Ìwé Ìyìnrere Jòhánù 8:1-59 BYB2014 - Bible AI

1Jésù sì lọ sí orí òkè Ólífì.

2Ó sì tún padà wá sí tẹ́ḿpìlì ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gbogbo ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì jókòó, ó ń kọ́ wọn.

3Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí sì mú obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí a mú ní ṣíṣe panṣágà; wọ́n sì mú un dúró láàrin.

4Wọ́n sì wí fún un pé, “Olùkọ́, a mú obìnrin yìí nínú ìṣe panṣágà,

5Ǹjẹ́ nínú òfin, Mósè pàṣẹ fún wa láti sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta, ṣùgbọ́n ìwọ ha ti wí?”

6Èyí ni wọ́n wí, láti dán á wò, kí wọn ba à lè rí ẹ̀sùn kan kà sí i lọ́rùn.

6Ṣùgbọ́n Jésù bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń fi ìka rẹ̀ kọ̀wé ní ilẹ̀.

7Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ̀, ó nà rọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú.”

8Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó ń kọ̀wé ní ilẹ̀.

9Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, (tí ẹ̀rí-ọkan wọn sì dá wọn lẹ́bi) wọ́n sì jáde lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títí dé àwọn tí ó kẹ́yìn; a sì fi Jésù nìkan sílẹ̀, àti obìnrin náà láàárin, níbi tí ó wà.

10Jésù sì nà rọ́, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, àwọn (olùfisùn rẹ) dà? Kò sí ẹnìkan tí ó dá ọ lẹ́bi?”

11Ó wí pé, “Kò sí ẹnìkan, Olúwa.” Jésù wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi: má a lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́sẹ̀ mọ́.”

12ⓐ Jésù sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

13ⓑ Nítorí náà àwọn Farisí wí fún un pé, “Ìwọ ń jẹ́rí ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òtítọ́.”

14Jésù dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo tilẹ̀ ń jẹ́rí fún ara mi, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi: nítorí tí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mo ń lọ; ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò lè mọ ibi tí mo ti wá, àti ibi tí mo ń lọ.

15ⓒ Ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ nípa ti ara; èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni.

16ⓓ Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni: nítorí èmi nìkan kọ́, ṣùgbọ́n èmi àti Baba tí ó rán mi.

17ⓔ A sì kọ ọ́ pẹ̀lú nínú òfin pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì.

18Èmi ni ẹni tí ń jẹ́rí ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rí mi.”

19ⓕ Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Níbo ni Baba rẹ wà?” Jésù dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi: ìbá ṣe pé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá sì ti mọ Baba mi pẹ̀lú.”

20ⓖ Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jésù sọ níbi ìṣúra, bí ó ti ń kọ́ni ní tẹ́ḿpìlì: ẹnikẹ́ni kò sì mú un; nítorí wákàtí rẹ̀ kò tíì dé.

21ⓗ Nítorí náà ó tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ, ẹ̀yin yóò sì wá mi, ẹ ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: ibi tí èmi gbé ńlọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá.”

22Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Òun ó ha pa ara rẹ̀ bí? Nítorí tí ó wí pé, ‘Ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá’?”

23ⓘ Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ìsàlẹ̀ wá; èmi ti òkè wá; ẹ̀yin jẹ́ ti ayé yìí; èmi kì í ṣe ti ayé yìí

24ⓙ Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: nítorí bí kò ṣe pé ẹ bá gbàgbọ́ pé èmi ni, ẹ ó kú níńu ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

25Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ jẹ́?” Jésù sì wí fún un pé, “Èmi ni èyí tí mo ti wí fún yín ní àtètèkọ́ṣe.

26Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ, àti láti ṣe ìdájọ́ nípa yín: ṣùgbọ́n olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ohun tí èmi sì ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, wọ̀nyí ni èmi ń sọ fún aráyé.”

27Kò yé wọn pé ti Baba ni ó ń sọ fún wọn.

28ⓚ Lẹ́yìn náà Jésù wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ mọ̀ pé, nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé ẹ̀mi ni àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi; ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmí ń sọ nǹkan wọ̀nyí.

29Ẹni tí ó rán mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi: kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan; nítorí tí èmi ń se ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.”

