1
2Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tó wà lọ́hùn-ún nì. Nígbà tí ẹ bá sì wọlé, ẹ̀yin yóò rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a so mọ́lẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ì tí i gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú wá síhìn-ín.
3Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń se èyí?’ Ẹ sọ fún un pé, ‘Olúwa ní í fi ṣe, yóò sì dá a padà síbí láìpẹ́.’ ”
4
5Bí wọ́n ti ń tú u, díẹ̀ nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀ bi wọ́n léèrè pé, “Kí ni ẹ̀ ń ṣe, È ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́?”
6Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì wọ̀nyí sọ ohun tí Jésù ní kí wọ́n sọ. Nítorí náà àwọn ènìyàn náà yọ̀ǹda fún wọn láti mú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà lọ.
7
8Nígbà náà, púpọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ènìyàn tẹ́ àṣọ wọn sójú-ọ̀nà níwájú u rẹ̀. Àwọn mìíràn ju ewéko ìgbẹ́ sílẹ̀.
9
10
11
12
13Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́ọ̀ọ́kán ti ewé kún orí rẹ̀. Nígbà náà, ó lọ sí ìdí rẹ̀ bóyá ó léso tàbí kò léso. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ewé lásán ni ó rí, kò rí èso lórí rẹ̀. Nítorí pé àkókò náà kì í ṣe àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń so.
14Lẹ́yìn náà, Jésù pàṣẹ fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nígbà tí ó wí bẹ́ẹ̀.
15
16Kò sì gba ẹnikẹ́ni láàyè láti gbé ẹrù ọjà títa wọlé.
17
18Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́-òfin gbọ́ ohun tí ó ti ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń gbà èrò bí wọn yóò ti ṣe pa á. Wọ́n bẹ̀rù rògbòdìyàn tí yóò bẹ́ sílẹ̀, nítorí tí àwọn ènìyàn ní ìgbóná-ọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.
19
20
21Pétérù rántí pé Jésù ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jésù pé, “Rábì, Wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!”
22Jésù sì dáhùn pé, “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run,
23Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘ṣí ìdí, gbé ara rẹ sọ sínú òkun’ ti kò sí ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n ti ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un.
24
25
26Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá dáríjì, Baba yín ti ń bẹ ni ọ̀run kí yóò dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín
27
28Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Àṣẹ wo ni ó fi ń se nǹkan yìí? Ta ni ó sì fún ọ ni àṣẹ yìí láti máa ṣe nǹkan wọ̀nyìí?”
29Jésù dá wọn lóhùn pé, “Èmi yóò sọ fún un yín bí ẹ bá lè dáhùn ìbéèrè mi yìí.”
30Ìtẹ̀bọmi Jòhánù láti ọ̀run wa ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn? “Ẹ dá mi lóhùn!”
31Wọ́n bá ara wọn jíjòrò pé: “Bí a bá wí pé Ọlọ́run ni ó rán an wá nígbà náà yóò wí pé, ‘nígbà tí ẹ mọ̀ bẹ́ẹ̀, èéṣe tí ẹ kò fi gbà à gbọ?’
32Ṣùgbọ́n bí a bá sọ wí pé Ọlọ́run kọ́ ló rán an, nígbà náà àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rẹ̀ rògbòdìyàn. Nítorí pé gbogbo ènìyàn ló gbàgbọ́ pé wòlíì gidi ni Jòhánù.”
33Nítorí náà, Wọ́n kọjú sí Jésù wọn sì dáhùn pé, “Àwa kò mọ̀.”