1
2Ó rí ọkọ̀ méjì tọ́ wá létí adágún: èyí tí àwọn apẹja ti sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú wọn, nítorí tí wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn.
3
4Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ í sọ, ó wí fún Símónì pé, “Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀.”
5
6Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja: àwọ̀n wọn sì ya.
7Wọ́n sì pe àwọn ẹgbẹ́ wọn, tí ó wà ní ọkọ̀ kéjì, kí wọn kí ó wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n sì wá, wọ́n kó ẹja ọkọ̀ méjèèjì sì kún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì.
8Nígbà tí Símónì Pétérù sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bá eékún Jésù, ó wí pé, “Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; nítorí ẹlẹ́sẹ̀ ni mí.”
9Ẹnu sì yàá wọ́n, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, fún àkópọ̀ ẹja tí wọ́n kó:
10Bẹ́ẹ̀ ni Jákọ́bù àti Jòhánù àwọn ọmọ Sébédè, tí ń ṣe alábàákẹ́gbẹ́ Símónì.
11Nígbà tí wọ́n sì ti mú ọkọ̀ wọn dé ilẹ̀, wọ́n fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lọ.
12
13Jésù sì na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́!” Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ.
14
15
16
17
18Sáà sì kíyèsí i, àwọn Ọkùnrin kan gbé ẹnikantí ó ní àrùn egba wà lórí àketè: wọ́n ń wá ọ̀nà àti gbé e wọlé, àti láti tẹ́ ẹ ṣíwájú Jésù.
19Nígbà tí wọn kò sì rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi gbé e wọlé nítorí ìjọ ènìyàn, wọ́n gbé e gun òkè àjà ilé lọ, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sí àárín èrò ti òun ti àketè rẹ̀ níwájú Jésù.
20Nígbà tí ó sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí pé, “Ọkùnrin yìí, a darí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” (Luk 7.48,49.)
21Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí í gbérò wí pé, “Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀ òdì? Ta ni ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo.” (Isa 43.25.)
22Jésù sì mọ ìrò inú wọn, ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín?
23Èwo ni ó yá jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tàbí láti wí pé, ‘Dìde kí ìwọ sì má a rìn’?
24Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ọmọ ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini…” Ó wí fún ẹlẹ́gbà náà pé, “Mo wí fún ọ, dìde, sì gbé àketè rẹ, kí o sì máa lọ sí ilé!”
25Ó sì dìde lọ́gán níwájú wọn, ó gbé ohun tí ó dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó yin Ọlọ́run lógo.
26Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹ̀rù sì bà wọ́n, wọ́n ń wí pé, “Àwá rí ohun abàmì lónì-ín.”
27
28Léfì sì fi ohun gbogbo sílẹ̀ ó sì ń tẹ̀lé e.
29Léfì sì ṣe àṣè ńlá kan fún Jésù ní ilé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti àwọn mìíràn sì ń jẹun pẹ̀lú wọn.
30
31Jésù dáhùn ó wí fún wọn pé “Ẹni tí ara rẹ̀ le kò nílò oníṣègùm, bí kò ṣe ẹni tí ara rẹ̀ kò dá.”
32
33
34Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ó seé se kí àwọn àlejò ọkọ ìyàwó máa gbàwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó wà pẹ́lú wọn bí?
35Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyìí ni wọn yóò gbàwẹ̀.”
36Ó sì pa òwe yìí fún wọn wí pé: “Kò sí ẹni tó lè ya asọ tuntun kí ó sì rán mọ́, èyí tó ti gbó. Tí ó ba ṣe èyí, yóò ba asọ tuntun jẹ́, èyí tí ó tuntun náà kì yóò ṣe dógba pẹ̀lú èyí tí ó ti gbó.
37Àti wí pé, kò sí ẹni tí ó lè dá otí wáìnì sínú ògbólógbò awọ, tí ó bá ṣe èyí, wáìnì tuntun yóò fa awọ náà ya, wáìnì náà yóò dànù awo náà a sí.
38Nítorí náà, ó tọ́ kí á da wáìnì tuntun sínú awọ tuntun.
39Kò sì ẹni tí yóò fẹ́ láti mu wáìnì tuntun lẹ́yìn tí ó bá ti mu ogbólógbò tán, nítorí yóò wí pé ‘èyí tí ó jẹ́ ògbólógbò dára jù.’ ”