1
2ó bèèrè ìwé lọ́wọ́ rẹ̀ sí sínágọ́gù tí ń bẹ ní ìlú Dámásíkù pé, bí òun bá rí ẹnikẹ́ni tí ń bẹ ni Ọ̀nà yìí, ìbaà ṣe ọkùnrin, tàbí obìnrin, kí òun lè mú wọn ní dídè wá sí Jerúsálémù.
3Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ, ó sì súmọ́ Dámásíkù; lójijì, ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run wá mọlẹ̀ yí i ká.
4Ó sì subú lulẹ̀, ó gbọ́ ohùn tí ó ń fọ̀ sí i pé, “Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù, è é ṣe ti ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?”
5Ó sì wí pé, “Ìwọ ta ni, Olúwa?”
6Ó sì ń wárìrì, ẹnu sì yà á, ó ni Olúwa, kín ní ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe? Olúwa sì wí fún pé, Dìde, kí o sì lọ sí ìlú náà, a ó sì sọ fún ọ nípa ohun tí ìwọ yóò ṣe.”
7Àwọn ọkùnrin tí wọ́n sì ń bá Sọ́ọ̀lù lọ àjò dúró, wọn kò sì le sọ ohun kan, wọn gbọ́ ohùn náà ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹnìkan.
8Ṣọ́ọ̀lù sì dìde ní ilẹ̀; nígbà tí ojú rẹ̀ sì lá kò rí ohunkóhun; ṣùgbọ́n wọ́n fà á lọ́wọ́ wọ́n sì mú un wá sí Dámásíkù.
9Ó sì gbé ọjọ́ mẹ́ta ni àìríran kò sì jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu.
10Ọmọ-ẹ̀yìn kan sì wà ní Dámásíkù, tí a ń pè ni Ananíyà! Olúwa sì wí fún un lójúran pé, “Ananíyà!”
11Olúwa sì wí fún un pé, “Dìde kí ó sì lọ sí ilé Júdà ní Òpópónà Tààrà, kí ó sì bèèrè ẹni tí a ń pè ni Ṣọ́ọ̀lù, ara Tásọ́sì, sá wò ó, ó ń gbàdúrà.
12Òun sì tí ri ọkùnrin kan lójúran ti a ń pè ni Ananíyà o wọlé, ó sì fi ọwọ́ lé e, kí ó lè ríran.”
13Ananíyà sì dáhùn wí pé, “Olúwa mo tí gbúrò ọkùnrin yìí lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn, gbogbo búrukú ti ó ṣe sí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ ni Jerúsálémù.
14Ó sì gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà wá sí ìhínyìí, láti de gbogbo àwọn ti ń pe orúkọ rẹ.”
15Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Má a lọ; nítorí ohun-èlò ààyò ni òun jẹ́ fún mi, láti gbé orúkọ mi lọ sí iwájú àwọn aláìkọlà, àti àwọn ọba, àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
16Nítorí èmi o fi gbogbo ìyà ti kò le ṣàìjẹ nítorí orúkọ mi hàn án.”
17Ananíyà sì lọ, ó sì wọ ilé náà, nígbà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù, ó sì wí pé, “Arákùnrin Sọ́ọ̀lù, Olúwa ni ó rán mi, Jésù tí ó fi ara hàn ọ lọ́nà tí ìwọ bá wá, kí ìwọ baà lè rìran, kí ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.”
18Lójúkan náà nǹkan kan ti ó dàbí ìpẹ́ sì bọ kúrò lójú rẹ̀, ó sì ríran; ó sì dìde, a sì bamitíìsì rẹ̀.
19Nígbà tí ó sì jẹun, ara rẹ̀ mókun.
20Lójúkan náà ó sì ń wàásù Kírísítì nínú àwọn sínágógù pé, “Ọmọ Ọlọ́run ní í ṣe.”
21Ẹnu sì yà gbogbo àwọn ti ó ń gbọ́, wọn sì wí pé, “Èyí ha kọ ẹni ti ó ti fòórò àwọn ti ń pe orúkọ yìí ni Jerúsálémù? Nítorí èyí náà ni ó sa ṣe wá sí ìhìnyìí, láti mú wọn ní dìde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.”
22Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ń pọ̀ sí i ní agbára ó sì ń dààmú àwọn Júù tí ó ń gbé Dámásíkù, ó fi hàn pé, èyí ni Kírísítì náà.
23Lẹ́yìn ìgbà tí ọjọ́ púpọ̀ kọjá, àwọn Júù ń gbìmọ̀ láti pa á
24
25Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé ní òru, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lára odi nínú agbọ̀n.
26Nígbà ti Ṣọ́ọ̀lù sì de Jerúsálémù ó pète láti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn; gbogbo wọn sì bẹ̀rù rẹ̀, nítorí wọn kò gbàgbọ́ pé ọmọ-ẹ̀yìn kan ni.
27Ṣùgbọ́n Bánábà mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ àwọn àpósítélì, ó sì sọ fún wọn bí ó ti rí Olúwa ní ọ̀nà, àti bí ó ti fi ìgboyà wàásù ní Dámásíkù ní orúkọ Jésù.
28Ó sì pẹ̀lú wọn, ó ń wọlé, ó sì ń jáde ní Jerúsálémù.
29Ó sì ń fi ìgboyà wàásù ni orúkọ Jésù Olúwa, ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Hélénì, ó sì ń jà wọ́n níyàn; ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a.
30Nígbà tí àwọn arákùnrin sì mọ̀, wọ́n mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kesaríà, wọ́n sì rán an lọ sí Tásísì.
31Nígbà náà ni ìjọ wà ni àlàáfíà yíká gbogbo Jùdíà àti ni Gálílì àti ni Samaríà, wọn ń fẹsẹ̀múlẹ̀, wọn ń rìn ní ìbẹ̀rù Olúwa, àti ni ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ń pọ̀ sí i
32Ó sì ṣe, bí Pétérù ti ń kọjá lọ káàkiri láàrin wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú si ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ ti ń gbé ni Lídà.
33Níbẹ̀ ni ó rí ọkùnrin kan ti a pè ní Áénéà tí ó ti dùbúlẹ̀ lórí àkéte ni ọdún mẹ́jọ, ó ní àrùn ẹ̀gbà.
34Pétérù sì wí fún un pé, “Áénéà, Jésù Kírísítì mú ọ láradá; dìde kí ó sì tún àkéte rẹ ṣe.” Ó sì dìde lójúkan náà.
35Gbogbo àwọn tí ń gbé Lídà àti Sárónì sì rí i, wọn sì yípadà sí Olúwa.
36Ọmọ-ẹyìn kan sí wà ní Jópà ti a ń pè ni Tàbítà, èyí tí ó túmọ̀ sí Dọ́kásì; obìnrin yìí pọ̀ ni iṣẹ́ oore, àti ìtọrẹ-àánú ṣíṣe.
37Ní àkókò náà ni ó wà nínú àìsàn, ó sì kú, wọ́n sì wẹ òkú rẹ̀, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sí iyàrá òké.
38Bí Lídà sì ti súnmọ́ Jópà, nígbà tí àwọn ọmọ-ẹyìn gbọ́ pé Pétérù wà níbẹ̀, wọ́n rán ọkùnrin méjì sí i láti bẹ̀ ẹ́ pé, “Má ṣe jáfara láti dé lọ́dọ̀ wa.”
39Pétérù sí dìde, ó sì bá wọn lọ. Nígbà tí ó dé, wọ́n mú un lọ sí ìyará òkè náà: gbogbo àwọn opó sí dúró tì í wọn sọkún, wọ́n sì ń fi ẹ̀wù àti aṣọ tí Dọ́kásì dá hàn án, nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn.
40Ṣùgbọ́n Pétérù ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà; ó sì yípadà sí òkú, ó ní “Tàbítà, dìde.” Ó sì la ojú rẹ̀: nígbà tí ó sì rí Pétérù, ó dìde jókòó.
41Ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí i, ó fà á dìde; nígbà tí ó sì pe àwọn ènìyàn mímọ́ àti àwọn opó, ó fi i lé wọn lọ́wọ́ láàyè.
42Èyí sì di mímọ̀ já gbogbo Jópà; ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gba Olúwa gbọ́.
43Ó gbé ọjọ́ púpọ̀ ni Jópà ní ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan Símónì oníṣọ̀nà-awọ.