1Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ti dáwọ́lé títo àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì jọ lẹ́sẹẹsẹ, èyí tí ó ti múlẹ̀ ṣinṣin láàárin wa,
2ⓐ àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà tí ó ṣe ojú wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ ti fi lé wa lọ́wọ́.
3ⓑ Nítorí náà, ó sì yẹ fún èmi pẹ̀lú láti kọ̀wé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ bí mo ti wádìí ohun gbogbo fínnífínní láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, Tìófílù ọlọ́lá jùlọ,
4ⓒ kí ìwọ kí ó le mọ òtítọ́ ohun wọ̀n-ọn-nì tí a ti kọ́ ọ.
5ⓓ Nígbà ọjọ́ Hérọ́dù ọba Jùdéà, Àlùfáà kan wà, ní ipa ti Ábíà, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Sakaráyà: aya rẹ̀ sì ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìrin Árónì, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Èlísábẹ́tì.
6Àwọn méjèèjì sì ṣe olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n ń rìn ní gbogbo òfin àti ìlànà Olúwa ní àìlẹ́gàn.
7Ṣùgbọ́n wọn kò ní ọmọ, nítorí tí Èlísábẹ́tì yàgàn; àwọn méjèèjì sì di arúgbó.
8Ó sì ṣe, nígbà tí ó ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà níwájú Ọlọ́run níipaṣẹ̀ tirẹ̀
9ⓔ Bí ìṣe àwọn àlùfáà, ipa tirẹ̀ ni láti máa fi tùràrí jóná, nígbà tí ó bá wọ inú tẹ́ḿpìlì Olúwa lọ.
10Gbogbo Ìjọ àwọn ènìyàn sì ń gbàdúrà lóde ní àkókò sísun tùràrí.
11ⓕ Ańgẹ́lì Olúwa kan sì fi ara hàn án, ó dúró ní apá ọ̀tún pẹpẹ tùràrí.
12Nígbà tí Sakaráyà sì rí i, orí rẹ̀ wúlé, ẹ̀rù sì bà á.
13ⓖ Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sakaráyà: nítorí tí àdúrà rẹ gbà; Èlísábẹ́tì aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Jòhánù.
14Òun yóò sì jẹ́ ayọ̀ àti ìdùnnú fún ọ: ènìyàn púpọ̀ yóò sì yọ̀ sí ìbí rẹ.
15ⓗ Nítorí òun ó pọ̀ níwájú Olúwa, kì yóò sì mu ọtí-wáìnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì mu ọtí-líle; yóò sì kún fún Èmí Mímọ́ àní láti inú ìyá rẹ̀ wá.
16Òun ó sì yí ènìyàn púpọ̀ padà nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí Olúwa Ọlọ́run wọn.
17ⓘ Ẹ̀mí àti agbára Èlíjàh ni Olúwa yóò sì fi ṣáájú rẹ̀ lọ, láti pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ti àwọn aláìgbọ́ràn sí ọgbọ́n àwọn olóòótọ́; kí ó le pèṣè àwọn ènìyàn tí a múra sílẹ̀ de Olúwa.”
18ⓙ Sakaráyà sì wí fún áńgẹ́lì náà pé, “Àmì wo ni èmi ó fi mọ èyí? Èmi sá ti di àgbà, àti Èlísábẹ́tì aya mi sì di arúgbó.”
19ⓚ Ańgẹ́lì náà sì dáhùn ó wí fún un pé, “Èmi ni Gébúrẹ́lì, tí máa ń dúró níwájú Ọlọ́run; èmi ni a rán wá láti sọ fún ọ, àti láti mú ìyìn ayọ̀ wọ̀nyí fún ọ wá.
20Sì kíyèsí i, ìwọ ó yadi, ìwọ kì yóò sì le fọhùn, títí ọjọ́ náà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ, nítorí ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ tí yóò ṣẹ ní àkókò wọn.”
21Àwọn ènìyàn sì ń dúró de Sakaráyà, ẹnu sì yà wọ́n nítorí tí ó pẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì.
