1
2Mo sì rí bí ẹni pé, òkun dígí tí o dàpọ̀ pẹ̀lú iná: àwọn tí ó sì dúró lórí òkun dígí yìí jẹ́ àwọn ti wọ́n sẹ́gun ẹranko náà, àti àwòrán rẹ̀, àti àmì rẹ̀ àti nọ́ḿba orúkọ rẹ̀, wọn ní Haàpù Ọlọ́run.
3
4
5
6Àwọn ańgẹ́lì méje náà sì ti inú tẹ́ḿpìlì jáde wá, wọ́n ni ìyọnu méje náà, a wọ̀ wọ́n ní aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun ti ń dán, a sì fi àmùrè wúrà dì wọ́n ni oókan àyà.
7Àti ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fi àgbàda wúrà méje fún àwọn ańgẹ́lì méje náà, tí ó kún fún ìbínú Ọlọ́run, ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láéláé.
8Tẹ́ḿpìlì náà sì kún fún èéfín láti inú ògo Ọlọ́run àti agbára rẹ̀ wá; ẹnikẹ́ni kò sì lè wọ inú tẹ́ḿpìlì náà lọ títí a fi mú ìyọnu méjèèje àwọn ańgẹ́lì méje náà ṣẹ.