1
2Bí Jésù sì ti ń ti inú ọkọ̀ ojú omi jáde. Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́ jáde ti ibojì wá pàdé rẹ̀.
3Ọkùnrin yìí ń gbé nínú ìbojì, kò sí ẹni tí ó lè dè é mọ́, kódà ẹ̀wọ̀n kò le dè é.
4Nítorí pé nígbà púpọ̀ ni wọn ti ń fi ṣẹ́kẹ́sẹkẹ̀ dè é lọ́wọ́ àti ẹṣẹ̀, tí ó sì ń já a dànù kúrò ni ẹṣẹ rẹ. Kò sí ẹnìkan tí ó ní agbára láti káwọ́ rẹ̀.
5Tọ̀sán-tòru láàrin àwọn ibojì àti ní àwọn òkè ni ó máa ń kígbe rara tí ó sì ń fi òkúta ya ara rẹ̀.
6Nígbà tí ó sì rí Jésù látòkèrè, ó sí sáré lọ láti pàdé rẹ̀. Ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀.
7
8Nítorí tí Ó wí fún un pé, “Jáde kúrò lára ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́!”
9Jésù sì bi í léèrè pé, “Kí ni orúkọ rẹ?”
10Nígbà náà ni ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jésù gidigidi, kí ó má ṣe rán àwọn jáde kúrò ní agbègbè náà.
11Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá kan sì ń jẹ lẹ́bàá òké.
12Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ Jésù pé, “Rán wa lọ sínú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ wọnni kí awa le è wọ inú wọn lọ.”
13Jésù fún wọn láàyè, àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà tí ó tó ìwọ̀n ẹgbàá sì túká lọ́gán, wọ́n sì sáré lọ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè rọ́ sínú òkun, wọ́n sì ṣègbé.
14Àwọn olùtọ́jú ẹran wọ̀nyí sì sá lọ sí àwọn ìlú ńlá àti ìlú kéékèèkéé, wọ́n sì ń tan ìròyìn náà ká bí wọ́n ti ń sáré. Àwọn ènìyàn sì tú jáde láti fojú gán-án-ní ohun náà tí ó sẹlẹ̀.
15Nígbà tí wọ́n péjọ sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n rí ọkùnrin náà, ẹni tí ó ní ẹ̀mí-èṣù, tí ó jokòó níbẹ̀, ó wọ aṣọ iye rẹ sì bọ̀ sípọ, ẹ̀rù sì bà wọ́n.
16Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn sì ń ròyìn rẹ̀ fún àwọn ènìyàn ohun tí ó sẹlẹ̀ sí ọkùnrin ẹlẹ́mí àìmọ́, wọn si sọ nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà pẹ̀lú.
17Nígbà náà, àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ Jésù pé kí ó fi agbégbé àwọn sílẹ̀.
18Bí Jésù ti ń wọ inú ọkọ̀ ojú-omi lọ, ọkùnrin náà tí ó ti ní ẹ̀mí àìmọ́ tẹ̀lẹ̀ bẹ̀ Ẹ́ pé kí òun lè bá a lọ.
19Jésù kò gbà fún un, ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Lọ sí ilé sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sì sọ fún wọn bí Ọlọ́run ti ṣe ohun ńlá fún ọ, àti bí ó sì ti ṣàánú fún ọ.”
20
21
22
23
24Jésù sì ń bá a lọ.
25Obìnrin kan sì wà láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá.
26Ẹni tí ojú rẹ̀ sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, tí ó sì ti ná gbogbo ohun tí ó ní, síbẹ̀ kàkà kí ó san, ó ń burú sí i.
27Nígbà tí ó sì gburo iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, ìdí nìyìí tí ó fi wá sẹ́yìn rẹ̀, láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀.
28Nítorí ti ó rò ní ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá ṣá à lè fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.”
29Ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ sì gbẹ lẹṣẹkẹṣẹ, òun sì mọ̀ lára rẹ̀ pé, a mú òun láradá kúrò nínú àrùn náà.
30
31Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó rọ̀gbà yí ọ ká, ìwọ́ sì tún ń bèèrè ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn ọ́?”
32Ṣíbẹ̀, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí wò yíká láti rí ẹni náà, tí ó fi ọwọ́ kan òun.
33Nígbà náà, obìnrin náà kún fún ìbẹ̀rù àti ìwárìrì nítorí ó ti mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun. Ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ ohun tí òun ti ṣe.
34
35Bí Jésù sì ti ń ba obìnrin náà sọ̀rọ̀, àwọn ìránṣẹ́ dé láti ilé Jáírù olorí sínágọ́gù wá, wọ́n wí fún un pé, ọmọbìnrin rẹ ti kú, àti pé kí wọn má ṣe yọ Jésù lẹ́nu láti wá, nítorí ó ti pẹ́ jù.
36Ṣùgbọ́n bi Jésù ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jáírù pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbà mí gbọ́ nìkan.”
37
38Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jésù rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún.
39Ó wọ inú ilé lọ, Ó sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohunréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni.”
40Wọ́n sì fi í rẹ́rín.
41
42Lẹ́sẹ̀kan-náà, ọmọbìnrin náà sì dìde. Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì ba wọn, ẹnú sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi.
43