22Nígbà tí ó sì jáde wá, òun kò le bá wọn sọ̀rọ̀. Wọn sì kíyèsí wí pé ó ti rí ìran nínú tẹ́ḿpílì. ó sì ń se àpẹẹrẹ sí wọn, nítorí tí ó yadi.
23Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ pé, ó lọ sí ilé rẹ̀.
24Lẹ́yìn èyí ni Èlísábẹ́tì aya rẹ̀ lóyún, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́ ní oṣù márùn-ún, ó ní,
25Ó sì wí pé “Báyìí ni Olúwa ṣe fún mi ní ọjọ́ tí ó ṣíjú wò mí, láti mú ẹ̀gàn mi kúrò láàrin àwọn ènìyàn.”
26Ní oṣù kẹfà Ọlọ́run sì rán áńgẹ́lì Gébúríẹ́lì sí ìlú kan ní Gálílì, tí à ń pè ní Násárẹ́tì,
27sí wúndíá kan tí a ṣè lérí láti fẹ́ fún ọkùnrin kan, tí a ń pè ní Jóṣéfù, ti ìdílé Dáfídì; orúkọ wúndíá náà a sì máa jẹ́ Màríà.
28Ańgẹ́lì náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Àlààáfíà, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ńbẹ pẹ̀lú rẹ”
29Ṣùgbọ́n ọkàn Màríà kò lélẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà, ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, irú kíkí kínni èyí.
30ⓛ Ṣùgbọ́n àńgẹ́lì náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Màríà: nítorí ìwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
31ⓜ Ìwọ óò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní JÉSÙ.
32Òun ó pọ̀, Ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é: Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún:
33ⓝ Yóò sì jọba lórí ilé Jákọ́bù títí láé; ìjọba rẹ̀ kì yóò sì ní ìpẹ̀kun.”
34ⓞ Nígbà náà ni Màríà bèèrè lọ́wọ́ ańgẹ́lì náà pé, “Èyí yóò ha ti ṣe rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí èmi kò tii mọ ọkùnrin.”
35ⓟ Ańgẹ́lì náà sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóò tọ̀ ọ́ wá, àti agbára Ọ̀gá-ògo jùlọ yóò sìji bò ọ́. Nítorí náà ohun mímọ́ tí a ó ti inú rẹ bí, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè é.
36Sì kíyèsí i, Èlísábẹ́tì ìbátan rẹ náà yóò sì ní ọmọ kùnrin kan ní ògbólògbó rẹ̀: èyí sì ni oṣù kẹfà fún ẹni tí à ń pè ní àgàn.
37ⓠ Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe.”
38“Màríà sì dáhùn wí pé, wò ó ọmọ-ọ̀dọ̀ Olúwa; kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Ańgẹ́lì náà sì fi í sílẹ̀ lọ.
39Ní ijọ́ wọ̀nyí ni Màríà sì dìde, ó lọ kánkán sí ilẹ̀ òkè, sí ìlú kan ní Júdà;
40Ó sì wọ ilé Sakaráyà lọ ó sì kí Èlísabẹ́tì.
41Ó sì ṣe, nígbà tí Èlísábẹ́tì gbọ́ kíkí Màríà, ọlẹ̀ sọ nínú rẹ̀; Èlísábẹ́tì sì kún fún Èmí mímọ́;
42ⓡ Ó sì ké ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Alúbùkún fún ni ìwọ nínú àwọn obìnrin, alábùkúnfún sì ni ọmọ tí ìwọ yóò bí.
43Èéṣe tí èmi fi rí irú ojúrere yìí, tí ìyá Olúwa mi ìbá fi tọ̀ mí wá?
44Sá wò ó, bí ohùn kíkí rẹ ti bọ́ sí mi ní etí, ọlẹ̀ sọ nínú mi fún ayọ̀.
45Alábùkúnfún sì ni ẹni tí ó gbàgbọ́: nítorí nǹkan wọ̀nyí tí a ti sọ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò ṣẹ.”
