Ìwé Ìyìnrere Jòhánù 10:1-42 BYB2014 - Bible AI

1“Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí kò bá gba ẹnu ọ̀nà wọ inú agbo àgùntàn, ṣùgbọ́n tí ó bá gba ibòmíràn gun òkè, Òun náà ni olè àti ọlọ́sà.

2ⓐ Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ti ẹnu-ọ̀nà wọlé, Òun ni olùṣọ́ àwọn àgùntàn.

3Òun ni osọ́nà yóò ṣílẹ̀kùn fún; àwọn àgùntàn gbọ́ ohùn rẹ̀: ó sì pe àwọn àgùntàn tirẹ̀ lórúkọ, ó sì se amọ̀nà wọn jáde.

4Nígbà tí ó bá sì ti mú àwọn àgùntàn tirẹ̀ jáde, yóò ṣíwájú wọn, àwọn àgùntàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn: nítorí tí wọ́n mọ ohùn rẹ̀.

5Wọn kò jẹ́ tọ àlejò lẹ́yìn, ṣùgbọ́n wọn a sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀: nítorí tí wọn kò mọ ohùn àlejò.”

6ⓑ Òwe yìí ni Jésù pa fún wọn: ṣùgbọ́n òye ohun tí nǹkan wọ̀nyí jẹ́ tí ó ń sọ fún wọn kò yé wọn.

7Nítorí náà Jésù tún wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn àgùntàn.

8ⓒ Olè àti ọlọ́sà ni gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú mi: ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò gbọ́ ti wọn.

9Èmi ni ìlẹ̀kùn: bí ẹnìkan bá bá ọ̀dọ̀ mi wọlé, Òun ni a ó gbà là, yóò wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí koríko.

10Olè kì í wá bí kò ṣe láti jalè, láti pa, àti láti parun: èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọpọ̀.

11ⓓ “Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn rere: olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.

12Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́ àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkokò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri.

13Òun sá lọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn.

14“Èmi ni olùsọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí.

15ⓔ Gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba; mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.

16ⓕ Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe agbo yìí: àwọn ni èmi yóò mú wá pẹ̀lú, wọn ó sì gbọ́ ohùn mi; wọn ó sì jẹ́ agbo kan, olùsọ́-àgùntàn kan.

17Nítorí náà ni Baba mi ṣe fẹ́ràn mi, nítorí tí mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, kí èmi lè tún gbà á.

18ⓖ Ẹnìkan kò gbà á lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n mo fi í lélẹ̀, mo sì lágbára láti tún gbà á. Àṣẹ yìí ni mo ti gbà wá láti ọ̀dọ̀ Baba mi.”

19ⓗ Nítorí náà ìyapa tún wà láàrin àwọn Júù nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.

20ⓘ Ọ̀pọ̀ nínú wọn sì wí pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ sì dàrú; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń gbọ́rọ̀ rẹ̀?”

21ⓙ Àwọn mìíràn wí pé, “Ìwọ̀nyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀mi èṣù lè la ojú àwọn afọ́jú bí?”

22Ó sì jẹ́ àjọ̀dún ìyàsímímọ́ ní Jérúsálẹ́mù, ìgbà òtútù ni.

23ⓚ Jésù sì ń rìn ní tẹ́mpílì, ní ìloro Sólómónì,

24Nítorí náà àwọn Júù wá dúró yí i ká, wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ó ti mú wa ṣe iyèméjì pẹ́ tó? Bí ìwọ bá ni Kírísítì náà, wí fún wa gbangba.”

25ⓛ Jésù dá wọn lóhùn pé, “Èmi ti wí fún yín, ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́; iṣẹ́ tí èmi ń ṣe lórúkọ Baba mi, àwọn ni ó ń jẹ́rìí mi.

26ⓜ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbàgbọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí nínú àwọn àgùntàn mi, gẹ́gẹ́ bí mo tí wí fún yín.

27Àwọn àgùntàn mi ń gbọ́ ohùn mi, èmi sì mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn:

28ⓝ Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun; wọn kì yóò sì ṣègbé láéláé, kò sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi.

29Baba mi, ẹni tí ó fi wọ́n fún mi pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò sì sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba mi.

30ⓞ Ọ̀kan ni èmi àti Baba mi.”

31ⓟ Àwọn Júù sì tún he òkúta, láti sọ lù ú.

32Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fi hàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá; nítorí èwo nínú iṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀yin ṣe sọ mí ní òkúta?”

33ⓠ Àwọn Júù sì dá a lóhùn pé, “Àwa kò sọ ọ́ lókúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀-ọ̀dì: àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ ṣe Ọlọ́run.”

34ⓡ Jésù dá wọn lóhùn pé, “A kò ha tí kọ ọ́ nínú òfin yín pé, ‘Mo ti wí pé, Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́’?

35Bí ó bá pè wọ́n ní Ọlọ́run, àwọn ẹni tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, a kò sì lè ba ìwé-mímọ́ jẹ́,

36Ẹ̀yin ha ń wí ní ti ẹni tí Baba yà sí mímọ́, tí ó sì rán sí ayé pé: Ìwọ ń sọ̀rọ̀ òdì, nítorí tí mo wí pé, ‘Ọmọ Ọlọ́run ni mí.’

37Bí èmi kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́.

38Ṣùgbọ́n bí èmi bá ṣe wọ́n, bí ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gbà iṣẹ́ náà gbọ́: kí ẹ̀yin baà lè mọ̀, kí ó sì lè yé yín pé, Baba wà nínú mi, èmi sì wà nínú rẹ̀.”

39ⓢ Wọ́n sì tún ń wá ọ̀nà láti mú un: ó sì bọ́ lọ́wọ́ wọn.

40ⓣ Ó sì tún kọjá lọ sí apá kéjì Jodánì sí ibi tí Jòhánù ti kọ́kọ́ ń bamítísì; níbẹ̀ ni ó sì jókòó.

41Àwọn ènìyàn púpọ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Jòhánù kò ṣe iṣẹ́ àmì kan: Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni ohun gbogbo tí Jòhánù sọ nípa ti ọkùnrin yìí.”

42ⓤ Àwọn ènìyàn púpọ̀ níbẹ̀ sì gbàágbọ́.

ticle>