Ìwé Ìyìnrere Jòhánù 6:1-71 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù kọjá sí apákejì òkun Gálílì, tí í ṣe òkun Tiberíà.

2Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n rí iṣẹ́ àmì rẹ̀ tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn.

3Jésù sì gun orí òkè lọ, níbẹ̀ ni ó sì gbé jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀.

4Àjọ ìrékọjá ọdún àwọn Júù sì sún mọ́ etílé.

5ⓑ Ǹjẹ́ bí Jésù ti gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí fún Fílípì pé, “Níbo ni a ó ti ra àkàrà, kí àwọn wọ̀nyí lè jẹ?”

6Ó sì sọ èyí láti dán an wò; nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ohun tí òun ó ṣe.

7Fílípì dá a lóhùn pé, “Àkàrà igba owó idẹ kò lè tó fún wọn, bí olúkúlùkù wọn kò tilẹ̀ níí rí ju díẹ̀ bù jẹ.”

8ⓒ Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ańdérù, arákùnrin Símónì Pétérù wí fún un pé,

9ⓓ “Ọmọdékùnrin kan ńbẹ níhínyìí, tí ó ní ìṣù àkàrà barle márùnún àti ẹja kékèké méjì: ṣùgbọ́n kín ni ìwọ̀nyí jẹ́ láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí?”

10Jésù sì wí pé, “Ẹ mú kí àwọn ènìyàn náà jókòó!” Kóríkó púpọ̀ sì wá níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin náà jókòó; ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní iye.

11Jésù sì mú ìṣù àkàrà náà. Nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì pín wọn fún àwọn tí ó jókòó; bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni ẹja ní ìwọn bí wọ́n ti ń fẹ́.

12Nígbà tí wọ́n sì yó, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó àjẹkù tí ó kù jọ, kí ohunkóhun má ṣe ṣòfò.”

13Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó wọn jọ wọ́n sì fi àjẹkù ìṣù àkàrà barle márùn-ún náà kún agbọ̀n méjìlá, èyí tí àwọn tí ó jẹun jẹ kù.

14ⓔ Nítorí náà nígbà tí àwọn ọkùnrin náà rí iṣẹ́-àmì tí Jésù ṣe, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà tí ń bọ̀ wá sí ayé.”

15ⓕ Nígbà tí Jésù sì wòye pé wọ́n ń fẹ́ wá fi agbára mú òun láti lọ fi jọba, ó tún padà lọ sórí òkè, òun nìkan.

16ⓖ Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí òkun.

17Wọ́n sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì rékọjá òkun lọ sí Kápénámù. Ilẹ̀ sì ti ṣú, Jésù kò sì tí ì dé ọ̀dọ̀ wọn.

18Òkun sì ń ru nítorí ẹ̀fúfù líle tí ńfẹ́.

19Nígbà tí wọ́n wa ọkọ̀ ojú omi tó bí ìwọ̀n ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n, wọ́n rí Jésù ń rìn lórí òkun, ó sì súnmọ́ ọkọ̀ ojú omi náà; ẹ̀rù sì bà wọ́n.

20Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.”

21Nítorí náà wọ́n fi ayọ̀ gbà á sínú ọkọ̀; lójúkannáà ọkọ̀ náà sì dé ilẹ̀ ibi tí wọ́n gbé ń lọ.

22Ní ijọ́ kéjì nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó dúró ní apákejì òkun ríi pé, kò sí ọkọ̀ ojú omi mìíràn níbẹ̀, bí kò ṣe ọ̀kan náà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ̀, àti pé Jésù kò bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ inú ọkọ̀ ojú omi náà, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ni ó lọ.

23Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ̀ ojú omi mìíràn ti Tiberíà wá, létí ibi tí wọn gbé jẹ àkàrà, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti dúpẹ́;

24Nítorí náà nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Jésù tàbí ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò sí níbẹ̀, àwọn pẹ̀lú wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kápánámù, wọ́n ń wá Jésù.

25Nígbà tí wọ́n sì rí i ní apákejì òkun, wọ́n wí fún un pé, “Rábì, nígbà wo ni ìwọ wá síhín yìí?”

26Jésù dá wọn lóhùn ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín. Ẹ̀yin ń wá mi, kì í ṣe nítorí tí ẹ̀yin rí iṣẹ́-àmì, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀yin jẹ àjẹyó ìṣù àkàrà.

27ⓗ Ẹ má ṣe ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ńṣègbé, ṣùgbọ́n fún oúnjẹ tí ó wà títí di ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí ọmọ-ènìyàn yóò fi fún yín: nítorí pé òun ni, àní Ọlọ́run Baba ti fi èdìdì dì í.”

28Nígbà náà ni wọ́n wí fún wọn pé, “Kín ni àwa ó ha ṣe, kí a lè ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run?”

29ⓘ Jésù dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni iṣe Ọlọ́run pé, kí ẹ̀yin gba ẹni tí ó rán an gbọ́.”

30ⓙ Nígbà náà ni wọ́n wí fún wọn pé, “Iṣẹ́ àmì kín ní ìwọ ń ṣe, tí àwa lè rí, kí a sì gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ kínni ìwọ ṣe?

31ⓚ Àwọn baba wa jẹ mánà ní ihà; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ó fi oúnjẹ láti ọ̀run wá oúnjẹ fún wọn jẹ.’ ”

32Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kì í ṣe Mósè ni ó fi oúnjẹ fún yín láti ọ̀run wá; ṣùgbọ́n Baba mi ni ó fi oúnjẹ òtítọ́ náà fún yín láti ọ̀run wá.

