1
2Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan tí ó ní àsunkún ń bẹ níwájú rẹ̀.
3
4Wọ́n sì dákẹ́. Ó sì mú un, ó sì mú un láradá, ó sì jẹ́ kí ó lọ.
5
6Wọn kò sì lè dá a lóhùn mọ́ sí nǹkan wọ̀nyí.
7Ó sì pa òwe kan fún àwọn tí ó pè é wá jẹun, nígbà tí ó ṣàkíyèsí bí wọ́n ti ń yan ipò ọlá; ó sì wí fún wọn pé:
8
9Nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ àti òun bá dé, a sì wí fún ọ pé, ‘Fún ọkùnrin yìí ní àyè!’ Ìwọ á sì wá fi ìtìjú mú ipò ẹ̀yìn.
10Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá pè ọ́, lọ kí o sì jókòó ní ipò ẹ̀yìn; nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, kí ó lè wí fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́, bọ́ sókè!’ Nígbà náà ni ìwọ ó ní ìyìn lójú àwọn tí ó bá ọ jókòó t'oúnjẹ.
11
12
13
14Ìwọ ó sì jẹ́ alábùkún fún; nítori wọn kò ní ohun tí wọn ó fi san án fún ọ: ṣùgbọ́n a ó san án fún ọ ní àjíǹde, àwọn olóòótọ́.”
15
16
17Ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní wákàtí àsè alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Ẹ wá; nítorí ohun gbogbo ṣe tán!’
18“Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ ní ohùn kan láti ṣe àwáwí. ‘Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’
19“Èkejì sì wí pé, ‘Mo ra màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’
20
21
22“Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì wí pé, ‘Olúwa a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, àyè sì ń bẹ síbẹ̀.’
23“Olúwa náà sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà pé, ‘Jáde lọ sí òpópó, àti sí ọ̀nà ọgbà, kí o sì rọ̀ wọ́n láti wọlé wá, kí ilé mi lè kún.
24Nítorí mo wí fún yín, Ẹnìkẹ́ni nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí a ti pè, kì yóò tọ́ wò nínú àsè ńlá mi!’ ”
25Àwọn ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ń bá a lọ; ó sì yípadà, ó sì wí fún wọn pé,
26
27
28“Nítorí tani nínú yín tí ń pète láti kọ́ ilé ìṣọ́, tí kì yóò kọ́kọ́ jòkòó kí ó ṣírò iye owó rẹ̀, bí òun ní tó tí yóò fi parí rẹ̀.
29Kí ó má baà jẹ́ pé nígbà tí ó bá fi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ tan, tí kò lè parí rẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn tí ó rí i a bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe ẹlẹ́yà.
30Wí pé, ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé, kò sì lè parí rẹ̀.’
31“Tàbí ọba wo ni ó ń lọ bá ọba mìíràn jà, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbèrò bí yóò lè fi ẹgbàarún-ún pàdégun ẹni tí ń mú ẹgbàawàá bọ̀ wá ko òun lójú?
32Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà tí onítọ̀hún bá sì wà ní òkèrè, òun a rán ikọ̀ sí i, a sì bẹ̀rẹ̀ àdéhùn àlààáfíà.
33
34
35Kò yẹ fún ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ fún ààtàn; bí kò ṣe pé kí a kó o dànù.