1“Sí Ańgẹ́lì Ní Éfésù kọ̀wé:
2Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti làálàá rẹ, àti ìfaradà rẹ, àti bí ara rẹ kò ti gba àwọn ẹni búburú: àti bí ìwọ sì ti dán àwọn tí ń pe ara wọn ní àpósítélì, tí wọ́n kì í sì í se bẹ́ẹ̀ wo, tí ìwọ sì rí pé èké ni wọ́n;
3Tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọjú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ.
4Ṣíbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹsílẹ̀.
5Rántí ibi tí ìwọ ti gbé subú! Ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe iṣẹ́ ìsáájú; bí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó sì tọ̀ ọ́ wá, èmi ó sì sí ọ̀pá fìtílà rẹ̀ kúrò ní ipò rẹ̀, bí kò ṣe bí ìwọ bá ronúpìwàdà.
6Ṣùgbọ́n èyí ni ìwọ ní, pé ìwọ kórìíra ìṣe àwọn Nikoláétánì, èyí tí èmi pẹ̀lú sì kórìíra.
7
8
9Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́ èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé Júù ni àwọn tìkárawọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ sínágọ́gù ti Sátánì.
10
11Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá sẹ́gun kì yóò farapa nínú ikú kejì.
12“Àti sì Ańgẹ́lì ìjọ ni Págámọ́sì Kọ̀wé:
13Èmí mọ̀ ibi tí ìwọ ń gbé, àní ibi tí ìtẹ́ Sàtánì wà. Síbẹ̀ ìwọ di orúkọ mi mú ṣinṣin. Ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ nínú mi, pàápàá jùlọ ni ọjọ́ Áńtípà ẹlẹ́rì mi, olóòótọ́ ènìyàn, ẹni tí wọn pa láàrin yín, níbi tí Sàtánì ń gbé.
14
15Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ní àwọn tí ó gbá ẹ̀kọ́ àwọn Nikoláétanì pẹ̀lú, ohun tí mo kórìíra.
16Nítorí náàonúpìwàdà; bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó tọ̀ ọ́ wá nísinsinyìí, èmí o sì fi idà ẹnu mi bá wọn jà.
17
18
19Èmi mọ̀ iṣẹ́, ìfẹ́, àti ìgbàgbọ́ àti ìsìn àti sùúrù rẹ̀; àti pé iṣẹ́ rẹ̀ ìkẹyìn ju tí iṣàájú lọ.
20
21Èmi fi àkókò fún un, láti ronúpìwàdà; ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ ronúpìwàdà àgbèrè rẹ̀.
22Nítorí náà, èmi ó gbé e sọ sí orí àkéte, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà ni èmi ó fi sínú ìpọ́njú ńlá, bí kò ṣe bí wọ́n bá ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn.
23
24Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni mò ń sọ fún, ẹ̀yin ìyókù tí ń bẹ ní Tíátírà, gbogbo ẹ̀yin tí kò ni ẹ̀kọ́ yìí, ti kò ì tí ì mọ̀ ohun tí wọn pe ni ohun ìjìnlẹ̀ Sàtánì, èmi kò di ẹrù mìíràn rù yín:
25Ṣùgbọ́n èyí tí ẹ̀yin ní, ẹ di i mú ṣinṣin títí èmi ó fi dé.
26
27
28Èmi yóò sì fi ìràwọ̀ òwúrọ̀ fún un.
29Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.