30ⓛ Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà á gbọ́.

31ⓜ Nítorí náà Jésù wí fún áwọn Júù tí ó gbà á gbọ́, pé, “Bí ẹ bá tẹ̀ṣíwájú nínú ọ̀rọ̀ mi ẹ ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yin mi nítòótọ́.

32ⓝ Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.”

33ⓞ Wọ́n dá a lóhùn pé, “Irú-Ọmọ Ábúráhámù ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé; ìwọ ha ṣe wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?”

34ⓟ Jésù dá wọn lóhùn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.

35ⓠ Ẹrú kì í sìí gbé ilé títí láé: ọmọ ní ń gbé ilé títí láé

36Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira ẹ ó di òmìnira nítòótọ́.

37Mo mọ̀ pé irú-ọmọ Ábúráhámù ni ẹ̀yin jẹ́; ṣùgbọ́n ẹ ń wá ọ̀nà láti pa mí nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí àyè nínú yín. Jésù sọ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ara rẹ̀

38Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba ni mo sọ: ẹ̀yin pẹ̀lú sì ń ṣe èyí tí ẹ̀yin ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ baba yín.”

39Wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ábúráhámù ni baba wa!” Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìbá ṣe iṣẹ́ Ábúráhámù

40Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, ẹni tí ó sọ òtítọ́ fún yín, èyí tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run: Ábúráhámù kò ṣe èyí.

41ⓡ Ẹ̀yin ń ṣe iṣẹ́ baba yín.”

41Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “A kò bí wa nípa panṣágà: A ní Baba kan, èyí sì ni Ọlọ́run.”

42ⓢ Jésù wí fún wọn pé, “Ìbáṣe pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ìbá fẹ́ràn mi: nítorí tí èmi ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde, mo sì wá; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n òun ni ó rán mi.

43Èé ṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.

44ⓣ Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké.

45Ṣùgbọ́n nítorí tí èmi ń sọ òtítọ́ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbà mí gbọ́.

46ⓤ Ta ni nínú yín tí ó ti dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀? Bí mo bá ń ṣo òtítọ́ èé ṣe tí ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run

47Ẹni tí ń ṣe ti Ọlọ́run, a máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí èyí ni ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run.”

48ⓥ Àwọn Júù dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò wí nítòótọ́ pé, ará Samaríà ni ìwọ jẹ́, àti pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù?”

49Jésù sì dáhùn pé, “Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù, ṣùgbọ́n èmi ń bu ọlá fún Baba mi, ẹ̀yin kò sì bu ọlá fún mi.

50Èmi kò wá ògo ara mi: Ẹnìkan ń bẹ tí ó ń wá a tí yóò sì ṣe ìdájọ́.

51Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò rí ikú láéláé.”

52Àwọn Júù wí fún un pé, “Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù. Ábúráhámù kú, àti àwọn wòlíì; ìwọ sì wí pé, ‘Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò tọ́ ikú wò láéláé’

53ⓦ Ìwọ ha pọ̀ ju Ábúráhámù Baba wa lọ, ẹni tí ó kú? Àwọn wòlíì sì kú: tani ìwọ ń fi ara rẹ pè?”

54Jésù dáhùn wí pé, “Bí mo bá yin ara mi lógo, ògo mi kò jẹ́ ǹkan; Baba mi ni ẹni tí ń yìn mí lógo, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, Ọlọ́run yín ní i ṣe:

55Ẹ kò sì mọ̀ ọ́n: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: bí mo bá sì wí pé, èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóò di èké gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, mo sì pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́.

56ⓧ Ábúráhámù baba yín yọ̀ láti rí ọjọ́ mi: ó sì rí i, ó sì yọ̀.”

57ⓨ Nítorí náà, àwọn Júù wí fún un pé, “Ọdún rẹ kò ì tó àádọ́ta, ìwọ sì ti rí Ábúráhámù?”

58ⓩ Jésù sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kí Ábúráhámù tó wà, èmi nìyìí.”

59ⓐ Nítorí náà wọ́n gbé òkúta láti sọ lù ú: ṣùgbọ́n Jésù fi ara rẹ̀ pamọ́, ó sì jáde kúrò ní tẹ́ḿpílì.

icle>