1
2
3
4Nígbà náà ni Èlíjà àti Mósè farahàn fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Jésù.
5Pétérù sì wí fún Jesù pé, “Rábì, ó dára fún wa láti máa gbé níhìnín, si jẹ́ kí a pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fun ọ, ọ̀kan fún Mósè, àti ọ̀kan fún Èlíjà.”
6Nítorí òun kò mọ ohun tí òun ìba sọ, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi.
7
8Lójijì, wọ́n wo àyíká wọn, wọn kò sì rí ẹnìkan kan mọ́, bí kò ṣe Jésù nìkan ṣoṣo ni ó sì wà pẹ̀lú wọn.
9
10Nítorí náà, wọ́n pa nǹkan náà mọ́ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ ara wọn ohun tí àjíǹde kúrò nínú òkú túmọ̀ sí.
11
12
13Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Èlíjà ti wa ná, wọ́n sì ti ṣe ohunkóhun tí ó wù wọ́n sí i, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀.”
14
15Bí Jésù ti ń súnmọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pẹ̀lú ìbẹ̀rù, nígbà náà ni wọ́n sáré lọ kí i.
16Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ló fa àríyàn-jiyàn?”
17Ọkùnrin kan láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn dáhùn pé, “Olùkọ́, èmi ni mo mú ọmọ yìí wá fún ọ láti wò ó sàn. Kò lè sọ̀rọ̀ rárá, nítorí tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́.
18Àti pé, nígbàkúùgbà tí ó bá mú un, á gbé e sánlẹ̀, a sì máa hó itọ́ lẹ́nu, a sì máa lọ́ ẹyín rẹ̀. Òun pàápàá a wá le gbàgìdì. Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kí wọn lé ẹ̀mí àìmọ́ náà jáde, ṣùgbọ́n wọ́n kò lè ṣe é.”
19Ó sì dá wọn lóhun, ó wí pé, “Ẹ̀yin ìran aláìgbàgbọ́ yìí, Èmi yóò ti bá a yín pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti mú sùúrù fún un yín pẹ́ tó? Ẹ mú ọmọ náà wá sọ́dọ̀ mi.”
20Wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ rẹ̀: nígbà tí ó sì rí i, lójúkan-náà ẹ̀mi náà nà án tàntàn ó sì ṣubú lulẹ̀, ó sì ń fi ara yílẹ̀, ó sì ń yọ ìfófóò lẹ́nu.
21Jésù béèrè lọ́wọ́ baba ọmọ náà pé, “Ó tó ìgbà wo tí ọmọ rẹ̀ ti wà nínú irú ipò báyìí?”
22Nígbàkúùgbà ni ó sì máa ń gbé e sínú iná ati sínú omi, láti pa á run, ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun, ṣàánú fún wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.
23
24Lójúkan-náà baba ọmọ náà kígbe ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́, ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́.”
25Nígbà tí Jésù rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń péjọ sọ́dọ̀ wọn, ó bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí pé, “Ìwọ ẹ̀mí àìmọ́, adití àti odi, mo pàṣẹ fún ọ, kí ó jáde kúrò lára ọmọ yìí, kí ó má ṣe padà sí ibẹ̀ mọ́.”
26Òun sì kígbe ńlá, ó sì nà án tàn tàn, ó sì jáde kúrò lára rẹ̀: ọmọ náà sì dàbí ẹni tí ó kú tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ké wí pé, “Héè, ọmọ náà ti kú.”
27Ṣùgbọ́n Jésù fà á lọ́wọ́, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó díde dúró.
28Nígbà tí ó sì wọ ilé, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í léèrè ní kọ́kọ́ wí pé, “Èéṣe tí àwa kò fi lè lé e jáde?”
29Ó sì wí fún wọn pé, “Irú èyí kò le ti ipa ohun kan jáde, bí kò se nípa àdúrà.”
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39Jésù sì sọ fún un pé, “Má ṣe dá irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ dúró, nítorí kò sí ẹnìkan ti ó fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ ìyanu tí yóò tún lè máa sọ ohun búburú nípa mi.
40Nítorí ẹni tí kò bá kọ ojú ìjà sí wa, ó wà ní ìhà tiwa
41
42
43Bí ọwọ́ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o gbé títí ayé àìnípẹ̀kun pẹ̀lú ọwọ́ kan ju kí a gbé ọ sínú iná àjóòkú ọ̀run àpáàdì pẹ̀lú ọwọ́ méjèèjì.
44Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú tí iná nàá kì í kú
45Bí ẹsẹ̀ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé é sọnú, ó sàn kí ó di agẹ́sẹ̀, kí o sì gbé títí ayé àìnípẹ̀kun ju kí o ní ẹṣẹ̀ méjì tí ó gbé ọ lọ sí ọ̀run àpáàdì.
46Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú, tí iná nàá kì í sì í ku
47Àti pé, bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn kí o wọ ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú ojú kan ju kí ó ní ojú méjì kí ó sì lọ sí inú iná ọ̀run àpáàdì.
48Níbi ti
49
50