1
2
3Àwọn olórí àlùfáà fi ẹ̀sùn ohun púpọ̀ kàn án.
4Pílátù sì tún bi í léèrè pé, “Ṣe ìwọ kò dáhùn ni? Wo gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn ọ.”
5Ṣùgbọ́n Jésù kò da lohùn síbẹ̀, tóbẹ́ẹ̀ ti ẹnu fi ya Pílátù.
6Ní báyìí, nígbà àjọ, gẹ́gẹ́ bí àsà, òun a máa dá òǹdè kan sílẹ̀ fún àwọn, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá béèrè fún.
7Ọkùnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bárábà. Wọ́n ti ju òun àti àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, nítorí wọ́n sọ̀tẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì pa ènìyàn nínú ìdìtẹ̀ wọn.
8Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì lọ bá Pílátù, wọ́n ní kí ó ṣe bí ó ti máa ń ṣe fún wọn ní ọdọọdún.
9Pílátù béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, “Ṣe ẹ̀yín ń fẹ́ kí èmi dá ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yin?”
10òun mọ̀ pé nítorí ìlara ni àwọn olórí àlùfáà ṣe fà Jésù lé òun lọ́wọ́.
11
12Pílátù sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe pẹ̀lú ẹni ti ẹ̀yin n pè ní ọba àwọn Júù?”
13Wọ́n sì tún kígbe sókè pé, “Kàn án mọ àgbélébùú!”
14Nígbà náà ni Pílátù bi wọn léèrè pé, “Èéṣe? Búburú kí ni ó ṣe?”
15Pilatù sì ń fẹ́ se èyí tí ó wu àwọn ènìyàn, ó dá Bárábà sílẹ̀ fún wọn. Nígbà tí ó sì na Jésù tan o fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn an mọ́ àgbélébùú.
16
17Wọn sì fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò wọ̀ ọ́, wọ́n hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí.
18Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i kí ì, wí pé Kábíyèsí, Ọba àwọn Júù
19Wọ́n sì fi ọ̀pá ìyè lù ú lórí, wọ́n sì tutọ́ síi lára, wọ́n sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un.
20Nígbà tí wọ́n sì fi ṣẹ̀sín tan, wọ́n sì bọ aṣọ elésè àlùkò náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n sì fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n sì mú un jáde lọ láti kàn án mọ́ àgbélébùú.
21
22
23Wọ́n sì fi wáìnì tí a dàpọ̀ mọ́ òjìá fún un mu, ṣùgbọ́n òun kò gbà á.
24
25Ní wákàtí kẹta ọjọ́ ni wọ́n kàn án mọ́ àgbélébùú.
26Àkọlé Ìfisùn tí wọ́n kọ sókè orí rẹ̀ ni ỌBA ÀWỌN JÚÙ.
27Wọ́n sì kan àwọn olè méjì mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀, èkejì lọ́wọ́ òsì rẹ̀.
28Eléyìí mú àṣọtẹ́lẹ̀ ìwé Mímọ́ ṣẹ wí pé, “Wọ́n kà á pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn búburú.”
29
30Tí ó bá lágbára tó bẹ́ẹ̀, gba ara rẹ là, kí o sì ti orí àgbélébùú sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú.”
31
32Jẹ́ kí Kírísítì, Ọba Ísírẹ̀lì, sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélèbùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀.
33
34
35Nígbà tí àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Wò ó ó ń pe Èlíjà.”
36
37Jésù sì tún kígbe soke ni ohùn rara, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.
38
39
40
41
42
43Jóṣẹ́fù ará Arimatíyà wá, ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ẹni tí ń retí ìjọba Ọlọ́run, ó fi ìgboyà lọ sí iwájú Pílátù láti tọrọ òkú Jésù.
44Ẹnú ya Pílátù láti gbọ́ pé Jésù ti kú. Nítorí náà ó pe balógun-ọ̀rún, ó sì bí i léèrè bóyá Jésù ti kú ní tòótọ́.
45Nígbà tí balógun-ọ̀rún náà sì fún Pílátù ni ìdánilójú pé Jésù ti kú, Pílátù yọ̀ǹda òkú rẹ̀ fún Jóṣẹ́fù.
46Jóṣẹ́fù sì ti ra aṣọ ọ̀gbọ̀ wá. Ó sọ òkú Jésù kalẹ̀: ó sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ náà dì í. Ó sì tẹ́ ẹ sí inú ibojì, tí wọ́n gbẹ́ sí ara àpáta. Ó wá yí òkúta dí ẹnu ibojì náà.
47Màríà Magidalénì àti Màríà ìyá Jósè ń wò ó bi Jóṣẹ́fù ti n tẹ́ Jésù sí ibojì.