1“Àti sí Ańgẹ́lì ìjọ ni Sádísì kọ̀wé:
2Jí, kí o sì fi ẹsẹ̀ ohun tí ó kù múlẹ̀, tí ó ṣetán láti kú: Nítorí èmi kò rí iṣẹ́ rẹ ni pípé níwájú Ọlọ́run.
3Nítorí náà rántí bí ìwọ ti gbà, àti bí ìwọ ti gbọ́, kí o sì pa á mọ́, kí o sì ronúpìwàdà. Ǹjẹ́, bí ìwọ kò ba ṣọ́ra, èmi yóò dé sí ọ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ́ wákàtí tí èmi yóò dé sí ọ.
4Ìwọ ní orúkọ díẹ̀ ní Sádísì, tí kò fi aṣọ wọn yí èérí; wọn yóò sì máa ba mi rìn ní aṣọ funfun: nítorí wọ́n yẹ.
5
6Ẹni tí ó ba létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń ṣọ fún àwọn ìjọ.
7
8Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀: kíyèsí i, mo gbe ilẹ̀kùn tí ó ṣí kálẹ̀ níwájú rẹ̀, tí kò sí ẹni tí o lè tì í; pé ìwọ ni agbára díẹ̀, ìwọ sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, ìwọ kò sì sẹ́ orúkọ mi.
9
10Nítorí tí ìwọ tí pa ọ̀rọ̀ sùúrù mi mọ́, èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, tí ń bọ̀ wá dé bá gbogbo ayé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò.
11Kíyèsí i, èmi ń bọ̀ kánkán: di èyí ti ìwọ ní mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gba adé rẹ.
12
13Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun ti Ẹmi ń sọ fún àwọn ìjọ.
14
15Èmi mọ̀ iṣẹ́ rẹ, pé ìwọ kò gbóná bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò tútù: èmi ìbá fẹ́ pé kí ìwọ kúkú tutù, tàbí kí ìwọ kúkú gbóná.
16Ǹjẹ nítorí tí ìwọ lọ wọ́ọ́rọ́, tí o kò si gbóná, bẹ́ẹ̀ ni tí o kò tutù, èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ni ẹnu mi.
17
18Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀; àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran.
19
20Kíyèsí i, èmi dúró ni ẹnu ilẹ̀kùn, èmi sì ń kànkùn, bí ẹnikẹ́ni bá gbọ ohun mi, tí ó sì ṣí ilẹ̀kùn, èmi yóò sì wọlé tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bá a jẹun, àti òun pẹ̀lú mi.
21Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi fún láti jókòó pẹ̀lu mi lórí ìtẹ́ mi, bí èmi pẹ̀lú ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀.
22Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń ṣọ fún àwọn Ìjọ.”