1
2
3Ó sì gbé mi nínú ẹ̀mí lọ sí ihà: mo sì rí obìnrin kan ó jòkòó lórí ẹranko aláwọ̀ òdòdó kan tí ó kún fún orúkọ ọ̀rọ̀ òdì, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá.
4
5Àti níwájú rẹ̀ ni orúkọ kan tí a kọ:
6Mo sì rí obìnrin náà mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ajẹ́rìí ikú Jésù ní àmuyó.
7Ańgẹ́lì sì wí fún mi pé, “Nítorí kí ni ẹnu ṣe yà ọ́? Èmi ó sọ ti ìjìnlẹ̀ obìnrin náà fún ọ, àti ti ẹranko tí ó gùn, ti ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá.
8
9“Níhìn-ín ni ìtumọ̀ tí o ní ọgbọ́n wà. Orí méje ni òkè ńlá méje ni, lórí èyí tí obìnrin náà jókòó.
10Ọba méje sì ní wọn: àwọn márùn-ún ṣubú, ọ̀kan ń bẹ, ọ̀kan ìyókù kò sì tí ì dé; nígbà tí ó bá sì dé, yóò dúró fún ìgbà kúkurú.
11Ẹranko tí ó sì ti wà, tí kò sì sí, òun náà sì ni ìkẹjọ, ó sì ti inú àwọn méje náà wá, ó sì lọ sí ìparun.
12
13Àwọn wọ̀nyí ní inú kan, wọ́n ò sì fi agbára àti ọlá wọn fún ẹranko náà.
14
15Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn omi tí ìwọ ti rí ni, níbi tí àgbèrè náà jókòó, àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà àti orílẹ̀ àti oníruru èdè ni wọ́n.
16Àti ìwo mẹ́wàá tí ìwọ rí, àti ẹranko náà, àwọn wọ̀nyí ni yóò koríra àgbèrè náà, wọn ó sì sọ ọ́ di ahoro àti ẹni ìhòòhò, wọn ó sì jẹ ẹran ara rẹ̀, wọn ó sì fi iná sun ún pátapáta.
17Nítorí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn wọn láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, láti ní inú kan, àti láti fi ìjọba wọn fún ẹranko náà, títí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi ṣẹ
18Obìnrin tí ìwọ rí ní ìlú ńlá ni, tí ń jọba lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.”