1Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, nígbà tí Jésù tún padà wọ Kápánámù, òkìkì kàn pé ó ti wà nínú ilé.
2Láìpẹ́, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ti kún ilé tí ó dé sí tó bẹ́ẹ̀ tí inú ilé àti ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ní ìta kò gba ẹyọ ẹnìkan mọ́, ó sì wàásù ọ̀rọ̀ náà sí wọn.
3
4Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jésù, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jésù wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti ẹní rẹ̀ níwájú Jésù.
5Nígbà tí Jésù sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
6Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn olùkọ́ òfin tó jókòó níbẹ̀ sọ fún ara wọn pé,
7“È é ṣe ti ọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀ báyìí? O ń sọ̀rọ̀ òdì. Ta ni ó lè darí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí ko ṣe Ọlọ́run nìkan?”
8Lojú kan náà bí Jésù tí wòye nínú ọkàn rẹ̀ pé wọn ń gbèrò bẹ́ẹ̀ ní àárín ara wọn, ó wí fún wọn pé, “È é ṣe tí ẹ̀yìn fí ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín?
9Èwo ni ó rọrùn jù láti wí fún arọ náà pé: ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ,’ tàbí wí pé, ‘Dìde sì gbé àkéte rẹ, ki o si máa rin?’
10Ṣùgbọ́n ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Ènìyàn ní agbára ní ayé làti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ji ní.” Ó wí fún ọkùnrin arọ náà pé,
11“Mo wí fún ọ, dìde, gbé ẹní rẹ kí ó sì máa lọ ilé rẹ.”
12
13Nígbà náà, Jésù tún jáde lọ sí etí òkun. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ wọn.
14
15Ó si ṣe, bí ó sì ti jókòó tí oúnjẹ ni ilé Léfì, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wá bá Jésù jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, nítorí ti wọn pọ̀ ti wọn tẹ̀lé e.
16
17Nígbà tí Jésù gbọ́, ó sọ fún wọn wí pé, “Àwọn tí ara wọ́n dá kò wa oníṣègùn, bí ko ṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Èmi kò wá lati sọ fún àwọn ènìyàn rere láti ronúpìwàdà, bí kò ṣe àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
18
19Jésù dáhùn wí pé, “Báwo ni àwọn àlejò ọkọ ìyàwó yóò se máa gbàwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó sì wà lọ́dọ̀ wọn?
20
21“Kò si ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ túntún lẹ ògbólógbo ẹ̀wù, bí ó ba se bẹ́ẹ̀, èyí túntún ti a fi lẹ̀ ẹ́ yóò fà ya kúrò lára ògbólógbòó, yíyọ́ rẹ̀ yóò sí burú púpọ̀ jù.
22Kò sì sí ẹni tí ń fi ọtí wáìnì túntún sínú ìgò wáìni ògbólógbó. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí wáìnì náà yóò fa ìgò náà ya, ọtí wáìnì a si dàànu, bákan náà ni ìgò náà, ṣùgbọ́n ọtí wáìnì tuntun ni a n fi sínú ìgò wáìnì tuntun.”
23
24Díẹ̀ nínú àwọn Farisí wí fún Jésù pé, “Wò ó, è é ṣe ti wọn fi ń ṣe èyí ti kò yẹ ni ọjọ́ ìsinmi.”
25Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yín kò tí kà ohun tí Dáfídì ṣe, nígbà tí ó ṣe aláìní, tí ebi sì ń pa á, òun àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀?
26
27
28Nítorí náà Ọmọ Ènìyàn ni Olúwa ọjọ́ ìsinmi pẹ̀lú.”