1Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú pé, “Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ní ìríjú kan; òun náà ni wọ́n fi sùn ún pé, ó ti ń fi ohun-ìní rẹ̀ ṣòfò.
2Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, ‘Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ? ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ; nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mọ́.’
3“Ìríjú náà sì wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Nítorí tí olúwa mi gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi: èmi kò lè walẹ̀; láti sàgbẹ̀ ojú ń tì mí.
4Mo mọ èyí tí èmi yóò se, nígbà tí a bá mú mi kúrò níbi isẹ́ ìríjú, kí wọn kí ó le gbà mí sínú ilé wọn.’
5“Ó sì pe àwọn ajigbèsè olúwa rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún èkínní pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ olúwa mi?’
6“Ó sì wí pé, ‘Ọgọ́rùn-ún Òṣùwọ̀n òróró.’
7“Nígbà náà ni ó sì bi ẹnìkejì pé, ‘Èló ni ìwọ́ jẹ?’
8
9
10
11Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò bá ti jẹ́ olóòótọ́ ní mámónì àìṣòótọ́, tani yóò fi ọ̀rọ̀ tòótọ́ ṣú yín?
12Bí ẹ̀yin kò bá sì ti jẹ́ olóòtítọ́ ní ohun tí í se ti ẹlòmíràn, tani yóò fún yín ní ohun tí í se ti ẹ̀yin tìkara yín?
13
14Àwọn Farisí, tí wọ́n ní ojúkòkòrò sì gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì yọ sùtì sí i.
15
16
17
18
19“Ǹjẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ń wọ asọ elésèé àlùkò àti asọ àlà dáradára, a sì máa jẹ dídùndídùn lójóojúmọ́:
20
21Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun: àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá.
22
23Ní ipò-òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìṣẹ́ oró, ó sì rí Ábúráhámù ní òkèrè, àti Lásárù ní oókan-àyà rẹ̀.
24Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Ábúráhámù, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lásárù, kí ó tẹ oríka rẹ̀ bọmi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’
25
26Àti pẹ̀lú gbogbo èyí, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbede-méjì àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tí ń fẹ́ má baa le rékọjá láti ìhín lọ sọ́dọ̀ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì le ti ọ̀hún rékọjá tọ̀ wá wá.’
27“Ó sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ mo bẹ̀ ọ́, baba, kí ìwọ kí ó rán an lọ sí ilé baba mi:
28Nítorí mo ní arákùnrin márùnún; kí ó lè rò fún wọn kí àwọn kí ó má baa wá sí ibi oró yìí pẹ̀lú.’
29
30
31“Ó sì wí fún un pé, ‘Bí wọn kò bá gbọ́ ti Mósè àti ti àwọn wòlíì, a kì yóò yí wọn ní ọkàn padà bí ẹnìkan tilẹ̀ ti inú òkú dìde.’ ”