1
2Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “A kò ní mú un ní ọjọ́ Àjọ, kí àwọn ènìyàn má bá á fa ìjàngbọ̀n.”
3
4Àwọn kan nínú àwọn tí ó jókòó ti tábìlì kún fún ìbànújẹ́. Wọ́n sì ń bi ara wọn pé, “Nítorí kí ni a ṣe fi òróró yìí ṣòfò?
5Òun ìbá tà á ju owó iṣẹ́ ọdún kan lọ, kí ó sì fi owó rẹ̀ ta àwọn talákà lọ́rẹ.” Báyìí ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ gún obìnrin náà lára.
6Ṣùgbọ́n Jésù wí fún pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ ń yọ ọ́ lẹ́nu fún ṣé? Nítorí tí ó ṣe ohun rere sí mi?
7
8
9Lóótọ́ ni mo wí fún un yín, níbikíbi tí wọ́n bá ti wàásù mi, ní gbogbo ayé, wọn kò ní ṣe aláìsọ ohun tí obìnrin yìí ṣe pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.”
10
11Inú wọn dùn láti gbọ́ èyí, wọ́n sì pinnu láti fún un ní owó. Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àkókò tí ó rọrùn tí òun yóò fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.
12
13Ó rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru iṣà omi yóò pàdé yín, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
14Ilé tí ọkùnrin náà bá wọ̀, kí ẹ wí fún baale náà pé, ‘Olùkọ́ rán wa pé: Ní bo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wa, níbi tí èmi yóò gbé jẹ àṣè ìrékọja pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’
15Òun yóò sì mú un yín lọ sí gbàngàn ńlá kan lókè ilé náà, tí a ti ṣe lọ́sọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ pèṣè sílẹ̀ dè wá.”
16Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì jáde lọ àárin ìlú. Wọ́n bá gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Jésù tí sọ fún wọn. Wọ́n sì pèsè àṣè ìrékọjá.
17
18Bí wọ́n sì ti jókòó yí tábìlì ká, tí wọ́n ń jẹun, Jésù wí pé, “Lóòtọ́ ni mo wí fún un yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ẹ ń bá mi jẹun yìí ni yóò fí mí hàn.”
19Ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàrú. Olúkúlùkù sì ń bi í ní ọkọ̀ọ̀kan wí pé, “Dájúdájú, kì í ṣe èmi?”
20Ó sì dáhùn wí pé, “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá tí ó ń bá mi jẹun nísinsin yìí ni.
21Ní tòótọ́ Ọmọ-Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: Ṣùgbọ́n ègbé ní fún ọkùnrin náà, láti ọwọ́ ẹni tí a ti fi Ọmọ-Ènìyàn hàn. Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i rárá.”
22
23
24
25Lóótọ̀ ni mo wí fún un yín, èmi kò tún ní mu wáìnì mọ́ títí yóò fi di ọjọ́ náà tí Èmi yóò mu ún ní titun nínú ìjọba Ọlọ́run.”
26
27
28
29Ṣùgbọ́n Pétérù dá a lóhùn, ó wí pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ sá kúrò lẹ́yìn rẹ, èmi kò ní sá.”
30
31Ṣùgbọ́n Pétérù faraya, ó wí pé, “Bí mo tilẹ̀ ní láti kú pẹ̀lú rẹ̀, èmi kò jẹ́ sọ pé n kò mọ̀ ọ́ rí.” Ìlérí yìí kan náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe.
32
33Ó sì mú Pétérù àti Jákọ́bù àti Jòhánù lọ pẹ̀lú rẹ̀. Òun sì kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ gidigidi.
34
35Ó sì lọ ṣíwájú díẹ̀, ó dojú bolẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i gbàdúrà pé, bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré òun kọjá.
36
37Nígbà tí ó sì páda dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́ta, ó bá wọn lójú oorun. Ó sì wí fún Pétérù pé, “Símónì, o ń sùn ni? Ìwọ kò lè bá mi sọ́nà fún wákàtí kan?
38
39Ó sì tún lọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sì gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti gbà á ti ìṣáájú.
