1Ìbẹ̀rẹ̀ ìyìnrere nípa Jésù Kírísítì, Ọmọ Ọlọ́run.
2
3
4
5Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Jùdíà, àti gbogbo ènìyàn Jerúsálémù jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọmi ni odò Jọ́dánì, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
6Jòhánù sì wọ ẹ̀wù tí a fi irun ràkúnmí hun. Ó sì lo ìgbànú awọ. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.
7Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹṣẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú.
8Èmi ń fi omi se ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ se ìtẹ̀bọmi yín.”
9
10Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jésù ń ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó sí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọkalẹ̀ lé E lórí.
11
12
13Ó sì wà níbẹ̀ fún ogójì ọjọ́. A sì fi Í lé Èṣù lọ́wọ́ láti dán an wò. Àwọn ańgẹ́lì sì wá ṣe ìtọ́jú Rẹ̀.
14
15Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dèdè. Ẹ yípadà kúró nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìyìnrere yìí gbọ́.”
16
17Jésù sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.”
18Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.
19Bí Ó sì ti rìn ṣíwájú díẹ̀, ní etí òkun, Ó rí Jákọ́bù àti Jòhánù, àwọn ọmọ Sébédè nínú ọkọ̀ wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe.
20Ó sì ké sí àwọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi Sébédè baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tẹ̀lé e.
21
22Ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn nítorí ìkọ́ni rẹ̀, nítorí pé ó ń kóni bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn olùkọ́ òfin ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn.
23
24
25Jésù si bá a wí, ó wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí ó sì jáde kúro lára rẹ̀.”
26Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì gbé e sánlẹ̀ lógèdèǹgbé, ó ké ní ohùn rara, ó sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà.
27Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń sọ láàrin ara wọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Wọ́n béèrè pẹ̀lú ìgbóná ara, pé, “Kí ni èyí? Irú ẹ̀kọ́ titun wo ni èyí? Ó ń fi agbára pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀.”
28Ìròyìn nípa rẹ̀ tàn ká gbogbo agbégbé Gálílì.
29
30Ìyá ìyàwó Símónì tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jésù nípa rẹ̀.
31Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; lójú kan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
32
33Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà.
34Jésù sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú aláìsàn sàn. Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde, Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í se.
35
36Símónì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a.
37nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!”
38Jésù sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.”
39
40
41Jésù kún fún àánú, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó fi ọwọ́ rẹ̀ bà a, ó wí pé, “Èmí fẹ́. Di mímọ́.”
42Lójúkan-náà ẹ̀tẹ̀ náà fi sílẹ̀ lọ, ọkùnrin náà sì rí ìwòsàn.
43Jésù sì kìlọ̀ fún un gidigidi
44
45Ṣùgbọ́n ó jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pòkìkì, ó ń tan ìròyìn kálẹ̀. Nítorí èyí, Jésù kò sì le wọ ìlú ní gba-n-gba mọ́, ṣùgbọ́n ó wà lẹ́yìn odi ìlú ní ihà. Ṣíbẹ̀, àwọn ènìyàn tọ̀ ọ́ wá láti ibi gbogbo.