1
2Òkúta ti yí kúrò ní ẹnu ibojì.
3Nígbà tí wọ́n sì wọ inú rẹ̀, wọn kò rí òkú Jésù Olúwa.
4Bí wọ́n ti dààmú kiri níhà ibẹ̀, kíyèsí i, àwọn ọkùnrin méjì aláṣọ dídán dúró tì wọ́n:
5Nígbà tí ẹ̀rù ń bà wọ́n, tí wọ́n sì dojúbolẹ̀, àwọn ańgẹ́lì náà bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá alààyè láàrin àwọn òkú?
6
7Pé, ‘A ó fi ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn ẹlẹ́sẹ̀ lọ́wọ́, a ó sì kàn án mọ́ àgbélèbú, ní ijọ́ kẹ́ta yóò sì jíǹde.’ ”
8Wọ́n sì rántí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
9Wọ́n sì padà ti ibojì wá, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún àwọn mọ́kànlá, àti fún gbogbo àwọn ìyókù.
10
11Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì dàbí ìsọkúsọ lójú wọn, wọn kò sì gbà wọ́n gbọ́.
12Nígbà náà ni Pétérù dìde, ó súré lọ sí ibojì; nígbà tí ó sì bẹ̀rẹ̀, ó rí aṣọ àlà lọ́tọ̀ fúnrarawọn, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣe.
13Sì kíyèsí i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ijọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Èmáúsì, tí ó jìnnà sí Jerúsálémù níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀.
14Wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣẹlẹ̀.
15Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jésù tìkara rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ.
16
17Ó sì bi wọ́n pé, “Ọ̀rọ̀ kínni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?”
18Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kíléópà, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sáà ni ìwọ ní Jerúsálémù, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?”
19
20Àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélèbú.
21Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Ísírẹ́lì ní ìdè. Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹ́ta tí nǹkan wọ̀nyí ti sẹlẹ̀.
22Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá dá wa níjì:
23Nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn ańgẹ́lì tí wọ́n wí pé, ó wà láàyè.
24
25Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́:
26Kò ha yẹ kí Kírísítì ó jìyà nǹkan wọ̀nyí kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀ lọ.”
27
28
29Wọ́n sì rọ̀ ọ́, pé, “Bá wa dúró: nítorí ó di ọjọ́ alẹ́, ọjọ́ sì kọjá tán.” Ó sì wọlé lọ, ó bá wọn dúró.
30
31Ojú wọn sì là, wọ́n sì mọ̀ ọ́n; ó sì nù mọ́ wọn ní ojú
32Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, “Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa!”
33Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerúsálémù, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn,
34
35Àwọn náà sì ròyìn nǹkan tí ó ṣe ní ọ̀nà, àti bí ó ti di mímọ̀ fún wọn ní bíbu àkàrà.
36
37Ṣùgbọ́n àyà fò wọ́n, wọ́n sì díjì, wọ́n ṣe bí àwọn rí ẹ̀mí kan.
38Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ara yín kò lélẹ̀? Èé sì ti ṣe tí ìròkúrò fi ń sọ nínú ọkàn yín?
39
40Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọ́n.
41Nígbà tí wọn kò sì tí ì gbàgbọ́ fún ayọ̀, àti fún ìyanu, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ní ohunkóhun jíjẹ níhín yìí?”
42Wọ́n sì fún un ní ẹja tí a fi oyin sè.
43Ó sì gbà á, ó jẹ ẹ́ lójú wọn.
44
45Nígbà náà ni ó ṣí wọn níyè, kí ìwé mímọ́ lè yé wọn.
46
47
48Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí.
49
50Ó sì mú wọn jáde lọ títí wọ́n fẹ́rẹ̀ dé Bétanì, nígbà tí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó súre fún wọn.
51
52
53Wọ́n sì wà ní tẹ́ḿpìlì nígbà gbogbo, wọ́n ń fi ìyìn, àti ìbùkún fún Ọlọ́run. Àmín.