1Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kéje, ìdákẹ́ rọ́rọ́ sì wà ní ọ̀run níwọ́n ààbọ̀ wákàtí kan.
2Mo sì rí àwọn ańgẹ́lì méje tí wọn dúró níwájú Ọlọ́run; a sì fi ìpè méje fún wọn.
3
4Àti èéfín tùràrí náà pẹ̀lú àdúrà àwọn ènìyàn-mímọ́ sì gòkè lọ ṣíwájú Ọlọ́run láti ọwọ́ ańgẹ́lì náà wá.
5
6Àwọn ańgẹ́lì méje náà tí wọn ni ìpè méje sì múra láti fún wọn.
7
8
9Àti ìdámẹ̀ta àwọn ẹ̀dá tí ń bẹ nínú òkun tí ó ni ẹ̀mí sì kú; àti ìdámẹ̀ta àwọn ọkọ̀ si bàjẹ́.
10
11A sì ń pe orúkọ ìràwọ̀ náà ni ìwọ̀, ìdámẹ̀ta àwọn omi sì di ìwọ̀, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn sì tí ipa àwọn omi náà kú, nítorí tí a sọ wọn di kíkorò.
12Ańgẹ́lì kẹ́rin sì fún ìpè tirẹ̀, a sì kọlu ìdámẹ̀ta òòrùn, àti ìdámẹ̀ta òṣùpá, àti ìdámẹ̀ta àwọn ìràwọ̀, ki ìdámẹ̀ta wọn lè ṣóòkùn, kí ọjọ́ má ṣe mọ́lẹ̀ fún ìdámẹ̀ta rẹ̀, àti òru báka náà.
13Mo sì wò, mo sì gbọ́ idí kan tí ń fò ni àárin ọ̀run, ó ń wí lóhùn rara pé, “Ègbé, ègbé, fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé nítorí ohun ìpè ìyókù tí àwọn ańgẹ́lì mẹ́ta tí ń bọ̀ wá yóò fún!”