1
2Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí aríwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá: mo sì gbọ́ àwọn oníháàpù, ń lù haàpù wọn.
3Wọ́n sì ń kọ bí ẹni pé orin túntún níwájú ìtẹ́ náà, àti àwọn àgbà náà: kò sì sí ẹni tí o lè kọ orin náà, bí kò ṣe àwọn òkè méje o lé ẹgbàájì ènìyàn, tí a tí rà padà láti inú ayé wá.
4Àwọn wọ̀nyí ni a kò fi obìnrin sọ di èérì: nítorí tí wọ́n jẹ́ wúndíá. Àwọn wọ̀nyí ni o ń tọ Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà lẹ́yìn níbikíbi tí o bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a ràpadà láti inú àwọn ènìyàn wá, wọ́n jẹ́ àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ̀-Àgùntàn náà.
5A kò sì rí èké lẹ́nu wọn, wọn jẹ́ aláìlábùkù.
6Mo sì rí ańgẹ́lì mìíràn ń fò ní àárin méjì ọ̀run, pẹ̀lú Ìyìn rere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn.
7Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ogo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbàlẹ́ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti òkun, àti àwọn orísun omi!”
8
9Ańgẹ́lì mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ń fóríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba àmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀.
10
11
12Nihìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jésù mọ́.
13Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.”
14
15
16Ẹni tí ó jókòó lórí ìkúùkùu àwọsánmà náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ orí ilẹ̀ ayé; a sì ṣe ìkórè ilẹ̀ ayé.
17Ańgẹ́lì mìíràn sì tí inú tẹmpílì tí ń bẹ ni ọ̀run jáde wá, òun pẹ̀lú sì ní dòjé mímú, kan.
18Ańgẹ́lì mìíràn sì tí ibi pẹpẹ jáde wá, tí ó ní agbára lórí iná; ó sì ké ni ohùn rara sí ẹni tí o ni dòjé mímú náà, wí pé, “Tẹ dòjé rẹ mímú bọ̀ ọ́, ki ó sì rẹ̀ àwọn ìdí àjàrà ayé, nítorí àwọn èso rẹ̀ tí pọ́n.”
19Ańgẹ́lì náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ ilẹ́ ayé, ó sì gé àjàrà ilẹ́-ayé, ó sì kó o lọ sínú ìfúntì, ìfúntí ńlá ìbínú Ọlọ́run.
20