Ìwé Ìṣe àwọn Àpósítélì 6:1-15 BYB2014 - Bible AI

1Ǹjẹ́ ní ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, ìkùn-sínú wà ní àárin àwọn Gíríkì tí se Júù àti àwọn Hébérù tí se Júù, nítorí tí a gbàgbé nípa ti àwọn opó wọn nínú ìpín-fúnni ojoojúmọ́.

2Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọn wí pé, “Kò yẹ kí àwa ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábílì.

3Nítorí náà, ará, ẹ wo ọkùnrin méje nínú yín, olórúkọ rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí-Mímọ́ àti fún ọgbọ́n, tí àwa lè yàn sí iṣẹ́ yìí.

4Ṣùgbọ́n àwa yóò dúró ṣinṣin nínú àdúrà gbígbà, àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”

5Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú gbogbo ìjọ; wọ́n sì yan Sítéfánù, ọkùnrin tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti fún Ẹ̀mí-Mímọ́ àti Fílípì, àti Pírókórù, àti Níkánórù, àti Tímónì, àti Páríménà, àti Níkólásì aláwọ̀se Júù ara Ańtíókù.

6Ẹni tí wọ́n mú dúró níwájú àwọn Àpósítélì; nígbà tí wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn.

7Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì gbilẹ̀, iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pọ̀ sí i gidigidi ni Jerúsálémù, ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà sí fetí sí tí ìgbàgbọ́ náà.

8Sítéfánù tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti agbára, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu, àti iṣẹ́ àmì ńlá láàrin àwọn ènìyàn.

9Ṣùgbọ́n àwọn kan dìde nínú àwọn ti ń se ara sínágógù, tí a ń pè ní Líbátaínì. Àwọn Júù Kírénè àti ti Alekisáńdíríà àti ti Kílíkíà, àti ti Ásíà wá, wọ́n ń bá Sítéfánù jiyàn,

10ṣùgbọ́n wọn kò sí lè ko ọgbọ́n àti Ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀ lójú.

11Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọkùnrin kan ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀, kí wọn ń wí pé, “Àwa gbọ́ tí Sítéfánù ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Mósè àti sí Ọlọ́run.”

12Wọ́n sí ru àwọn ènìyàn sókè, àti àwọn alàgbà, àti àwọn olùkọ́ni ní òfin. Wọ́n dìde sí i, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sí iwájú àjọ ìgbìmọ̀.

13Wọ́n sí mú àwọn ẹlẹ́rìí èké wá, ti wọn wí pé, “Ọkùnrin yìí kò sinmi láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí ibi mímọ́ yìí, àti sí òfin.

14Nítorí àwa gbọ́ o wí pé Jésù ti Násárẹ́tì yìí yóò fọ́ ibí yìí, yóò sì yí àṣà ti Mósè fifún wa padà.”

15Gbogbo àwọn tí ó sì jókò ni àjọ ìgbìmọ̀ tẹjúmọ́ Sítéfánù, wọ́n sì rí ojú rẹ̀ dàbí ojú ańgẹ́lì.

article>