1
2
3Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi pẹ̀lú yóò sì bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan; ẹ sì fi ìdáhùn fún mi.
4Bamitísímù ti Jòhánù, láti ọ̀run wá ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?”
5Wọ́n sì bá ara wọn gbérò pé, “Bí àwa bá wí pé, ‘Láti ọ̀run wá ni,’ òun ó wí pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’
6
7Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Wọn kò mọ̀ ibi tí ó ti wá.”
8Jésù sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ èmi kì yóò wí fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”
9
10Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùsọ́gbà náà: kí wọn lè fún un nínú èṣo ọgbà àjàrà náà: ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.
11Ó sì tún rán ọmọ-ọ̀dọ̀ míràn: wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ níyà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.
12Ó sì tún rán ẹ̀kẹ́ta: wọ́n sì ṣá a lọ́gbẹ́ pẹ̀lú, wọ́n sì tì í jáde.
13“Nígbà náà ni Olúwa ọgbà àjàrà wí pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Èmi ó rán ọmọ mi àyànfẹ́ lọ: bóyá nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn ó ṣojúsájú fún un.’
14“Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn alágbàtọ́jú náà rí i, wọ́n bá ara wọn gbérò pé, ‘Èyí ni àrólé; ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún rẹ̀ lè jẹ́ ti wa.’
15Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tìí jáde sẹ́yìn ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á.
16
17
18
19
20
21
22Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó-òde fún Késárì, tàbí kò tọ́?”
23Ṣùgbọ́n ó kíyèsí àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé,
24“Ẹ fi owó-idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti tani ó wà níbẹ̀?”
25
26Wọn kò sì lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú níwájú àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn rẹ̀, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́.
27
28
29Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ.
30Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ.
31Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú: wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú.
32Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú.
33Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya tìtani yóò ha ṣe nínú wọn? Nítorí àwọn méjèèje ni ó sáà ni ín ní aya.”
34Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún-ni.
35Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún-ni.
36Nítorí wọn kò lè kú mọ́; nítorí tí wọn bá àwọn áńgẹ́lì dọ́gba; àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde.
37
38Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè: nítorí gbogbo wọn wà láàyè fún un.”
39
40
41
42Dáfídì tìkárarẹ̀ sì wí nínú ìwé Psalmu pé:
43
44Ǹjẹ́ bí Dáfídì bá pè é ní ‘Olúwa.’ Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
45
46“Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn ní aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú sínágọ́gù, àti ipò ọlá ní ibi àsè;
47Àwọn tí ó jẹ ilé àwọn opó run, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn: àwọn wọ̀nyí náà ni yóò jẹ̀bi pọ̀jù.”