1
2Lákókò ìkórè, ọkùnrin náà rán ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí àwọn tí ń tọ́jú oko tí ó fi sílẹ̀, láti gba ìpín tirẹ̀ wá nínú ohun ọ̀gbìn oko náà.
3Ṣùgbọ́n àwọn àgbẹ̀ wọnnnì lu ìránṣẹ́ ọkùnrin náà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.
4Ó sì tún rán ọmọ-ọ̀dọ̀ mìíràn sí wọn. Bí àwọn àgbẹ̀ tí tún rí ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó rán sí wọn; wọ́n lù ú. Àní, wọ́n tilẹ̀ dá ọgbẹ́ sí i lórí, wọn rán an lọ ni ìtìjú.
5Ó sì tún rán òmíràn, èyí n nì wọ́n sì pa, àti ọ̀pọ̀ mìíràn, wọ́n lu òmíràn wọ́n sì pa òmiran.
6“Ìránṣẹ́ kan ṣoṣo ló kù tí Baba olóko kò ì tí ì rán níṣẹ́, èyí ni ọmọ òun tìkárarẹ̀. Níkẹyìn ó ran an sí àwọn àgbẹ̀ náà, pẹ̀lú èrò pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ òun.’
7“Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ọmọ baba olóko, wọ́n sọ fún ara wọn pé, ‘Ọmọ rẹ̀ ló ń bọ̀ yìí. Òun ni yóò jogún oko yìí tí baba rẹ̀ bá kú. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, lẹ́yìn náà oko náà yóò di tiwa.’
8Báyìí ni wọ́n mú ọmọ náà tí wọ́n pa á. Wọ́n gbé òkú rẹ̀ kúrò nínú oko.
9“Kí ni ẹ rò pé baba olóko yóò ṣe nígbà tí ó bá gbọ́ ohun tí ó ṣélẹ́. Dájúdájú yóò pa àwọn ẹni ibi wọ̀nyí. Yóò sì gba àwọn olùtọ́jú mìíràn sínú oko rẹ̀.
10
11
12
13
14Bí wọn ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ máa ń sọ òtítọ́ tìrẹ láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ máa ń kọ́ni. Nísinsin yìí, sọ fún wa, ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti máa san owó orí fún Késárì?
15Kí àwa kí ó fi fún un, tàbí kí a máa fi fún un?” Ṣùgbọ́n Jésù mọ ìwà àgàbàgebè wọn. Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi fi èyí dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.”
16Nígbà tí wọ́n mú owó idẹ náà fún un, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ wò ó! Àwòrán àti orúkọ ta ni ó wà níbẹ̀?”
17
18
19
20Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan wà, èyí tí ó dàgbà jùlọ gbéyàwó, ó sì kú láìbímọ.
21Arákùnrin rẹ̀ kejì ṣu obìnrin tí ó fi sílẹ̀ lópó, láìpẹ́, òun pẹ̀lú tún kú láìbímọ. Arákùnrin kẹta tó sú obìnrin yìí lópó tún kú bákan náà láìbímọ.
22Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe títí àwọn méjèèje fi kú láìbímọ. Ní òpin gbogbo rẹ̀, obìnrin tí a ń wí yìí náà kú.
23Ohun tí a fẹ́ mọ̀ nìyì: Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé àwọn arákùnrin méjèèje ló fẹ́ obìnrin náà, ìyàwó o ta ni yóò jẹ́ nínú wọn lọ́jọ́ àjíǹde?”
24Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ìṣòro yín ni wí pé, ẹ kò mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti agbára Ọlọ́run.
25Nítorí pé, nígbà tí àwọn arákùnrin méje yìí àti obìnrin náà bá jí dìde nínú òkú, a kò ní ṣe ìgbéyàwó fún wọn. Wọn yóò dàbí àwọn ańgẹ́lì.
26
27Òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú bí kò ṣe Ọlọ́run àwọn alààyè: nítorí ẹ̀yin ṣe àṣìṣe gidigidi.”
28
29
30Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, èyí ní òfin kìn-ín-ní.’
31
32Olùkọ́ ófin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, ìwọ sọ òtítọ́ nípa pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ, àti pé kò sí òmíràn àfi òun nìkan.
33
34Jésù rí i dájú pé òye ọkùnrin yìí ga, nítorí náà, Jésù sọ fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ kò jìnà sí à ti dé ìjọba Ọ̀run.” Láti ìgbà náà lọ, ẹnikẹ́ni kò tún béèrè ohun kan lọ́wọ́ Jésù.
35
36
37Níwọ̀n ìgbà tí Dáfídì tìkáraarẹ̀ pè é ní ‘Olúwa,’ Báwo ni ó tún ṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
38
39àti ibùjókòó ọlá nínú Sínágọ́gù àti ipò ọlá níbi àṣẹ.
40Àwọn tí wọ́n jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígun fún àsehàn, nítorí èyí, ìjìyà wọn yóò pọ̀ púpọ̀.”
41
42Ṣùgbọn obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ kọ́bọ̀ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdáméjì owó-bàbà kan sínú rẹ̀.
43Jésù pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìì sọ sínú àpótí ìsura ju gbogbo àwọn ìyókù lọ to sọ sínú rẹ lọ.
44Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n, ṣùgbọ́n ní tirẹ̀, nínú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní náà sílẹ̀ àní gbogbo ìní rẹ̀.”