1
2
3Jésù wí fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé, “Dìde dúró ní iwájú ìjọ ènìyàn.”
4Nígbà náà ni Jésù bèèrè lọ́wọ́ wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ó bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi bóyá láti ṣe rere, tàbí láti ṣe búburú! Láti gbà ẹ̀mí là, tàbí pa á run?” Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́ láìfèsì.
5Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá.
6
7
8
9Nítorí ẹ̀rọ̀, Jésù sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ lati sètò ọkọ̀ ojú omi kekere kan sílẹ̀ fún un láti lọ, láti lé àwọn ẹ̀rọ̀ sẹ́yìn.
10
11Ìgbàkúùgbà tí àwọn tí ó kún fún ẹ̀mí àìmọ́ bá ti fojú gán-án ní rẹ̀, wọ́n á wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọn a sì kígbe lóhùn-rara wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”
12
13
14Ó yan àwọn méjìlá-ó pè wọ́n ní apostẹli-kí wọ́n kí ó lè wà pẹ̀lú rẹ̀, àti kí wọn kí ó lè lọ láti wàásù
15àti láti lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí Èsù jáde.
16
17Jákọ́bù ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jésù sọ àpèlé wọ́n ní Bóánájì, èyí tí ó túmọ̀ sí àwọn ọmọ àrá).
18Àti Ańdérù, Fílípì, Bátólómíù, Mátíù, Tómásì, Jákọ́bù (ọmọ Álíféù), Tádéù, Símónì (ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó fẹ́ ará Kénánì tí ó fi ìjàngbọ̀n dojú ìjọba Rómù bolẹ̀)
19
20
21
22
23Jésù pè wọ́n, ó sì fi òwé bá wọn sọ̀rọ̀: “Báwo ni Èsù ṣe lè lé èsù jáde?
24Bí ìjọba kan bá yapa sí ara rẹ̀, ìjọba náà yóò wó lulẹ̀.
25Bákan náà, bí ilé kan bá sì yapa sí ara rẹ, ilé náà kí yóò leè dúró.
26Bí Èṣù bá sì díde sí ara rẹ, tí ó sì yapa, òun kí yóò le è dúró ṣùgbọ́n òpin rẹ̀ yóò dé.
27
28
29Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́, kì yóò rí ìdáríjì títí ayé, ṣùgbọ́n ó wà nínú èwù ẹ̀bi àìnípẹ̀kun.”
30Òun sọ eléyìí fún wọn, nítorí tí wọ́n sọ pé, “Nípa agbára ẹ̀mí Èṣù ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.”
31
32Àwọn ènìyàn tí wọ́n jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ wà lóde.”
33Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhùn wí pé, “Ta ni í ṣe ìyá mi tàbí àwọn arákùnrin mi?”
34Ó sì wò gbogbo àwọn tí ó jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ yíká, ó sì wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi:
35Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, òun ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”