1
2Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan wà tí a ń pè ní Sákéù, ó sì jẹ́ olórí agbowó òde kan, ó sì jẹ́ ọlọ́rọ̀.
3Ó sì ń fẹ́ láti rí ẹni tí Jésù jẹ́: kò sì lè rí i, nítrorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti nítorí tí òun jẹ́ ènìyàn kúkúrú.
4Ó sì súré ṣíwájú, ó gun orí igi síkámórè kan, kí ó bà lè rí i: nítorí tí yóò kọjá lọ níhà ibẹ̀.
5Nígbà tí Jésù sì dé ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i, ó sì wí fún un pé, “Sákéù! Yára, kí o sì sọ̀kalẹ̀; nítorí pé èmi yóò wọ ilé rẹ lóní.”
6Ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbà á.
7
8
9
10Nítorí Ọmọ Ènìyàn dé láti wá àwọn tí ó nù kiri, àti láti gbà wọ́n là.”
11
12
13Ó sì pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mínà mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ má a ṣòwò títí èmi ó fi dé!’
14“Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, ‘Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jọba lórí wa.’
15“Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́-òwò wọn.
16“Èyí èkínní sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mínà rẹ jèrè owó mínà mẹ́wá sí i.’
17
18“Èyí èkéjì sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mínà rẹ jèrè owó mínà márùnún.’
19“Olúwa rẹ sì wí fún un pẹ̀lú pé, ‘Ìwọ joyè ìlú márùnún!’
20“Òmíràn sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, wòó owó mínà rẹ tí ń bẹ lọ́wọ́ mi ni mo dì sínú aṣọ-pélébé kan;
21Nítorí mo bẹ̀rù rẹ, àti nítorí tí ìwọ ṣe òǹrorò ènìyàn: ìwọ a máa mú èyí tí ìwọ kò fi lélẹ̀, ìwọ a sì máa ká èyí tí ìwọ kò gbìn!’
22“Olúwa rẹ sì wí fún un pé, ‘Ní ẹnu ara rẹ náà ni èmi ó ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni mí, pé, èmi a máa mú èyí tí èmi kò fi lélẹ̀ èmi a sì máa ká èyí tí èmi kò gbìn;
23Èé ha sì ti ṣe tí ìwọ kò fi owó mi pamọ́ sí ilé ìfowó pamọ́, pé nígbà tí mo bá dé, Èmi ìbá ti béèrè rẹ̀ pẹ̀lú èlé?’
24“Ó sì wí fún àwọn tí ó dúró létí ibẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó mínà náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fi í fún ẹni tí ó ní owó mínà mẹ́wàá.’
25“Wọ́n sì wí fún un pé, ‘Olúwa, ó ní owó mínà mẹ́wàá.’
26
27Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá mi wọ̀nyí, tí kò fẹ́ kí èmi jọba lórí wọn ẹ mú wọn wá ìhínyìí, kí ẹ sì pa wọ́n níwájú mi!’ ”
28
29
30Wí pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó kọjú sí yín; nígbà tí ẹ̀yin bá wọ̀ ọ́ lọ, ẹ̀yin ó rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí: ẹ tú u, kí ẹ sì fà á wá.
31Bí ẹnikẹ́ni bá sì bi yín pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tú u?’ Kí ẹ̀yin wí báyìí pé, ‘Olúwa ń fẹ́ lò ó.’ ”
32
33Bí wọ́n sì ti ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn Olúwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?”
34
35Wọ́n sì fà á tọ Jésù wá: wọ́n sì tẹ́ ẹ wọ́n sì gbé Jésù kà á.
36
37Bí ó sì ti súnmọ́ etí ibẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olófì, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀, wọ́n sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run, nítorí iṣẹ́ ńlá gbogbo tí wọ́n ti rí;
38
39
40Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí fún wọn pé, “Mo wí fún yín, Bí àwọn wọ̀nyí bá pa ẹnu wọn mọ́, àwọn òkúta yóò kígbe sókè.”
41
42Ó ń wí pé, “Ìbáṣepé ìwọ mọ̀, lóní yìí, àní ìwọ, ohun tí í ṣe tí àlààáfíà rẹ! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n pamọ́ kúrò lójú rẹ.
43
44
45
46Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò olè.”
47
48Wọn kò sì rí nǹkan kan tí wọn ìbá ṣe; nítorí gbogbo ènìyàn ṣù mọ́ ọn láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.