1
2Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé:
3“Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀.
4Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ.
5Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpátá, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀. Láìpẹ́ ọjọ́, ó hú jáde.
6Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jónà, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ.
7Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrin ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbà sókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúngbìn náà kò le so èso.
8Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Ó sì so èso lọ́pọ̀lọpọ̀-òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.”
9Jésù sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́”
10
11
12
13
14Afúrúgbìn ń fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà.
15Àwọn èṣo tó bọ́ sí ojú ọ̀nà líle, ni àwọn ọlọ́kan líle tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, lójúkan náà èṣù wá ó sì mú kí wọn gbàgbé ohun tí wọ́n ti gbọ́.
16Bákan náà, àwọn tí ó bọ́ sórí àpata, ni àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
17Ṣùgbọ́n kò ni gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọn a wà fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà nígbà ti wàhálà tàbí inúnibínu bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà, lójúkan náà, wọn a kọsẹ̀.
18Àwọn tí ó bọ́ sáàrin ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọn sì gbà á.
19Ṣùgbọ́n láìpẹ́ jọjọ, àwọn adùn ayé àti inú dídùn, ọrọ̀ àti ìjàkadì fún àṣeyọrí ìfẹ́ àwọn ohun mèremère ayé, gba ọkàn wọn, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa ní ọkàn wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ aláìléso.
20Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì gbà á lótìítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run, ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùnún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn.”
21
22
23
24
25
26
27Lóru àti ní ọ̀sán, bóyá ó sùn tàbí ó dìdè, irúgbìn náà hù jáde, ó sì dàgbà, òun kò sì mọ̀ bí ó ti ṣẹlẹ̀.
28Nítorí tí ilẹ̀ kọ́kọ́ hù èso jáde fún ara rẹ̀, ó mú èéhù ewé jáde, èyí tí ó tẹ̀lé e ni orí ọkà, ní ìparí, ọkà náà gbó.
29Nígbà tí èṣo bá gbó tan, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun a tẹ dòje bọ inú ọkà náà, ó sì kórè rẹ̀.”
30
31Ó dàbí èso hóró Músítádì kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan níńu àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbin sínú ilẹ̀.
32Ṣíbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbà sókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgba yókù lọ. Ó sì ya ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbò-bò.”
33Òun lo ọ̀pọ̀ irú òwe wọ̀nyí láti fi kọ́ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ti ń fẹ́ láti ní òye tó.
34
35
36Nígbà tí wọn ti tú ìjọ ká, wọ́n si gbà á sínú ọkọ̀ ojú omi gẹ́gẹ́ bí ó ti wà. Àwọn ọkọ̀ ojú-omi kékeré mìíràn sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀.
37Ìji líle ńlá kan sì dìde, omi sì ń bù sínú ọkọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ̀ síi kún fún omi, ó sì fẹ́rẹ rì.
38Jésù ti sùn lọ lẹ́yìn ọkọ̀, ó gbé orí lé ìrọ̀rí. Wọ́n sì jí i lóhùn rara wí pé, “Olùkọ́ni, tàbí ìwọ kò tilẹ̀ bìkítà pé gbogbo wa fẹ́ rì?”
39Ó dìde, ó bá ìjì líle náà wí, ó sì wí fún òkun pé, “Dákẹ́ jẹ́ẹ́,” ìjì náà sì dá, ìparọ́rọ́ ńlá sì wà.
40Lẹ́yìn náà, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èése tí ẹ̀yin fi ń ṣojo bẹ́ẹ̀? Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ì ní ìgbàgbọ́ ṣíbẹ̀síbẹ̀?”
41Ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni èyí, tí ìjì àti òkun ń gbọ́ tirẹ̀!”