40Nígbà tí ó sì tún padà dé, ó bá wọn wọ́n ń sùn, nítorí pé ojú wọn kún fún oorun. Wọn kò sì mọ irú èsì tí wọn ì bá fún un.
41Ó sì wá nígbà kẹ́ta, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa sùn kí ẹ sì máa sinmi ó tó bẹ́ẹ, wákàtí náà ti dé, wò ó, a fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́sẹ̀ lọ́wọ́.
42Ẹ dìde, Ẹ jẹ́ kí a máa lọ. Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mí hàn wà ní tòòsí!”
43
44Júdásì tí fí àmì fún wọn wí pe, “Ẹni tí mo bá fi ẹnu kò lẹ́nu nínú wọn, òun ní Jésù, Ẹ mú un.”
45Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jésù, Júdásì lọ sì ọ̀dọ̀ rẹ̀ tààrá, ó wí pé, “Rábì!” ó sì fi ẹnu kò Jésù lẹ́nu.
46Wọ́n sì mú Jésù.
47Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró idà rẹ̀ yọ, ó fi sá ọmọ-ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì ge etí rẹ̀ bọ́ sílẹ̀.
48Nígbà náà Jésù dáhùn, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ṣé Èmi ni ẹ̀yin jáde tọ̀ wá bi olè, ti ẹ̀yin ti idà àti kùmọ̀ láti mú?
49
50Ní àkókò yìí, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti fi í sílẹ̀, wọ́n sá lọ.
51Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ bo ìhòòhò rẹ̀ àwọn ọmọ-ogun gbìyànjú láti mú òun náà.
52Ó sì fi aṣọ funfun náà sílẹ̀ fún wọn, ó sì sá lọ ní ìhòòhò.
53
54Pétérù tẹ̀lé Jésù lókèèrè, ó sì yọ́ wọ inú àgbàlá olórí àlùfáà, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ó ń yáná.
55Bí ó ti ń ṣe èyí lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ń wá ẹni tí yóò jẹ́rí èkè sí Jésù, èyí tí ó jọjú dáadáa láti lè dájọ́ ikú fún un. Ṣùgbọ́n wọn kò rí.
56Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí wọ̀n ní kò bá ara wọn mu
57Níkẹyìn àwọn kan dìde, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́rìí èké sí i, wọ́n ní
58
59Ṣíbẹ̀, ẹ̀rí i wọn kò dọ́gba
60Nígbà náà ni àlùfáà àgbà dìde, ó bọ́ ṣíwájú. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi Jésù léèrè, ó ní, “Ṣé o kò ní fèsì sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi sùn ọ? Kí ni ìwọ gan an ní sọ fúnrarẹ?”
61Ṣùgbọ́n Jésù dákẹ́.
62
63
64
65Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í tu itọ̀ sí i lára. Wọ́n dì í lójú. Wọ́n ń gbà a lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lójú. Wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Sọtẹ́lẹ̀!” Àwọn olùsọ́ sì ń fi àtẹ́lẹwọ́ wọn gbá a lójú.
66
67Nigba tí ó rí Pétérù tí ó ti yáná, Ó tẹjú mọ́ ọn, ó sì sọ gbangba pé,
68Ṣùgbọ́n Pétérú ṣẹ́, ó ni, “N kò mọ Jésù náà rí; ohun tí ó ń sọ yìí kò tilẹ̀ yé mi.” Pétérù sì jáde lọ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Àkùkọ sì kọ.
69Ọmọbìnrin yẹn sì tún rí Pétérù. Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀. Ó ní, “Ọkùnrin yìí gan an jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù.”
70Ṣùgbọ́n Pétérù tún ṣẹ́.
71Nígbà náà ni Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́ ó sì ń búra, ó ni, “N kò mọ ẹni ti ẹ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí rí!”
72Lójú kan náà tí àkùkọ yìí kọ lẹ́ẹ̀kejì Pétérù rántí ọ̀rọ̀ Jésù fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì, ìwọ yóò ṣẹ́ mí nígbà mẹ́ta.” Ó sì rẹ̀ ẹ́ láti inú ọkàn wá, ó sì sọkùn.