33Nítorí pé oúnjẹ Ọlọ́run ni èyí tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ó sì fi ìyè fún aráyé.”

34ⓛ Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Olúwa, máa fún wa ní oúnjẹ yìí títí láé.”

35ⓜ Jésù wí fún wọn pé, “Èmi ni oúnjẹ ìyè: ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí wá, ebi kì yóò pa á; ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òrùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé.

36Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Ẹ̀yin ti rí mi, ẹ kò sì gbàgbọ́.

37ⓝ Gbogbo èyí tí Baba fi fún mi, yóò tọ̀ mí wá; ẹni tí ó bá sì tọ̀ mí wá, èmi kì yóò tà á nù, bí ó tí wù kó rí.

38ⓞ Nítorí èmi sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti má a ṣe ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.

39ⓟ Èyí sì ni ìfẹ́ Baba tí ó rán mi pé ohun gbogbo tí o fi fún mi, kí èmi má ṣe sọ ọ̀kan nù nínú wọn, ṣùgbọ́n kí èmi lè jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.

40ⓠ Èyí sì ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo ọmọ, tí ó bá sì gbà á gbọ́, kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun: Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.”

41Nígbà náà ni àwọn Júù ń kùn sí i, nítorí tí ó wí pé, “Èmi ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá.”

42ⓡ Wọ́n sì wí pé, “Jésù ha kọ́ èyí, ọmọ Jósẹ́fù, baba àti ìyá ẹni tí àwa mọ̀? Báwo ni ó ṣe wí pé, ‘Èmi ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá’?”

43Nítorí náà Jésù dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe kùn láàárin yín!

44ⓢ Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, bí kò ṣe pé Baba tí ó rán mi fà á: Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.

45ⓣ A sáà ti kọ ọ́ nínú àwọn wòlíì pé, ‘A ó sì kọ́ gbogbo wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá,’ nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́, tí a sì ti ọ̀dọ̀ Baba kọ́, òun ni ó ń tọ̀ mí wá.

46ⓤ Kì í ṣe pé ẹnìkan ti rí Baba bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, òun ni ó ti rí Baba.

47Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun.

48Èmi ni oúnjẹ ìyè.

49Àwọn baba yín jẹ mánà ní ihà, wọ́n sì kú.

50Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, kí ènìyàn lè máa jẹ nínú rẹ̀ kí ó má sì kú.

51Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá: bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé: oúnjẹ náà tí èmi ó sì fifúnni fún ìyè aráyé ni ara mi.”

52ⓥ Nítorí náà ni àwọn Júù ṣe ń bá ara wọn jiyàn, pé, “Ọkùnrin yìí yóò ti ṣe lè fi ara rẹ̀ fún wa láti jẹ?”

53Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá jẹ ara ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀yin kò ní ìyè nínú yin.

54Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun; Èmi o sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.

55Nítorí ara mi ni ohun jíjẹ nítòótọ́, àti ẹ̀jẹ̀ mi ni ohun-mímu ní tòótọ́.

56ⓦ Ẹni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ń gbé inú mi, èmi sì ń gbé inú rẹ̀.

57Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, tí èmi sì yè nípa Baba gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó jẹ mí, òun pẹ̀lú yóò yè nípa mi.

58ⓧ Èyí sì ni oúnjẹ náà tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá: kì í ṣe bí àwọn baba yín ti jẹ mánà, tí wọ́n sì kú: ẹni tí ó bá jẹ́ oúnjẹ yìí yóò yè láéláé.”

59ⓨ Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ nínú sínágọ́gù, bí ó ti ń kọ́ni ní Kápánámù.

60Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Ọ̀rọ̀ tí ó le ni èyí; ta ní lè gbọ́ ọ?”

61ⓩ Nígbà tí Jésù sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn sí ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún wọn pé, “Èyí jẹ́ ìkọ̀sẹ̀ fún yín bí?

62ⓐ Ǹjẹ́, bí ẹ̀yin bá sì rí i tí ọmọ ènìyàn ń gòkè lọ síbi tí ó gbé ti wà rí ń kọ́?

63ⓑ Ẹ̀mi ní ń sọni di ààyè; ara kò ní èrè kan; ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo sọ fún yín, ẹ̀mí ni, ìyè sì ni.

64ⓒ Ṣùgbọ́n àwọn kan wà nínú yín tí kò gbàgbọ́,” nítorí Jésù mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá ẹni tí wọ́n jẹ́ tí kò gbàgbọ́, àti ẹni tí yóò fi òun hàn.

65ⓓ Ó sì wí pé, “Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, kò sí ẹni tí ó lè tọ̀ mí wá, bí kò ṣe pé a fi fún un láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá.”

66Nítorí èyí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ padà sẹ́yìn, wọn kò sì báa rìn mọ́.

67Nítorí náà Jésù wí fún àwọn méjìlá pé, “Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ lọ bí?”

68ⓔ Nígbà náà ni Símónì Pétérù dá a lóhùn pé, “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa ó lọ? Ìwọ ni ó ni ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.

69Àwa sì ti gbàgbọ́, a sì mọ̀ pé ìwọ ni Kristì náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”

70ⓕ Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin méjìlá kọ́ ni mo yàn, ọ̀kan nínú yín kò ha sì ya Èṣù?”

71ⓖ (Ó ń sọ ti Júdásì Iskariótù Ọmọ Símónì ọ̀kan nínú àwọn méjìlá: nítorí pé òun ni ẹni tí yóò fi í hàn.)

icle>