo ènìyàn júmọ́ sure tọ̀ wọ́n lọ ni ìloro ti a ń pè ní ti Sólómónì, pẹ̀lú ìyàlẹ́nú ńlá.
12Nígbà tí Pétérù sì rí i, ó dáhùn, ó wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, è é ṣe tí háà fi ń ṣe yín sí èyí? Tàbí è é ṣe ti ẹ̀yin fi tẹjúmọ́ wa, bí ẹni pé agbára tàbí ìwà mímọ́ wa ni àwa fi ṣe é ti ọkùnrin yìí fi ń rìn?
13
14Ṣùgbọ́n ẹ̀yin sẹ́ Ẹni-Mímọ́ àti Olóòtọ̀ náà, ẹ̀yin sì béèrè kí a fi apànìyàn fún un yín.
15Ẹ̀yin sì pa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìyè, ẹni tí Ọlọ́run sì ti jí dìde kúrò nínú òkú; ẹlẹ́rìí èyí ti àwa jẹ́.
16Nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù, òun ni ó mú ọkùnrin yìí láradá, ẹni tí ẹ̀yin rí, tí ẹ sì mọ̀. Orúkọ Jésù àti ìgbàgbọ́ tí ó wá nípa rẹ̀ ni ó fún un ní ìlera pípé ṣáṣá yìí ni ojú gbogbo yín.
17“Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ará, mo mọ̀ pé nípa àìmọ̀ ni ẹ̀yin fi ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àwọn olórí yín pẹ̀lú ti ṣe.
18Ṣùgbọ́n báyìí ni Ọlọ́run ti se ìmúṣẹ àwọn ohun tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì pé, Kírísítì rẹ̀ yóò jìyà.
19Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,
20àti kí ó baà lè rán Kírísítì tí a ti yàn fún yín tẹlẹ̀: àní Jésù.
21Ẹni tí ọ̀run kò lé ṣàìmá gbà títí di ìgbà ìmúpadà ohun gbogbo, tí Ọlọ́run ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tí wọn ti ń bẹ nígbà tí ayé ti sẹ̀.
22
23
24“Àní, gbogbo àwọn wòlíì láti Sámúẹ́lì wá, àti àwọn tí ó tẹ̀lé e, iye àwọn tí ó ti sọ̀rọ̀, wọn sọ ti ọjọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú.
25
26Nígbà ti Ọlọ́run jí Jésù Ọmọ rẹ̀ dìde, ó kọ́ rán an sí i yín láti bùkún fún un yín, nípa yíyí olúkúlùkù yín padà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀.”