1
2Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù tìkararẹ̀ kò ṣe ìtẹ̀bọmibí kò ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀,
3Nígbà tí Olúwa mọ nípa èyí, Ó fi Jùdéà sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Gálílì lẹ́ẹ̀kan si.
4
5
6Kànga Jákọ́bù sì wà níbẹ̀. Nítorí pé ó rẹ Jésù nítorí ìrìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó jòkó létí kànga: ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́.
7Obìrin kan, ará Samaríà sì wá láti fà omi: Jésù wí fún un pé fún mi mu.
8(Nítorí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ sí ìlú láti lọ ra ońjẹ.)
9
10
11Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, ìwọ kò ní nǹkan tí ìwọ ó fi fà omi, bẹ́ẹ̀ ni kànga náà jìn: Níbo ni ìwọ ó ti rí omi ìyè náà?
12Ìwọ pọ̀ ju Jákọ́bù baba wa lọ bí, ẹni tí ó fún wa ní kànga náà, tí Òun tìkararẹ̀ mu nínú rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ẹran rẹ̀?”
13Jésù dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi yìí, òrùngbẹ yóò tún gbẹ ẹ́:
14
15
16Jésù wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.”
17Òbìnrin náà dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Èmi kò ní ọkọ. Jésù wí fún un pé, Ìwọ́ dáhùn dáradára pé, èmi kò ní ọkọ:
18
19Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé, wòlíì ni ìwọ ń ṣe.
20
21
22
23Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsìn yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun.
24
25Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, “Mèsáyà ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Krísítì: Nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa.”
26
27Lórí èyí ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ẹnu sì yà wọ́n pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kan tí ó wí pé, “Kíni ìwọ ń wá?” tàbí “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá a sọ̀rọ̀?”
28Nígbà náà ni obìnrin náà fi ládugbó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí ìlú, ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé,
29
30Nígbà náà ni wọ́n ti ìlú jáde, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá.
31Láàárin èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ wí pé, “Olùkọ́, jẹun.”
32
33Nítorí náà ni àwọn ọmọ-èyìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, “Ẹnì kan mú ońjẹ fún un wá láti jẹ bí?”
34
35
36Kódà báyìí, ẹni tí ó ń kórè ń gba owó ọ̀yà rẹ̀, kódà báyìí, ó ń kórè fún ayérayé: kí ẹni tí ó ń fúrúgìn àti ẹni tí ń kórè lè jọ máa yọ̀ pọ̀.
37
38Mo rán yín lọ kórè ohun tí ẹ kò ṣiṣẹ́ fún. Àwọn ẹlòmíràn ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin sì kórè èrè làálàá wọn.”
39Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samáríà láti ìlú náà wá sì gbà á gbọ́ nítorí ìjẹ́rìí obìnrin náà pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi.”
40Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samáríà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé, kí ó wà pẹ̀lú wọn: ó sì dúró fún ijọ́ méjì.
41Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ sí i nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
42
43Lẹ́yìn ijọ́ méjì ó sì ti ibẹ̀ kúrò, ó lọ sí Gálílì.
44
45Nítorí náà nígbà tí ó dé Gálílì, àwọn ará Gálílì gbà á, nítorí ti wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ṣe ní Jérúsálẹ́mù nígbà àjọ; nítorí àwọn tìkára wọn lọ sí àjọ pẹ̀lú.
46
47Nígbà tí ó gbọ́ pé Jésù ti Jùdéà wá sí Gálílì, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá: nítorí tí ó wà ní ojú ikú.
48
49Ọkùnrin ọlọ́lá náà wí fún un pé, “Olúwa, sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ mi tó kú.”
50Jésù wí fún un pé, “Má a bá ọ̀nà rẹ lọ; ọmọ rẹ yóò yè.”
51Bí ó sì ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pàde rẹ̀, wọ́n sì wí fún un pé, ọmọ rẹ ti yè.
52Nígbà náà ni ó béèrè wákàtí tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ní àná, ní wákàtí kéje ni ibà náà fi í sílẹ̀.”
53
54