1
2Wọ́n sì ṣe àkíyèsí wí pé díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí yìí ni wẹ ọwọ́.
3(Àwọn Farisí, àti gbogbo àwọn Júù, bí wọ́n kò bá wẹ ọwọ́ wọn gidigidi, wọn kií jẹun nítorí wọ́n ti pa òfin àtọwọdọ́wọ́ àwọn àgbà mọ́.
4
5
6
7
8Nítorí tí ẹ̀yin fi òfin Ọlọ́run sí apákan, ẹ̀yin ń tẹ̀lé àà àwọn ènìyàn.”
9Ó si wí fún wọn: “Ẹyin sáà mọ̀ bí ẹ ti ń gbé òfin Ọlọ́run jù sẹ́yìn kí ẹ lè mú òfin tiyín ṣẹ.
10
11Ṣùgbọ́n ẹyin wá yí i po pé ó dára bákan náà fún ọkùnrin kan bí kó bá tilẹ̀ pèsè fún àìní àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kí a sọ fún wọn pé, ‘Ẹ má ṣe bínú baba tàbí ìyá mi, n kò lè ràn yín lọ́wọ́ nísinsin yìí,’ nítorí tí mo ti fi èyí tí ǹ bá fi fún un yín fún Ọlọ́run.
12Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò si jẹ́ kí ó ṣe ohunkóhun fún baba tàbí iyá rẹ̀ mọ́.
13Ẹ̀yin ń fi òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ti yín tí ẹ fi lélẹ̀, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán àti ọ̀pọ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń ṣe.”
14Lẹ́yìn náà, Jésù pe ọ̀pọ̀ ènìyàn láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí èyí ó yé e yín.
15Kò sí ohunkóhun láti òde ènìyàn, tí ó wọ inú rẹ̀ lọ, tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tí ó ti inú rẹ jáde, àwọn wọ̀nyí ní ń sọ ènìyàn di aláìmọ́.
16Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”
17
18
19Ìdí ni wí pé, Ohunkóhun tí ó bá wọ inú láti ìta, kò wọ inú ọkàn rárá, ṣùgbọ́n ó kọjá sí ikùn.” (Nípa sísọ èyí, Jésù fi hàn pé gbogbo oúnjẹ jẹ́ “mímọ́.”)
20
21Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá: àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà,
22
23Gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí ń tí inú wá, àwọn ló sì ń sọ yín di aláìmọ́.”
24
25Láìpẹ́, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ ní ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá, ó ti gbọ́ nípa Jésù, ó wá, ó sì wólẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ Jésù.
26Gíríkì ní obìnrin náà, Ṣíríàfonísíà ní orílẹ̀ èdè rẹ̀. Ó bẹ Jésù kí ó bá òun lé ẹ̀mí Èsù náà jáde lára ọmọbìnrin òun.
27Jésù sọ fún obìnrin yìí pé, “Ní àkọ́kọ́, ó yẹ kí a fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọmọ lọ́rùn ná. Nítorí kò tọ́ kí a mú oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”
28Obìnrin náà dáhùn wí pé, “Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yín Olúwa, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ajá pàápàá a máa ní àǹfààní láti jẹ ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tábílì.”
29“Ó sì wi fún un pé, nítorí ọ̀rọ̀ yìí, máa lọ, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti jáde kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.”
30Nígbà tí ó náà padà dé ilé, ó bá ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìdùbúlẹ̀ jẹ́jẹ́ lórí ibùsùn, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti fi í sílẹ̀.
31
32
33
34Nígbà náà ni Jésù wòkè ọ̀run, ó sì mí kanlẹ̀, ó sì pàṣẹ wí pé, “Éfátà,” èyí ni, “Ìwọ ṣí.”
35Bí Jésù ti pàṣẹ yìí tan, ọkùnrin náà sì gbọ́ràn dáadáa. Ó sì sọ̀rọ̀ ketekete.
36
37Àwọn ènìyàn sì kún fún ìyanu, wọ́n wí pé, “Ó se ohun gbogbo dáradára, Ó mú kí adití gbọ́ràn, odi sì sọ̀rọ̀.”