46Màríà sì dáhùn, ó ní: “Ọkàn mi yin Olúwa lógo,
47Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
48Nítorí tí ó ṣíjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀: Sá wò ó,láti ìsinsìn yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkúnfún.
49Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi;Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.
50Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀láti ìrandíran.
51Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀;Ó ti tú àwọn onígberaga ká ní ìrònú ọkàn wọn.
52Ó ti mú àwọn alágbára kúrò lórí ìtẹ́ wọn,Ó sì gbé àwọn onírẹ̀lè lékè.
53Ó ti fi ohun tí ó dára kún àwọn tí ebí ń paó sì rán àwọn ọlọ́rọ̀ padà ní òfo.
54Ó ti ran Ísíráẹ́lì ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́,Ní ìrántí àánú rẹ̀;
55ⓢ sí Ábúráhámù àti àwọn ìran rẹ̀ láéláé, baba wa,àti bí ó ti sọ fún àwọn baba wa.”
56Màríà sì jókòó tì Èlísábétì níwọ̀n oṣù mẹ́ta, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀.
57Nígbà tí ọjọ́ Èlísabẹ́tì pé wàyí tí yóò bí; ó sì bí ọmọkùnrin kan.
58Àwọn aládùúgbò, àti àwọn ìbátan rẹ̀ gbọ́ bí Olúwa ti fi àánú ńlá hàn fún un, wọ́n sì bá a yọ̀.
59ⓣ Ó sì ṣe, ní ijọ́ kẹjọ wọ́n wá láti kọ ọmọ náà nílà; wọ́n sì fẹ́ sọ orúkọ rẹ̀ ní Sakaráyà, gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba rẹ̀.
60Ìyá rẹ̀ sì dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Jòhánù ni a ó pè é.”
61Wọ́n sì wí fún un pé, “Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ará rẹ̀ tí à ń pè ní orúkọ yìí.”
62Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí bàbá rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é.
63Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, “Jòhánù ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn.
64Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọ́gán, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì sọ̀rọ̀, ó sì ń yin Ọlọ́run.
65Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ń bẹ ní agbègbè wọn: a sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí ká gbogbo ilẹ̀ òkè Jùdéà.
66Ó sì jẹ́ ohun ìyọnu fún gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n ń wí pé, “Irú ọmọ kínni èyí yóò jẹ́?” Nítirí tí ọwọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.
67Sakaráyà baba rẹ̀ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì ṣọtẹ́lẹ̀, ó ní:
68“Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì;Nítorí tí ó ti bojúwò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè,
69Ó sì ti gbé ìwo ìgbàlà sókè fún waNí ilé Dáfídì ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀;
70(bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ ní ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ típẹ́típẹ́),
71Pé, a ó gbà wá là lọ́wọ́àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ àwọn tí ó kórira wá;
72Láti ṣe àánú tí ó ti lérí fún àwọn baba wa,Àti láti rántí májẹ̀mu rẹ̀ mímọ́,
73ìbúra tí ó ti bú fún Ábúráhámù baba wa,
74láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,Kí àwa kí ó lè máa sìn ín láìfòyà,
75Ní mímọ́ ìwà àti ní òdodo níwájú rẹ̀, ní ọjọ́ ayé wa gbogbo.
75
76ⓤ “Àti ìwọ, ọmọ mi, wòlíì Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó máa pè ọ́:Nítorí ìwọ ni yóò ṣáájú Olúwa láti tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe;
77ⓥ Láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn ènìyàn rẹ̀fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
78ⓦ nítorí ìyọ́nú Ọlọ́run wà;nípa èyí tí ìlà-òrùn láti òkè wá bojúwò wá,
79ⓧ Láti fi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó jókòó níòkùnkùn àti ní òjìjì ikú.Àti láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà àlààáfíà.”
80ⓨ Ọmọ náà sì dàgbà, ó sì le ní ọkàn, ó sì ń gbé ní ijù títí ó fi di ọjọ́ ìfihàn rẹ̀ fún Ísírẹ́lì.