1ⓐ Ní ọdún kẹẹ̀dógún ìjọba Tiberíù Késárì, nígbà tí Pontíù Pílátù jẹ́ Baálẹ̀ Jùdéà, tí Hẹ́ródù sì jẹ́ tẹ́tírákì Gálílì, Fílípì arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetírákì Ituréà àti ti Tirakonítì, Nísáníà sì jẹ́ Tétírákì Ábílénì,
2ⓑ Tí Ánásì òun Káíáfà ń ṣe olórí àwọn àlùfáà, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Jòhánù ọmọ Sakaráyà wá ní ijù.
3ⓒ Ó sì wá sí gbogbo ilẹ̀ ìha Jọ́dánì, ó ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀;
4ⓓ Bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Àìṣáyà pé,
4“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,Ẹ mú ipa-ọ̀nà rẹ̀ tọ́.
5Gbogbo ọ̀gbun ni a óò kún,Gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ̀bẹ̀rẹ̀;Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́,àti ọ̀nà gbọ́ngun-gbọ̀ngun ni a o sọ di dídán.
6ⓔ Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ”
7ⓕ Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀?
8ⓖ Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwá ní Ábúráhámù ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Ábúráhámù nínú òkúta wọ̀nyí.
9ⓗ Àti nísinsìnyí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà: gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a ké e lulẹ̀, a sì wọ́ ọ jù sínú iná.”
10Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ha ṣe?”
11Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”
12Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?”
13Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.”
14Àwọn ọmọ-ogun sì bèèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kíni àwa ó ṣe?”
14Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùneké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.”
15ⓘ Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Jòhánù, bí òun ni Kírísítì bí òun kọ́;
16ⓙ Jòhánù dáhùn ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Lóòótọ́ ni èmi ń fi omi bamtíìsì yín; ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ńbọ̀, okùn bàtà ẹ̀ṣẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ítú: òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamtísì yín:
17Ẹni tí àtẹ rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, láti gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tótó, kí ó sì kó àlìkámà rẹ̀ sínú àká; ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.”
18Jòhánù lo oríìṣíríṣìí ọ̀rọ̀ púpọ̀ láti gba àwọn ènìyàn níyànjú àti láti wàásù ìhìnrere fún wọn.
19ⓚ Ṣùgbọ́n nígbà ti Jòhánù bú Hẹ́rọ́dù tetírakì, tí ó bá wí nítorí Hérọ́díà aya Fílípì arákùnrin rẹ̀, àti nítorí ohun búburú gbogbo tí Hẹ́ródù tí ṣe,
20Ó fi èyí parí gbogbo rẹ̀ ní tí ó fi Jòhánù sínú túbú.
21ⓛ ⓜ Nígbà tí a sì ìtẹ̀bọmi àwọn ènìyàn gbogbo tán, ó sì ṣe, a bamtíìsì Jésù pẹ̀lú, bí ó ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀,
22ⓝ Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
23ⓞ ⓟ Jésù tìkara rẹ̀ ń tó bí ẹni ọgbọ̀n ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ (bí a ti fi pè) ọmọ Jósẹ́fù, tí í ṣe ọmọ Élì,
24Tí í ṣe ọmọ Mátatì, tí í ṣe ọmọ Janà, tí í ṣe ọmọ Jóṣẹ́fù,
24tí í ṣe ọmọ Léfì, tí í ṣe ọmọ Melíkì,
25Tí í ṣe ọmọ Matataì, tí í ṣe ọmọ Ámósì, tí í ṣe ọmọ Nágáì,
25tí í ṣe ọmọ Náúmù, tí í ṣe ọmọ Ésílì,
26Tí í ṣe ọmọ Máátì, tí í ṣe ọmọ Jósẹ́fù, tí í ṣe ọmọ Jódà,
26tí í ṣe ọmọ Matatíà, tí í ṣe ọmọ Síméì,
27Tí í ṣe ọmọ Jóánà, tí í ṣe ọmọ Résà, tí í ṣe ọmọ Nérì,
27tí í ṣe ọmọ Sérúbábélì, tí í ṣe ọmọ Sítíélì,
28Tí í ṣe ọmọ Melíkì, tí í ṣe ọmọ Élímadámù, tí í ṣe ọmọ Érì,
28tí í ṣe ọmọ Ádì, tí í ṣe ọmọ Kòsámù,
29Tí í ṣe ọmọ Jósúà, tí í ṣe ọmọ Élíásérì, tí í ṣe ọmọ Léfì,
29tí í ṣe ọmọ Jórímù, tí í ṣe Màtátì,
30Tí í ṣe ọmọ Síméónì, tí í ṣe ọmọ Jónámù, tí í ṣe ọmọ Élíákímù,
30tí í ṣe ọmọ Júdà, tí í ṣe ọmọ Jóséfù,
31Tí í ṣe ọmọ Méléà, tí í ṣe ọmọ Méná, tí í ṣe ọmọ Dáfídì,
31tí í ṣe ọmọ Mátatà, tí í ṣe ọmọ Nátanì,
32Tí í ṣe ọmọ Jésè, tí í ṣe ọmọ Sólómónì, tí í ṣe ọmọ Náásónì,
32tí í ṣe ọmọ Óbédì, tí í ṣe ọmọ Bóásì,
33Tí í ṣe ọmọ Ámínádábù, tí íṣe ọmọ Rámù, tí í ṣe ọmọ Júdà.
33tí í ṣe ọmọ Ésírónì, tí í ṣe ọmọ Fárésì,
34Tí í ṣe ọmọ Jákọ́bù, tí í ṣe ọmọ Térà, tí í ṣe ọmọ Náhórì,
34tí í ṣe ọmọ Ísáákì, tí í ṣe ọmọ Ábúráhámù,
35Tí í ṣe ọmọ Sárúgù, tí í ṣe ọmọ Rágáù, tí í ṣe ọmọ Sélà.
35tí í ṣe ọmọ Fálékì, tí í ṣe ọmọ Ébérì,
36Tí í ṣe ọmọ Kénánì, tí í ṣe ọmọ Nóà, tí í ṣe ọmọ Lámékì,
36tí í ṣe ọmọ Árífásádì, tí í ṣe ọmọ Sémù,
37Tí í ṣe ọmọ Mètúsélà, tí í ṣe ọmọ Énókù, tí í ṣe ọmọ Kénánì.